Hos 2:1-23

Hos 2:1-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ wi fun awọn arakunrin nyin, Ammi; ati fun awọn arabinrin nyin, Ruhama. Ẹ ba iya nyin wijọ, ẹ wijọ; nitori on kì iṣe aya mi, bẹ̃ni emi kì iṣe ọkọ rẹ̀: nitori na jẹ ki on ki o mu gbogbo agberè rẹ̀ kuro ni iwaju rẹ̀, ati gbogbo panṣaga rẹ̀ kuro larin ọyàn rẹ̀. Ki emi má ba tú u si ihòho, emi o si gbe e kalẹ bi ọjọ ti a bi i, emi o si ṣe e bi ijù, emi o si gbe e kalẹ bi ilẹ gbigbẹ, emi o si fi ongbẹ pa a kú. Emi kì yio si ṣãnu fun awọn ọmọ rẹ̀; nitoriti nwọn jẹ́ ọmọ agbère. Nitoriti iya wọn ti hùwa agbère: ẹniti o loyun wọn ti ṣe ohun itiju: nitori ti o wipe, Emi o tun tọ̀ awọn ayànfẹ́ mi lẹhìn, ti nfun mi ni onjẹ mi ati omi mi, irun agùtan mi ati ọgbọ̀ mi, ororo mi, ati ohun mimu mi. Nitorina kiyesi i, emi o fi ẹgún sagbàra yi ọ̀na rẹ̀ ka, emi o si mọ odi, ti on kì yio fi ri ọ̀na rẹ̀ mọ. On o si lepa awọn ayànfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kì yio le ba wọn; on o si wá wọn, ṣugbọn kì yio ri wọn: nigbana ni yio wipe, Emi o padà tọ̀ ọkọ mi iṣãju lọ; nitoriti o sàn fun mi nigbana jù ti isisiyi lọ. Nitori on kò ti mọ̀ pe emi li ẹniti o fun u li ọkà, ati ọti-waini titun, ati ororo; ti mo si mu fàdakà ati wurà rẹ̀ pọ̀ si i, ti nwọn fi ṣe Baali. Nitorina li emi o ṣe padà, emi o si mu ọkà mi kuro li akokò rẹ̀, ati ọti-waini mi ni igbà rẹ̀, emi o si gbà irun agùtan ati ọgbọ̀ mi padà, ti mo ti fi fun u lati bò ihòho rẹ̀. Nisisiyi li emi o ṣi itiju rẹ̀ silẹ li oju awọn ayànfẹ́ rẹ̀, ẹnikẹni kì yio si gbà a lọwọ mi. Emi o si mu ki gbogbo ayọ̀ rẹ̀ de opin, ọjọ asè rẹ̀, oṣù titun rẹ̀, ati ọjọ isimi rẹ̀, gbogbo ọjọ ọ̀wọ rẹ̀. Emi o si pa ajàra rẹ̀ ati igi ọpọ̀tọ rẹ̀ run, niti awọn ti o ti wipe, Awọn wọnyi li èrè mi ti awọn ayànfẹ́ mi ti fi fun mi; emi o si sọ wọn di igbo, awọn ẹranko igbẹ yio si jẹ wọn. Emi o si bẹ̀ ọjọ Baalimu wò li ara rẹ̀, ninu eyiti on fi turari joná fun wọn, ti on si fi oruka eti, ati ohun ọ̀ṣọ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọṣọ, ti on si tọ̀ awọn ayànfẹ́ lẹhìn lọ, ti on si gbagbe mi, ni Oluwa wi. Nitorina, kiyesi i, emi o tàn a, emi o si mu u wá si aginjù, emi o si sọ̀rọ itùnu fun u. Emi o si fun u ni ọgbà àjara rẹ̀ lati ibẹ̀ wá, ati afonifojì Akori fun ilẹ̀kun ireti: on o si kọrin nibẹ̀, bi li ọjọ ewe rẹ̀, ati bi li ọjọ ti o jade lati ilẹ Egipti wá. Yio si ṣe li ọjọ na, iwọ o pè mi ni Iṣi; iwọ kì yio si pè mi ni Baali mọ, ni Oluwa wi, Nitori emi o mu orukọ awọn Baali kuro li ẹnu rẹ̀, a kì yio si fi orukọ wọn ranti wọn mọ́. Li ọjọ na li emi o si fi awọn ẹranko igbẹ, ati ẹiyẹ oju ọrun, ati ohun ti nrakò lori ilẹ da majẹmu fun wọn, emi o si ṣẹ́ ọrun ati idà ati ogun kuro ninu aiye, emi o si mu wọn dubulẹ li ailewu. Emi o si fẹ́ ọ fun ara mi titi lai; nitõtọ, emi o si fẹ́ ọ fun ara mi ni ododo, ni idajọ, ati ni iyọ́nu, ati ni ãnu. Emi o tilẹ fẹ́ ọ fun ara mi ni otitọ, iwọ o si mọ̀ Oluwa. Yio si ṣe li ọjọ na, emi o dahùn, emi o dá awọn ọrun li ohùn, nwọn o si da aiye lohùn; li Oluwa wi. Ilẹ yio si dá ọkà, ati ọti-waini, ati ororo, li ohùn; nwọn o si dá Jesreeli li ohùn. Emi o si gbìn i fun ara mi lori ilẹ, emi o si ṣãnu fun ẹniti kò ti ri ãnu gbà; emi o si wi fun awọn ti kì iṣe enia mi pe, Iwọ li enia mi; on o si wipe, Iwọ li Ọlọrun mi.

Hos 2:1-23 Yoruba Bible (YCE)

