Heb 8:6-13

Heb 8:6-13 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn nisinsinyii iṣẹ́ ìsìn ti Olórí Alufaa wa dára pupọ ju ti àwọn ọmọ Lefi lọ, nítorí pé majẹmu tí ó jẹ́ alárinà fún dára ju ti àtijọ́ lọ, ìdí ni pé ìlérí tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ ni majẹmu yìí dúró lé lórí. Bí majẹmu ti àkọ́kọ́ kò bá ní àbùkù, kò sí ìdí tí à bá fi fi òmíràn dípò rẹ̀. Nítorí Ọlọrun rí ẹ̀ṣẹ̀ kà sí wọn lọ́rùn ni ó fi sọ pé, “Oluwa wí pé: Ọjọ́ ń bọ̀ tí èmi yóo bá ilé Israẹli ati ilé Juda dá majẹmu titun. Kì í ṣe irú majẹmu tí mo bá àwọn baba wọn dá ní ọjọ́ tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nítorí wọn kò pa majẹmu mi mọ́, mo bá kẹ̀yìn sí wọn. Èyí ni majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tí ó bá yá. N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo kọ ọ́ sí ọkàn wọn, èmi óo jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi. Kì yóo sí ìdí tí ẹnìkan yóo fi kọ́ aládùúgbò rẹ̀ tabi arakunrin rẹ̀, pé, ‘Mọ Oluwa.’ Nítorí pé gbogbo wọn ni wọn óo mọ̀ mí, ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí àwọn mẹ̀kúnnù inú wọn títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki. Nítorí n óo fi àánú fojú fo ìwà burúkú wọn, n kò sì ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” Nígbà tí ó sọ̀rọ̀ nípa majẹmu titun, ohun tí ó ń sọ ni pé ti àtijọ́ ti di ògbólógbòó. Ohun tí ó bá sì ti di ògbólógbòó, kò níí pẹ́ parẹ́.

Heb 8:6-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ni ọlá jù, níwọ̀n bí o ti jẹ pé alárinà májẹ̀mú tí o dára jù ní i ṣe, èyí tí a fi ṣe òfin lórí ìlérí tí o sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣáájú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá ààyè fún èkejì. Nítorí tí ó rí àbùkù lára wọn, ó wí pé, “Ìgbà kan ń bọ̀, ni Olúwa wí, tí Èmi yóò bá ilé Israẹli àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun. Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú tí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, nítorí wọn kò jẹ́ olóòtítọ́ sí májẹ̀mú mi èmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wí Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí. Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn, èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn, èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi. Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀, tàbí olúkúlùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘mọ Olúwa,’ Nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí, láti kékeré dé àgbà. Nítorí pé èmi ó ṣàánú fún àìṣòdodo wọn, àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéé wọn lèmi ki yóò sì rántí mọ́.” Ní èyí tí ó wí pé, májẹ̀mú títún ó ti sọ ti ìṣáájú di ti láéláé. Ṣùgbọ́n èyí tí ó ń di i ti láéláé tí ó sì ń gbó, o múra àti di asán.