Hos 13:1-16

Hos 13:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI Efraimu sọ̀rọ, ìwarìri ni; o gbe ara rẹ̀ ga ni Israeli; ṣugbọn nigbati o ṣẹ̀ ninu Baali, o kú. Nisisiyi, nwọn si dá ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ, nwọn si ti fi fàdakà wọn ṣe ere didà fun ara wọn, ati òriṣa ìmọ wọn: iṣẹ oniṣọnà ni gbogbo rẹ̀; nwọn wi niti wọn pe, Jẹ ki awọn enia ti nrubọ fi ẹnu kò awọn ọmọ malu li ẹnu. Nitorina ni nwọn o ṣe dabi kũkũ owurọ̀, ati bi irì owurọ̀ ti nkọja lọ, bi iyangbò ti a ti ọwọ́ ijì gbá kuro ninu ilẹ ipakà, ati bi ẹ̃fin ti ijade kuro ninu ile ẹ̃fin. Ṣugbọn emi li Oluwa Ọlọrun rẹ lati ilẹ Egipti wá, iwọ kì yio si mọ̀ ọlọrun kan bikòṣe emi: nitori kò si olugbàla kan lẹhìn mi. Emi ti mọ̀ ọ li aginjù, ni ilẹ ti o pongbẹ. Gẹgẹ bi a ti bọ́ wọn, bẹ̃ni nwọn yó; nwọn yó, nwọn si gbe ọkàn wọn ga; nitorina ni nwọn ṣe gbagbe mi. Nitorina li emi o ṣe dabi kiniun si wọn; emi o si ma ṣọ wọn bi ẹkùn li ẹ̀ba ọ̀na. Emi o pade wọn bi beari ti a gbà li ọ̀mọ, emi o si fà àwọn ọkàn wọn ya, nibẹ̀ ni emi o si jẹ wọn run bi kiniun, ẹranko igbẹ ni yio fà wọn ya. Israeli, iwọ ti pa ara rẹ run, niti pe iwọ wà lodi si emi, irànlọwọ rẹ. Nibo li ọba rẹ gbe wà nisisiyi ninu gbogbo ilu rẹ, ti o le gbà ọ? ati awọn onidajọ rẹ, niti awọn ti iwọ wipe; Fun mi li ọba ati awọn ọmọ-alade. Emi fun ọ li ọba ni ibinu mi, mo si mu u kuro ni irúnu mi. A dì aiṣedẽde Efraimu; ẹ̀ṣẹ rẹ̀ pamọ. Irora obinrin ti nrọbi yio de si i: alaigbọn ọmọ li on; nitori on kò duro li akokò si ibi ijade ọmọ. Emi o rà wọn padà lọwọ agbara isà-okú; Emi o rà wọn padà lọwọ ikú; Ikú, ajàkalẹ arùn rẹ dà? Isà-okú, iparun rẹ dà? ironupiwàda yio pamọ kuro loju mi. Bi on tilẹ ṣe eleso ninu awọn arakunrin rẹ̀, afẹfẹ́ ilà-õrùn kan yio de, afẹ̃fẹ́ Oluwa yio ti aginjù wá, orisun rẹ̀ yio si gbẹ, ati oju isun rẹ̀ li a o mu gbẹ: on o bà ohun elò daradara gbogbo jẹ. Samaria yio di ahoro: nitoriti on ti ṣọ̀tẹ si Ọlọrun rẹ̀: nwọn o ti ipa idà ṣubu: a o fọ́ ọmọ wọn tũtũ, ati aboyún wọn li a o là ni inu.

Hos 13:1-16 Yoruba Bible (YCE)