Pe arakunrin rẹ ní “Eniyan mi” kí o sì pe arabinrin rẹ ní “Ẹni tí ó rí àánú gbà.” Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ bá ìyá yín sọ̀rọ̀; nítorí pé kì í ṣe aya mi mọ́, ati pé èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀ mọ́. Ẹ sọ fún un pé kí ó má ṣe àgbèrè mọ́, kí ó sì fi ìṣekúṣe rẹ̀ sílẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo tú u sí ìhòòhò, n óo ṣe é bí ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí i. N óo ṣe é bí aṣálẹ̀, àní, bí ilẹ̀ tí ó gbẹ, n óo sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́ pa. N kò ní ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n. Nítorí alágbèrè ni ìyá wọn, ẹni tí ó bí wọn sì ti hùwà ainitiju. Òun fúnrarẹ̀ sọ pé, “N óo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ mi, àwọn tí wọn ń fún mi ní oúnjẹ ati omi, ati aṣọ òtútù, ati aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, ati òróró olifi ati ọtí.” Nítorí náà, n óo fi ẹ̀gún ṣe ọgbà yí i ká; n óo mọ odi yí i ká, tí kò fi ní rí ọ̀nà jáde. Yóo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kò ní lè bá wọn; yóo wá wọn káàkiri pẹlu ìtara, ṣugbọn kò ní rí wọn. Yóo wá wí nígbà náà pé, “N óo pada sọ́dọ̀ ọkọ mi àárọ̀, nítorí ó dára fún mi lọ́dọ̀ rẹ̀ ju ti ìsinsìnyìí lọ.” Kò gbà pé èmi ni mo fún òun ní oúnjẹ, tí mo fún un ní waini ati òróró, tí mo sì fún un ní ọpọlọpọ fadaka ati wúrà tí ó ń lò fún oriṣa Baali. Nítorí náà n óo gba waini ati ọkà mi pada ní àkókò wọn, n óo sì gba aṣọ òtútù ati ẹ̀wù fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun mi, tí kì bá fi bo ìhòòhò rẹ̀. N óo tú u sí ìhòòhò lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi. N óo fi òpin sí ayọ̀ rẹ̀ ati ọjọ́ àsè rẹ̀, ọjọ́ oṣù tuntun rẹ̀, ọjọ́ ìsinmi rẹ̀, ati gbogbo àjọ̀dún tí ó ti yà sọ́tọ̀. N óo run gbogbo igi àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, àwọn ohun tí ó ń pè ní owó ọ̀yà, tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ san fún un. N óo sọ ọgbà rẹ̀ di igbó, àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo sì jẹ wọ́n ní àjẹrun. N óo jẹ ẹ́ níyà fún àwọn ọjọ́ tí ó yà sọ́tọ̀, tí ó fi ń sun turari sí àwọn oriṣa Baali, tí ó kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ sára, tí ó ń sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, tí ó sì gbàgbé mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, n óo tàn án lọ sinu aṣálẹ̀, n óo bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́. N óo sì fún un ní àwọn ọgbà àjàrà rẹ̀ pada níbẹ̀, n óo sì sọ àfonífojì Akori di Ẹnu Ọ̀nà Ìrètí. Yóo kọrin fún mi bí ó tí ń ṣe ní ìgbà èwe rẹ̀, nígbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Ijipti dé. OLUWA ní, nígbà tí ó bá yá, yóo máa pè mí ní ọkọ rẹ̀, kò ní pè mí ní Baali rẹ̀ mọ́. Nítorí pé, n óo gba orúkọ Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀, kò sì ní dárúkọ rẹ̀ mọ́. Nígbà náà ni n óo tìtorí tirẹ̀ bá àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn nǹkan tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ dá majẹmu, n óo sì mú ọfà, idà, ati ogun kúrò ní ilẹ̀ náà. N óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ní alaafia ati ní àìléwu. Ìwọ Israẹli, n óo sọ ọ́ di iyawo mi títí lae; n óo sọ ọ́ di iyawo mi lódodo ati lótìítọ́, ninu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati àánú. N óo sọ ọ́ di iyawo mi, lótìítọ́, o óo sì mọ̀ mí ní OLUWA. OLUWA ní, “Ní ọjọ́ náà, n óo dáhùn adura ojú ọ̀run, ojú ọ̀run yó sì dáhùn adura ilẹ̀. Ilẹ̀ yóo sì dáhùn adura ọkà, ati ti waini ati ti òróró. Àwọn náà óo sì dáhùn adura Jesireeli. N óo fi ìdí àwọn eniyan mi múlẹ̀ ní ilẹ̀ náà, wọn yóo sì máa bí sí i. N óo ṣàánú ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kò sí àánú’, n óo sì sọ fún ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kì í ṣe eniyan mi’ pé eniyan mi ni; òun náà yóo sì dá mi lóhùn pé, ‘Ìwọ ni Ọlọrun mi.’ ”

