Isa 11:1-16

Isa 11:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

ẼKÀN kan yio si jade lati inu kùkute Jesse wá, ẹka kan yio si hù jade lati inu gbòngbo rẹ̀: Ẹmi Oluwa yio si bà le e, ẹmi ọgbọ́n ati oye, ẹmi igbimọ̀ ati agbara, ẹmi imọ̀ran ati ibẹ̀ru Oluwa. Õrùn-didùn rẹ̀ si wà ni ibẹ̀ru Oluwa, on ki yio si dajọ nipa ìri oju rẹ̀, bẹ̃ni ki yio dajọ nipa gbigbọ́ eti rẹ̀; Ṣugbọn yio fi ododo ṣe idajọ talakà, yio si fi otitọ ṣe idajọ fun awọn ọlọkàn tutù aiye; on o si fi ọgọ ẹnu rẹ̀ lu aiye, on o si fi ẽmi ète rẹ̀ lu awọn enia buburu pa. Ododo yio si jẹ amure ẹgbẹ́ rẹ̀, ati iṣotitọ amure inu rẹ̀. Ikõkò pẹlu yio ma ba ọdọ-agutan gbe pọ̀, kiniun yio si dubulẹ pẹlu ọmọ ewurẹ; ati ọmọ malũ ati ọmọ kiniun ati ẹgbọ̀rọ ẹran abọpa yio ma gbe pọ̀; ọmọ kekere yio si ma dà wọn. Malũ ati beari yio si ma jẹ pọ̀; ọmọ wọn yio dubulẹ pọ̀; kiniun yio si jẹ koriko bi malũ. Ọmọ ẹnu-ọmu yio si ṣire ni ihò pãmọlẹ, ati ọmọ ti a já lẹnu-ọmu yio si fi ọwọ́ rẹ̀ si ihò ejò. Nwọn ki yio panilara, bẹ̃ni nwọn ki yio panirun ni gbogbo oke mimọ́ mi: nitori aiye yio kún fun ìmọ Oluwa gẹgẹ bi omi ti bò okun. Ati li ọjọ na kùkute Jesse kan yio wà, ti yio duro fun ọpágun awọn enia; on li awọn keferi yio wá ri: isimi rẹ̀ yio si li ogo. Yio si ṣe li ọjọ na, ni Oluwa yio tun nawọ rẹ̀ lati gbà awọn enia rẹ̀ iyokù padà, ti yio kù, lati Assiria, ati lati Egipti, ati lati Patrosi, ati lati Kuṣi, ati lati Elamu, ati Ṣinari, ati lati Hamati, ati lati awọn erekùṣu okun wá. On o si gbe ọpagun kan duro fun awọn orilẹ-ède, yio si gbá awọn aṣati Israeli jọ, yio si kó awọn ti a tuka ni Juda jọ lati igun mẹrin aiye wá. Ilara Efraimu yio si tan kuro; Efraimu ki yio ṣe ilara Juda, Juda ki yio si bà Efraimu ninu jẹ. Ṣugbọn nwọn o si fò mọ ejika awọn Filistini siha iwọ̀-õrun; nwọn o jùmọ bà awọn ti ilà-õrun jẹ: nwọn o si gbe ọwọ́ le Edomu ati Moabu; awọn ọmọ Ammoni yio si gbà wọn gbọ́. Oluwa yio si pa ahọn okun Egipti run tũtũ; ẹfũfu lile rẹ̀ ni yio si mì ọwọ́ rẹ̀ lori odo na, yio si lù u ni iṣàn meje, yio si jẹ ki enia rekọja ni batà gbigbẹ. Ọna opopo kan yio si wà fun iyokù awọn enia rẹ̀, ti yio kù, lati Assiria; gẹgẹ bi o ti ri fun Israeli li ọjọ ti o goke jade kuro ni ilẹ Egipti.

