Hos 13

13
Paríparí Ìdájọ́ Israẹli
1NIGBATI Efraimu sọ̀rọ, ìwarìri ni; o gbe ara rẹ̀ ga ni Israeli; ṣugbọn nigbati o ṣẹ̀ ninu Baali, o kú.
2Nisisiyi, nwọn si dá ẹ̀ṣẹ kún ẹ̀ṣẹ, nwọn si ti fi fàdakà wọn ṣe ere didà fun ara wọn, ati òriṣa ìmọ wọn: iṣẹ oniṣọnà ni gbogbo rẹ̀; nwọn wi niti wọn pe, Jẹ ki awọn enia ti nrubọ fi ẹnu kò awọn ọmọ malu li ẹnu.
3Nitorina ni nwọn o ṣe dabi kũkũ owurọ̀, ati bi irì owurọ̀ ti nkọja lọ, bi iyangbò ti a ti ọwọ́ ijì gbá kuro ninu ilẹ ipakà, ati bi ẹ̃fin ti ijade kuro ninu ile ẹ̃fin.
4Ṣugbọn emi li Oluwa Ọlọrun rẹ lati ilẹ Egipti wá, iwọ kì yio si mọ̀ ọlọrun kan bikòṣe emi: nitori kò si olugbàla kan lẹhìn mi.
5Emi ti mọ̀ ọ li aginjù, ni ilẹ ti o pongbẹ.
6Gẹgẹ bi a ti bọ́ wọn, bẹ̃ni nwọn yó; nwọn yó, nwọn si gbe ọkàn wọn ga; nitorina ni nwọn ṣe gbagbe mi.
7Nitorina li emi o ṣe dabi kiniun si wọn; emi o si ma ṣọ wọn bi ẹkùn li ẹ̀ba ọ̀na.
8Emi o pade wọn bi beari ti a gbà li ọ̀mọ, emi o si fà àwọn ọkàn wọn ya, nibẹ̀ ni emi o si jẹ wọn run bi kiniun, ẹranko igbẹ ni yio fà wọn ya.
9Israeli, iwọ ti pa ara rẹ run, niti pe iwọ wà lodi si emi, irànlọwọ rẹ.
10Nibo li ọba rẹ gbe wà nisisiyi ninu gbogbo ilu rẹ, ti o le gbà ọ? ati awọn onidajọ rẹ, niti awọn ti iwọ wipe; Fun mi li ọba ati awọn ọmọ-alade.
11Emi fun ọ li ọba ni ibinu mi, mo si mu u kuro ni irúnu mi.
12A dì aiṣedẽde Efraimu; ẹ̀ṣẹ rẹ̀ pamọ.
13Irora obinrin ti nrọbi yio de si i: alaigbọn ọmọ li on; nitori on kò duro li akokò si ibi ijade ọmọ.
14Emi o rà wọn padà lọwọ agbara isà-okú; Emi o rà wọn padà lọwọ ikú; Ikú, ajàkalẹ arùn rẹ dà? Isà-okú, iparun rẹ dà? ironupiwàda yio pamọ kuro loju mi.
15Bi on tilẹ ṣe eleso ninu awọn arakunrin rẹ̀, afẹfẹ́ ilà-õrùn kan yio de, afẹ̃fẹ́ Oluwa yio ti aginjù wá, orisun rẹ̀ yio si gbẹ, ati oju isun rẹ̀ li a o mu gbẹ: on o bà ohun elò daradara gbogbo jẹ.
16Samaria yio di ahoro: nitoriti on ti ṣọ̀tẹ si Ọlọrun rẹ̀: nwọn o ti ipa idà ṣubu: a o fọ́ ọmọ wọn tũtũ, ati aboyún wọn li a o là ni inu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Hos 13: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