Hos 2:1-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘àyànfẹ́ mi.’ “Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí, nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi, Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀. Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀ àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀. Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòhò Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ bí ọjọ́ tí a bí i. Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀, Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀ Èmi yóò sì fi òǹgbẹ gbẹ ẹ́. Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀ nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́ Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè, ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú. Ó wí pé, ‘èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn, tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi, ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi, òróró mi àti ohun mímu mi.’ Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ. Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn; Yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn. Nígbà náà ni yóò sọ pé, ‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́ nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’ Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọpọ̀ Èyí tí wọ́n lò fún Baali. “Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n, èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀. Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀. Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin: àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀, ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àjọ̀dún tí a yàn. Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run, èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, Èmi yóò sọ wọ́n di igbó, àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run. Èmi yóò bẹ̀ ọjọ́ Baalimu wò ní ara rẹ̀ nínú èyí tó ń fi tùràrí jóná fún Baali; tí ó fi òrùka etí àti ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n èmi ni òun gbàgbé,” ni OLúWA wí. “Nítorí náà, èmi yóò tàn án Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀ Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀ Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un, Èmi yóò fi Àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un. Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti. “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà, Ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’; Ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’ ni OLúWA wí. Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀; ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́ Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀. Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́ Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu. Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé. Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú. Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́ ìwọ yóò sì mọ OLúWA. “Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà” ni OLúWA wí. “Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn; Ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró lóhùn Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn. Èmi ó sì gbìn ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘àánú Gbà.’ Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’ ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”