Isa 26:1-9
Isa 26:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọjọ na li a o kọ orin yi ni ilẹ Juda; Awa ní ilu agbara; igbala li Ọlọrun yio yàn fun odi ati ãbo. Ẹ ṣi ilẹkun bodè silẹ, ki orilẹ-ède ododo ti nṣọ́ otitọ ba le wọ̀ ile. Iwọ o pa a mọ li alafia pipé, ọkàn ẹniti o simi le ọ: nitoriti o gbẹkẹle ọ. Ẹ gbẹkẹle Oluwa titi lai: nitori Oluwa Jehofa li apata aiyeraiye: Nitori o rẹ̀ awọn ti ngbe oke giga silẹ; ilu giga, o mu u wálẹ; o mu u wálẹ; ani si ilẹ; o mu u de inu ekuru. Ẹsẹ yio tẹ̀ ẹ mọlẹ, ani ẹsẹ awọn talaka, ati ìṣísẹ̀ awọn alaini. Ọ̀na awọn olõtọ ododo ni: iwọ, olõtọ-julọ, ti wọ̀n ipa-ọ̀na awọn olõtọ. Nitõtọ, Oluwa, li ọ̀na idajọ rẹ, li awa duro de ọ: ifẹ́ ọkàn wa ni si orukọ rẹ, ati si iranti rẹ. Ọkàn mi li emi fi ṣe afẹ̃ri rẹ li oru; nitõtọ, pẹlu ẹmi mi ninu mi li emi o wá ọ ni kutùkutù; nitori nigbati idajọ rẹ mbẹ ni ilẹ, awọn ti mbẹ li aiye yio kọ́ ododo.
Isa 26:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò náà, orin tí wọn óo máa kọ ní ilẹ̀ Juda ni pé: “A ní ìlú tí ó lágbára, ó fi ìgbàlà ṣe odi ati ibi ààbò. Ẹ ṣí ìlẹ̀kùn ibodè, kí orílẹ̀-èdè olódodo, tí ń ṣe òtítọ́ lè wọlé. O óo pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé ọ mọ́ ní alaafia pípé, nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ. Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA títí lae, nítorí àpáta ayérayé ni OLUWA Ọlọrun. Ó sọ àwọn tí ń gbé orí òkè kalẹ̀, ó sọ ìlú tí ó wà ní orí òkè téńté di ilẹ̀, ó sọ ọ́ di ilẹ̀ patapata, ó fà á sọ sinu eruku. Wọ́n ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, bí àwọn òtòṣì tí ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni àwọn aláìní ń tẹ̀ ẹ́.” Ọ̀nà títẹ́jú ni ọ̀nà àwọn olódodo ó mú kí ọ̀nà àwọn olódodo máa dán. Àwa dúró dè ọ́ ní ọ̀nà ìdájọ́ rẹ, OLUWA, orúkọ rẹ ati ìrántí rẹ ni ọkàn wa ń fẹ́. Ọkàn mi ń ṣe àfẹ́rí rẹ lálẹ́, mo sì ń fi tọkàntọkàn wá ọ nítorí nígbà tí ìlànà rẹ bá wà láyé ni àwọn ọmọ aráyé yóo kọ́ òdodo.
Isa 26:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọjọ́ náà ni a ó kọ orin yìí ní ilẹ̀ Juda: Àwa ní ìlú alágbára kan, Ọlọ́run fi ìgbàlà ṣe ògiri àti ààbò rẹ̀. Ṣí àwọn ìlẹ̀kùn kí àwọn olódodo orílẹ̀-èdè kí ó lè wọlé, orílẹ̀-èdè tí ó pa ìgbàgbọ́ mọ́. Ìwọ yóò pa á mọ́ ní àlàáfíà pípé ọkàn ẹni tí ó dúró ṣinṣin, nítorí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ. Gbẹ́kẹ̀lé OLúWA títí láé, nítorí OLúWA, OLúWA ni àpáta ayérayé náà. Ó sọ àwọn tí ó ń gbé ní òkè di onírẹ̀lẹ̀ ó rẹ ìlú agbéraga náà nílẹ̀; ó sọ ọ́ di ilẹ̀ pẹrẹsẹ ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ nínú erùpẹ̀. Ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ẹsẹ̀ aninilára n nì, ipasẹ̀ àwọn òtòṣì. Ipa ọ̀nà àwọn olódodo tẹ́jú Ìwọ tó dúró ṣinṣin, ìwọ mú ọ̀nà àwọn olódodo ṣe geere. Bẹ́ẹ̀ ni, OLúWA, rírìn ní ọ̀nà òfin rẹ àwa dúró dè ọ́; orúkọ rẹ àti òkìkí rẹ àwọn ni ohun tí ọkàn wa ń fẹ́. Ọkàn mi ń pòùngbẹẹ̀ rẹ ní ọ̀gànjọ́ òru; ní òwúrọ̀ ni ẹ̀mí mi ń ṣàfẹ́rí rẹ. Nígbà tí ìdájọ́ rẹ bá sọ̀kalẹ̀ sórí ayé àwọn ènìyàn yóò kọ́ ìṣòdodo.