Hos 14:1-9
Hos 14:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
ISRAELI, yipadà si Oluwa Ọlọrun rẹ, nitori iwọ ti ṣubu ninu aiṣedẽde rẹ. Mu ọ̀rọ pẹlu nyin, ẹ si yipadà si Oluwa: ẹ wi fun u pe, Mu aiṣedẽde gbogbo kuro, si fi ore-ọfẹ gbà wa: bẹ̃ni awa o fi ọmọ malu ète wa san a fun ọ. Assuru kì yio gbà wa; awa kì yio gùn ẹṣin: bẹ̃ni awa kì yio tun wi mọ fun iṣẹ ọwọ́ wa pe, Ẹnyin li ọlọrun wa: nitori lọdọ rẹ ni alainibaba gbe ri ãnu. Emi o wo ifàsẹhìn wọn sàn, emi o fẹ wọn lọfẹ: nitori ibinu mi yí kuro lọdọ rẹ̀. Emi o dabi ìri si Israeli: on o tanná bi eweko lili; yio si ta gbòngbo rẹ̀ bi Lebanoni. Ẹka rẹ̀ yio tàn, ẹwà rẹ̀ yio si dabi igi olifi, ati õrùn rẹ̀ bi Lebanoni. Awọn ti o ngbe abẹ ojiji rẹ̀ yio padà wá; nwọn o sọji bi ọkà: nwọn o si tanná bi àjara: õrun rẹ̀ yio dabi ọti-waini ti Lebanoni. Efraimu yio wipe, Kili emi ni fi òriṣa ṣe mọ? Emi ti gbọ́, mo si ti kiyesi i: emi dabi igi firi tutù. Lati ọdọ mi li a ti ri èso rẹ. Tali o gbọ́n, ti o lè moye nkan wọnyi? tali o li oye, ti o le mọ̀ wọn? nitori ọ̀na Oluwa tọ́, awọn olododo yio si ma rìn ninu wọn: ṣugbọn awọn alarekọja ni yio ṣubu sinu wọn.
Hos 14:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ pada tọ OLUWA Ọlọrun yín lọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, nítorí pé ẹ ti kọsẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ pada sọ́dọ̀ OLUWA, kí ẹ sọ pé, “Mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, gba ohun tí ó dára a óo sì máa yìn ọ́ lógo. Asiria kò lè gbà wá là, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní gun ẹṣin; a kò sì ní pe oriṣa, tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wa, ní Ọlọrun wa mọ́. OLUWA, ìwọ ni ò ń ṣàánú fún ọmọ tí kò lẹ́nìkan.” Ọlọrun ní, “N óo gba ìwà aiṣootọ lọ́wọ́ wọn, n óo fẹ́ wọn tọkàntọkàn, nítorí n kò bínú sí wọn mọ́. Bí ìrì ni n óo máa sẹ̀ sí Israẹli, ẹwà rẹ̀ yóo yọ bí òdòdó lílì, gbòǹgbò rẹ̀ yóo sì múlẹ̀ bíi gbòǹgbò igi kedari Lẹbanoni. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo tàn kálẹ̀; ẹwà rẹ̀ yóo yọ bíi ti igi olifi, òórùn rẹ̀ yóo sì dàbí ti igi Lẹbanoni. Wọn óo pada sábẹ́ ààbò mi, wọn óo rúwé bí igi inú ọgbà; wọn óo sì tanná bí àjàrà, òórùn wọn óo dàbí ti waini Lẹbanoni. Efuraimu yóo sọ pé, ‘kí ni mo ní ṣe pẹlu àwọn oriṣa?’ Nítorí èmi ni n óo máa gbọ́ adura rẹ̀, tí n óo sì máa tọ́jú rẹ̀. Mo dàbí igi sipirẹsi tí kì í wọ́wé tòjò tẹ̀ẹ̀rùn. Lọ́dọ̀ mi ni èso rẹ̀ ti ń wá.” Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́n, kí ó mọ àwọn nǹkan wọnyi; kí òye rẹ̀ sì yé ẹnikẹ́ni tí ó bá lóye; nítorí pé ọ̀nà OLUWA tọ́, àwọn tí wọ́n bá dúró ṣinṣin ni yóo máa tọ̀ ọ́, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kọsẹ̀ níbẹ̀.
Hos 14:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Yípadà ìwọ Israẹli sí OLúWA Ọlọ́run rẹ. Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ló fa ìparun rẹ! Ẹ gba ọ̀rọ̀ OLúWA gbọ́, kí ẹ sì yípadà sí OLúWA. Ẹ sọ fún un pé: “Darí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá kí o sì fi oore-ọ̀fẹ́ gbà wá, kí àwa kí ó lè fi ètè wa sán an fún ọ Asiria kò le gbà wá là; A kò ní í gorí ẹṣin ogun A kò sì ní tún sọ ọ́ mọ́ láé ‘Àwọn ni òrìṣà wa sí àwọn ohun tí ó fi ọwọ́ wa ṣe; nítorí pé lọ́dọ̀ rẹ ni àwọn aláìní baba tí ń rí àánú.’ “Èmi wo àgàbàgebè wọn sàn, Èmi ó sì fẹ́ràn wọn, lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí ìbínú mi ti yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn. Èmi o dàbí ìrì sí Israẹli wọn o sì yọ ìtànná bi ewéko lílì Bi kedari ti Lebanoni yóò si ta gbòǹgbò Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ẹ̀ka rẹ̀ yóò dàgbà, Dídán ẹwà yóò rẹ̀ dànù bí igi olifi Òórùn rẹ yóò sì dàbí igi kedari ti Lebanoni. Àwọn ènìyàn yóò tún padà gbé lábẹ́ òjijì rẹ̀. Yóò rúwé bi ọkà. Yóò sì yọ ìtànná bi àjàrà, òórùn rẹ yóò dàbí ti wáìnì Lebanoni. Ìwọ Efraimu; Kín ló tún kù tí mo ní ṣe pẹ̀lú ère òrìṣà? Èmi ó dá a lóhùn, èmi ó sì ṣe ìtọ́jú rẹ. Mo dàbí igi junifa tó ń fi gbogbo ìgbà tutù, èso tí ìwọ ń so si ń wá láti ọ̀dọ̀ mi.” Ta ni ọlọ́gbọ́n? Òun yóò mòye àwọn nǹkan wọ̀nyí Ta a ní ó mọ̀? Òun yóò ní ìmọ̀ wọn. Títọ́ ni ọ̀nà OLúWA àwọn olódodo si ń rìn nínú wọn Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́tẹ̀ ni yóò kọsẹ̀ nínú wọn.