Isa 27:1-13

Isa 27:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo fi idà rẹ̀ tí ó mú, tí ó tóbi, tí ó sì lágbára, pa Lefiatani, ejò tí ó ń fò, Lefiatani, ejò tí ń lọ́ wérékéké, yóo sì pa ejò ńlá tí ń bẹ ninu òkun. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo kọrin nípa ọgbà àjàrà dáradára kan pé, “Èmi OLUWA ni olùṣọ́ rẹ̀, lásìkò, lásìkò ni mò ń bomi rin ín; tọ̀sán-tòru ni mò ń ṣọ́ ọ kí ẹnìkan má baà bà á jẹ́. Inú kò bí mi, ǹ bá rí ẹ̀gún ati pàǹtí ninu rẹ̀, ǹ bá gbógun tì wọ́n, ǹ bá jó gbogbo wọn níná papọ̀. Ṣugbọn bí wọn bá fi mí ṣe ààbò, kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa; kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa.” Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóo ta gbòǹgbò, Israẹli yóo tanná, yóo rúwé, yóo so, èso rẹ̀ yóo sì kún gbogbo ayé. Ṣé OLUWA ti jẹ wọ́n níyà bí ó ti fìyà jẹ àwọn tí ó jẹ wọ́n níyà? Ṣé ó ti pa wọ́n bí ó ti pa àwọn tí ó pa wọ́n? OLUWA fìyà jẹ àwọn eniyan rẹ̀, ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn; ó lé wọn jáde ní ìlú, bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù líle bá ń fẹ́ láti ìlà oòrùn. Ọ̀nà tí a fi lè pa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu rẹ́, tí a fi lè mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò ni pé: Kí ó fọ́ gbogbo òkúta àwọn pẹpẹ oriṣa rẹ̀ túútúú, bí ẹfun tí a lọ̀ kúnná; kí ó má ku ère oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari kan lóòró. Nítorí ìlú olódi ti di ahoro, ó di ibùgbé tí a kọ̀ sílẹ̀, tí a sì patì bí aginjù; ibẹ̀ ni àwọn ọmọ mààlúù yóo ti máa jẹko, wọn óo dùbúlẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀. Àwọn ẹ̀ka igi náà yóo dá nígbà tí wọ́n bá gbẹ, àwọn obinrin yóo sì fi wọ́n dáná. Nítorí òye kò yé àwọn eniyan wọnyi rárá; nítorí náà, ẹni tí ó dá wọn kò ní ṣàánú wọn, Ẹni tí ó mọ wọ́n kò ní yọ́nú sí wọn. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo pa ẹ̀yin eniyan Israẹli bí ẹni pa ọkà, láti odò Yufurate títí dé odò Ijipti, yóo sì ko yín jọ lọ́kọ̀ọ̀kan. Ní ọjọ́ náà, a óo fun fèrè ogun ńlá, àwọn tí ó ti sọnù sí ilẹ̀ Asiria ati àwọn tí a lé lọ sí ilẹ̀ Ijipti yóo wá sin OLUWA lórí òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.

Isa 27:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

LI ọjọ na li Oluwa yio fi idà rẹ̀ mimú ti o tobi, ti o si wuwo bá lefiatani ejò ti nfò wi, ati lefiatani ejò wiwọ́ nì; on o si pa dragoni ti mbẹ li okun. Li ọjọ na ẹ kọrin si i, Ajàra ọti-waini pipọ́n. Emi Oluwa li o ṣọ ọ: emi o bù omi wọ́n ọ nigbakugba: ki ẹnikẹni má ba bà a jẹ, emi o ṣọ ọ ti oru ti ọsan. Irunú kò si ninu mi: tani le doju pantiri ẹlẹgun ati ẹgun kọ mi li ogun jijà? emi iba là wọn kọja, emi iba fi wọn jona pọ̀ ṣọ̀kan. Tabi jẹ ki o di agbara mi mu, ki o ba le ba mi lajà; yio si ba mi lajà. Yio mu ki awọn ti o ti Jakobu wá ta gbòngbo: Israeli yio tanna yio si rudi, yio si fi eso kún oju gbogbo aiye. On ha lù u bi o ti nlu awọn ti o lù u? a ha pa a gẹgẹ bi pipa awọn ti on pa? Niwọ̀n-niwọ̀n, nigba itìjade rẹ̀, iwọ o ba a wi: on ṣi ẹfũfu-ile rẹ̀ ni ipò li ọjọ ẹfũfu ilà-õrun. Nitorina nipa eyi li a o bò ẹ̀ṣẹ Jakobu mọlẹ: eyi si ni gbogbo eso lati mu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ kuro; nigbati on gbe okuta pẹpẹ kalẹ bi okuta ẹfun ti a lù wẹwẹ, igbó ati ere-õrun kì yio dide duro. Nitori ilu-olodi yio di ahoro, a o si kọ̀ ibugbé silẹ, a o si fi i silẹ bi aginju: nibẹ ni ọmọ-malu yio ma jẹ̀, nibẹ ni yio si dubulẹ, yio si jẹ ẹka rẹ̀ run. Nigbati ẹka inu rẹ̀ ba rọ, a o ya wọn kuro: awọn obinrin de, nwọn si tẹ̀ iná bọ̀ wọn: nitori alaini oye enia ni nwọn: nitorina ẹniti o dá wọn kì yio ṣãnu fun wọn, ẹniti o si mọ wọn kì yio fi ojurere hàn wọn. Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio ja eso kuro ni ibu odò si iṣàn Egipti, a o si ṣà nyin jọ li ọkọkan, ẹnyin ọmọ Israeli. Yio si ṣe li ọjọ na, a o fun ipè nla, awọn ti o mura lati ṣegbe ni ilẹ Assiria yio si wá, ati awọn aṣátì ilẹ Egipti, nwọn o si sìn Oluwa ni oke mimọ́ ni Jerusalemu.

Isa 27:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ náà, OLúWA yóò fi idà rẹ̀ jẹ ni ní yà idà rẹ̀ a mú bí iná tí ó tóbi tí ó sì lágbára Lefitani ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì, Lefitani ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì; Òun yóò sì pa ẹ̀mí búburú inú Òkun náà. Ní ọjọ́ náà “Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan. Èmi OLúWA ń bojútó o, Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà. Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára. Inú kò bí mi. Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí! Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun; Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò; jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi, bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.” Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò, Israẹli yóò tanná yóò sì rudi èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé. Ǹjẹ́ OLúWA ti lù ú gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀? Ǹjẹ́ a ti pa á gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á? Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó fi dojúkọ ọ́ pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde, gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́ Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu, èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ: Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́, kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí tí yóò wà ní ìdúró. Ìlú olódi náà ti dahoro, ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì gẹ́gẹ́ bí aginjù; níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀; wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán. Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànù àwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dáná nítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́; Nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn; bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n. Ní ọjọ́ náà OLúWA yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin OLúWA ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.