Isa 11:1-10

Isa 11:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Èèhù kan yóo sọ jáde láti inú kùkùté igi Jese, ẹ̀ka kan yóo sì yọ jáde láti inú àwọn gbòǹgbò rẹ̀. Ẹ̀mí OLUWA yóo bà lé e, ẹ̀mí ọgbọ́n ati òye, ẹ̀mí ìmọ̀ràn ati agbára, ẹ̀mí ìmọ̀ ati ìbẹ̀rù OLUWA. Ìbẹ̀rù OLUWA ni yóo jẹ́ ìdùnnú rẹ̀ kì í ṣe ohun tí ó fojú rí, tabi èyí tí ó fi etí gbọ́ ni yóo fi ṣe ìdájọ́. Ṣugbọn yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn talaka, yóo fi ẹ̀tọ́ gbèjà àwọn onírẹ̀lẹ̀, yóo fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ na ayé bíi pàṣán, yóo sì fi èémí ẹnu rẹ̀ pa àwọn oníṣẹ́ ibi. Òdodo ni yóo fi ṣe àmùrè ìgbàdí rẹ̀, yóo sì fi òtítọ́ ṣe àmùrè ìgbànú rẹ̀. Ìkookò yóo máa bá ọ̀dọ́ aguntan gbé, àmọ̀tẹ́kùn yóo sùn sílẹ̀ pẹlu ọmọ ewúrẹ́, ọmọ mààlúù, ati kinniun, ati ẹgbọ̀rọ̀ ẹran àbọ́pa yóo jọ máa gbé pọ̀, ọmọ kékeré yóo sì máa kó wọn jẹ. Mààlúù ati ẹranko beari yóo jọ máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ wọn yóo jọ máa sùn pọ̀, kinniun yóo sì máa jẹ koríko bí akọ mààlúù. Ọmọ ọmú yóo máa ṣeré lórí ihò paramọ́lẹ̀, ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú yóo máa fi ọwọ́ bọ inú ihò ejò. Wọn kò ní ṣe eniyan ní jamba mọ́, tabi kí wọ́n bu eniyan jẹ ní gbogbo orí òkè mímọ́ mi. Nítorí ìmọ̀ OLUWA yóo kún gbogbo ayé bí omi ṣe kún gbogbo inú òkun. Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóo dúró bí àsíá fún àwọn orílẹ̀-èdè, òun ni àwọn orílẹ̀-èdè yóo máa wá. Ibùgbé rẹ̀ yóo jẹ́ èyí tí ó lógo.

Isa 11:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese, láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso. Ẹ̀mí OLúWA yóò sì bà lé e ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù OLúWA Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù OLúWA. Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí, tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́, Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní, pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu fún àwọn aláìní ayé. Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀, pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà. Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀ àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká. Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé, ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́ ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀ ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n. Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀, àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀, kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù. Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká, ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀. Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi, nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ OLúWA gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun. Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.