Tẹ́lẹ̀ rí, bí ẹ̀yà Efuraimu bá sọ̀rọ̀, àwọn eniyan a máa wárìrì; wọ́n níyì láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, ṣugbọn nítorí pé wọ́n bọ oriṣa Baali, wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì kú. Nisinsinyii, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yá ère fún ara wọn; ère fadaka, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan, Wọ́n ń sọ pé, “Ẹ wá rúbọ sí i.” Eniyan wá ń fi ẹnu ko ère mààlúù lẹ́nu! Nítorí náà, wọn óo dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí máa ń yára gbẹ, wọ́n óo dàbí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kúrò ní ibi ìpakà, ati bí èéfín tí ń jáde láti ojú fèrèsé. OLUWA ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, láti ìgbà tí ẹ ti wà ní ilẹ̀ Ijipti: ẹ kò ní Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ní olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi. Èmi ni mo ṣe ìtọ́jú yín nígbà tí ẹ wà ninu aṣálẹ̀, ninu ilẹ̀ gbígbẹ; ṣugbọn nígbà tí ẹ jẹun yó tán, ẹ̀ ń gbéraga, ẹ gbàgbé mi. Nítorí náà, bíi kinniun ni n óo ṣe si yín, n óo lúgọ lẹ́bàá ọ̀nà bí àmọ̀tẹ́kùn; n óo yọ si yín bí ẹranko beari tí wọ́n kó lọ́mọ lọ, n óo sì fa àyà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. N óo ya yín jẹ bíi kinniun, bí ẹranko burúkú ṣe ń fa ẹran ya. “N óo pa yín run, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; ta ni yóo ràn yín lọ́wọ́? Níbo ni ọba yín wà nisinsinyii, tí yóo gbà yín là? Níbo ni àwọn olórí yín wà, tí wọn yóo gbèjà yín? Àwọn tí ẹ bèèrè fún, tí ẹ ní, ‘Ẹ fún wa ní ọba ati àwọn ìjòyè.’ Pẹlu ibinu, ni mo fi fun yín ní àwọn ọba yín, ìrúnú ni mo sì fi mú wọn kúrò. “A ti di ẹ̀ṣẹ̀ Efuraimu ní ìtí ìtí, a ti kó ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pamọ́. Àwọn ọmọ Israẹli ní anfaani láti wà láàyè, ṣugbọn ìwà òmùgọ̀ wọn kò jẹ́ kí wọ́n lo anfaani náà. Ó dàbí ọmọ tí ó kọ̀, tí kò jáde kúrò ninu ìyá rẹ̀ ní àkókò ìrọbí. N kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú, n kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ ikú. Ikú! Níbo ni àjàkálẹ̀ àrùn rẹ wà? Ìwọ isà òkú! Ìparun rẹ dà? Àánú kò sí lójú mi mọ́. Bí Israẹli tilẹ̀ rúwé bí ewéko etí odò, atẹ́gùn OLUWA láti ìlà oòrùn yóo fẹ́ wá, yóo wá láti inú aṣálẹ̀; orísun rẹ̀ yóo gbẹ, ojú odò rẹ̀ yóo sì gbẹ pẹlu; a óo kó ìṣúra ati ohun èlò olówó iyebíye rẹ̀ kúrò. Samaria ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi Ọlọrun rẹ̀, ogun ni yóo pa wọ́n, a óo ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, a óo sì la inú àwọn aboyún wọn.”

Hos 13:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà ti Efraimu bá ń sọ̀rọ̀, àwọn ènìyàn máa ń wárìrì, a gbé e ga ní Israẹli ṣùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀sùn pé ó ń sin òrìṣà Baali, ó sì kú. Báyìí, wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ wọn fi fàdákà ṣe ère òrìṣà fúnrawọn ère tí a fi ọgbọ́n dá àrà sí gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà Wọn ń sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Pé, Jẹ́ kí àwọn “Ènìyàn tí ń rú ẹbọ fi ẹnu ko àwọn ẹgbọrọ màlúù ni ẹnu.” Nítorí náà wọn yóò dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀, bí ìrì òwúrọ̀ kùtùkùtù tó máa ń parẹ́, bí i èèpo ìyẹ̀fun tí afẹ́fẹ́ gbé láti ibi ìpakà bí èéfín tó rú jáde gba ojú fèrèsé. “Ṣùgbọ́n Èmi ni OLúWA Ọlọ́run rẹ̀, ẹni tó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá. Ìwọ̀ kì yóò sì mọ ọlọ́run mìíràn àfi èmi kò sí olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi Mo ṣe ìtọ́jú rẹ ní aginjù ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí kò ní omi Wọn ni ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí mo fún wọn ní oúnjẹ Nígbà tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tan wọ́n di agbéraga Nígbà náà ni wọ́n sì gbàgbé mi. Nítorí náà, Èmi yóò dìde sí wọn bí i kìnnìún Èmi yóò fi ara pamọ́ dè wọ́n lọ́nà bí i ẹkùn. Beari igbó tí a já ọmọ rẹ̀ gbà Èmi yóò bá wọn jà bí? Èmi yóò sì fà wọ́n ya bí ìgbà tí ẹkùn bá fa ara wọn ya bi ẹranko búburú ni èmi yóò fa wọn ya. “A ti pa ọ́ run, ìwọ Israẹli nítorí pé ìwọ lòdì sí mi, ìwọ lòdì sí olùrànlọ́wọ́ rẹ. Níbo ni ọba rẹ gbé wà nísinsin yìí kí ó bá à le gbà ọ là? Níbo ni àwọn olórí ìlú yín wà, àwọn tí ẹ sọ pé, ‘Fún wa ní ọba àti ọmọ-aládé’? Nítorí èyí nínú ìbínú mi ni mo fún un yín ní ọba, Nínú ìbínú gbígbóná mi, mo sì mú un kúrò. Ẹ̀bi Efraimu ni a tí ko jọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀ Ìrora bí obìnrin tó fẹ́ bímọ ti dé bá a Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ tí kò lọ́gbọ́n Nígbà tí àsìkò tó, ó kọ̀ láti jáde síta láti inú. “Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú. Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú Ikú, àjàkálẹ̀-ààrùn rẹ dà? Isà òkú, ìparun rẹ dà? “Èmi kò ní ṣàánú mọ́. Bí ó tilẹ̀ gbilẹ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀ afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀dọ̀ OLúWA yóò wá, Yóò fẹ́ wá láti inú aginjù orísun omi rẹ̀ yóò gbẹ kànga rẹ̀ yóò gbẹ pẹ̀lú olè yóò fọ́ ilé ẹrù àti gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀ Ará Samaria gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn, nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run wọn. Wọn ó ti ipa idà ṣubú; a ó fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, A ó sì la àwọn aboyún wọn nínú.”