Isa 11:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Èèhù kan yóo sọ jáde láti inú kùkùté igi Jese, ẹ̀ka kan yóo sì yọ jáde láti inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n ati òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn ati agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA. Ìbẹ̀rù OLUWA ni yóo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀ kì í ṣe ohun tí ó fojú rí, tabi èyí tí ó fi etí gbọ́ ni yóo fi ṣe ìdájọ́. Ṣugbọn yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn talaka, yóo fi ẹ̀tọ́ gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀, yóo fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ na ayé bíi pàṣán, yóo sì fi èémí ẹnu rẹ̀ pa àwọn oníṣẹ́ ibi. Òdodo ni yóo fi ṣe àmùrè ìgbàdí rẹ̀, yóo sì fi òtítọ́ ṣe àmùrè ìgbànú rẹ̀. Ìkookò yóo máa bá ọ̀dọ́ aguntan gbé, àmọ̀tẹ́kùn yóo sùn sílẹ̀ pẹlu ọmọ ewúrẹ́, ọmọ mààlúù, ati kinniun, ati ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa yóo jọ máa gbé pọ̀, ọmọ kékeré yóo sì máa kó wọn jẹ. Mààlúù ati ẹranko beari yóo jọ máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ wọn yóo jọ máa sùn pọ̀, kinniun yóo sì máa jẹ koríko bí akọ mààlúù. Ọmọ ọmú yóo máa ṣeré lórí ihò paramọ́lẹ̀, ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú yóo máa fi ọwọ́ bọ inú ihò ejò. Wọn kò ní ṣe eniyan ní jamba mọ́, tabi kí wọ́n bu eniyan jẹ ní gbogbo orí òkè mímọ́ mi. Nítorí ìmọ̀ OLUWA yóo kún gbogbo ayé bí omi ṣe kún gbogbo inú òkun. Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóo dúró bí àsíá fún àwọn orílẹ̀-èdè, òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa wá. Ibùgbé rẹ̀ yóo jẹ́ èyí tí ó lógo. Ní ọjọ́ náà, OLUWA yóo na ọwọ́ rẹ̀ lẹẹkeji, yóo ra àwọn eniyan rẹ̀ yòókù pada ní oko ẹrú, láti Asiria, ati Ijipti, láti Patosi ati Etiopia, láti Elamu ati Ṣinari, láti Amati ati àwọn erékùṣù òkun. Yóo gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, yóo kó àwọn Israẹli tí a ti patì jọ. Yóo ṣa àwọn ọmọ Juda tí wọ́n fọ́nká jọ, láti orígun mẹrẹẹrin ilẹ̀ ayé. Owú jíjẹ Efuraimu yóo kúrò, a óo sì pa àwọn tí ń ni Juda lára run. Efuraimu kò gbọdọ̀ jowú Juda mọ́, bẹ́ẹ̀ ni Juda kò gbọdọ̀ ni Efuraimu lára mọ. Wọn óo kọlu àwọn ará Filistini ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, wọn yóo jọ ṣẹgun àwọn ará ìlà oòrùn. Wọn yóo sì jọ dojú ìjà kọ Edomu ati Moabu. Àwọn ará Amoni yóo gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. OLUWA yóo pa Ijipti run patapata. Yóo na ọwọ́ ìjì líle sí orí odò Pirati, yóo sì pín in sí ọ̀nà meje, kí àwọn eniyan lè máa ríbi là á kọjá. Ọ̀nà tí ó gbòòrò yóo wà láti Asiria, fún ìyókù àwọn eniyan rẹ̀; bí ó ti ṣe wà fún àwọn ọmọ Israẹli, nígbà tí wọn ń bọ̀ láti Ijipti.

Isa 11:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese, láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso. Ẹ̀mí OLúWA yóò sì bà lé e ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù OLúWA Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù OLúWA. Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí, tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́, Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé. Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà. Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀ àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká. Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé, ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́ ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀ ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n. Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀, kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù. Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká, ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀. Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ OLúWA gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun. Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti Òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun. Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ, yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ, láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé. Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá, àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò, Efraimu kò ní jowú Juda, tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu. Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini sí apá ìwọ̀-oòrùn, wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn ènìyàn apá ìlà-oòrùn. Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu, àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn. OLúWA yóò sọ di gbígbé àyasí Òkun Ejibiti, pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀, kọjá lórí odò Eufurate. Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà. Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.