Isa 11:6-9
Isa 11:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ikõkò pẹlu yio ma ba ọdọ-agutan gbe pọ̀, kiniun yio si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ malũ ati ọmọ kiniun ati ẹgbọ̀rọ ẹran abọpa yio ma gbe pọ̀; ọmọ kekere yio si ma dà wọn. Malũ ati beari yio si ma jẹ pọ̀; ọmọ wọn yio dubulẹ pọ̀; kiniun yio si jẹ koriko bi malũ. Ọmọ ẹnu-ọmu yio si ṣire ni ihò pãmọlẹ, ati ọmọ ti a já lẹnu-ọmu yio si fi ọwọ́ rẹ̀ si ihò ejò. Nwọn ki yio panilara, bẹ̃ni nwọn ki yio panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi: nitori aiye yio kún fun ìmọ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bò okun.
Isa 11:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Ìkookò yóo máa bá ọ̀dọ́ aguntan gbé, àmọ̀tẹ́kùn yóo sùn sílẹ̀ pẹlu ọmọ ewúrẹ́, ọmọ mààlúù, ati kinniun, ati ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa yóo jọ máa gbé pọ̀, ọmọ kékeré yóo sì máa kó wọn jẹ. Mààlúù ati ẹranko beari yóo jọ máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ wọn yóo jọ máa sùn pọ̀, kinniun yóo sì máa jẹ koríko bí akọ mààlúù. Ọmọ ọmú yóo máa ṣeré lórí ihò paramọ́lẹ̀, ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú yóo máa fi ọwọ́ bọ inú ihò ejò. Wọn kò ní ṣe eniyan ní jamba mọ́, tabi kí wọ́n bu eniyan jẹ ní gbogbo orí òkè mímọ́ mi. Nítorí ìmọ̀ OLUWA yóo kún gbogbo ayé bí omi ṣe kún gbogbo inú òkun.
Isa 11:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé, ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́ ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀ ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n. Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀, kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù. Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká, ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀. Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ OLúWA gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.