Heb 8:1-7
Heb 8:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ pataki ninu ohun ti a nsọ li eyi: Awa ni irú Olori Alufa bẹ̃, ti o joko li ọwọ́ ọtún itẹ́ ọla nla ninu awọn ọrun: Iranṣẹ ibi mimọ́, ati ti agọ́ tõtọ, ti Oluwa pa, kì iṣe enia. Nitori a fi olukuluku olori alufa jẹ lati mã mu ẹ̀bun wá ati lati mã rubọ: nitorina olori alufa yi pẹlu kò le ṣe aini ohun ti yio fi rubọ. Nisisiyi ibaṣepe o mbẹ li aiye, on kì bá tilẹ jẹ alufa, nitori awọn ti nfi ẹbun rubọ gẹgẹ bi ofin mbẹ: Awọn ẹniti njọsìn fun apẹrẹ ati ojiji awọn ohun ọrun, bi a ti kọ́ Mose lati ọdọ Ọlọrun wá nigbati o fẹ pa agọ́: nitori o wipe, kiyesi ki o ṣe ohun gbogbo gẹgẹ bi apẹrẹ ti a fihàn ọ lori òke. Ṣugbọn nisisiyi o ti gbà iṣẹ iranṣẹ ti o ni ọlá jù, niwọn bi o ti jẹ pe alarina majẹmu ti o dara jù ni iṣe, eyiti a fi ṣe ofin lori ileri ti o sàn jù bẹ̃ lọ. Nitori ibaṣepe majẹmu iṣaju nì kò li àbuku, njẹ a kì ba ti wá àye fun ekeji.
Heb 8:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Kókó ohun tí à ń sọ nìyí, pé a ní irú Olórí Alufaa báyìí, ẹni tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ ọlá ńlá ní ọ̀run. Òun yìí ni òjíṣẹ́ ní ilé ìsìn tí ó mọ́ jùlọ tíí ṣe àgọ́ tòótọ́, tí Oluwa fúnrarẹ̀ kọ́, kì í ṣe èyí tí eniyan kọ́. Nítorí gbogbo Olórí Alufaa tí a bá yàn, a yàn wọ́n pé kí wọ́n máa mú ẹ̀bùn ati ẹbọ àwọn eniyan wá siwaju Ọlọrun ni. Bákan náà ni òun náà níláti ní àwọn ohun tí yóo máa mú wá siwaju Ọlọrun. Bí ó bá jẹ́ pé ó wà ninu ayé, kì bá tí jẹ́ alufaa rárá, nítorí àwọn alufaa wà tí wọn ń mú ẹ̀bùn àwọn eniyan lọ siwaju Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. Àwọn yìí ń ṣe ìsìn wọn ninu ilé ìsìn tí ó jẹ́ ẹ̀dà ati àfijọ ti ọ̀run. A rí i pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí nítorí nígbà tí Mose fẹ́ kọ́ àgọ́, ohun tí Ọlọrun sọ fún un ni pé, “Ṣe akiyesi pé o ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí mo fihàn ọ́ ní orí òkè.” Ṣugbọn nisinsinyii iṣẹ́ ìsìn ti Olórí Alufaa wa dára pupọ ju ti àwọn ọmọ Lefi lọ, nítorí pé majẹmu tí ó jẹ́ alárinà fún dára ju ti àtijọ́ lọ, ìdí ni pé ìlérí tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ ni majẹmu yìí dúró lé lórí. Bí majẹmu ti àkọ́kọ́ kò bá ní àbùkù, kò sí ìdí tí à bá fi fi òmíràn dípò rẹ̀.
Heb 8:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nísinsin yìí, kókó ohun tí à ń sọ nìyí: Àwa ní irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀, tí ó jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọláńlá nínú àwọn ọ̀run: ìránṣẹ́ ibi mímọ́, àti ti àgọ́ tòótọ́, tí Olúwa pa, kì í ṣe ènìyàn. Nítorí a fi olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan jẹ láti máa mú ẹ̀bùn wá láti máa rú ẹbọ: Nítorí náà ó ṣe pàtàkì fún eléyìí náà láti ní nǹkan tí ó máa fi sílẹ̀. Tí ó bá jẹ́ pé ó wà ní ayé ni, òun kì bá ti jẹ́ àlùfáà, nítorí pé àwọn ọkùnrin tí ó ń fi ẹ̀bùn sílẹ̀ ti wà bí òfin ṣe là á sílẹ̀. Àwọn ẹni tí ń jọ́sìn nínú pẹpẹ kan tí ó jẹ́ àpẹẹrẹ àti òjìji ohun tí ń bẹ ní ọ̀run. Ìdí abájọ nìyí tí a fi kìlọ̀ fún Mose nígbà tí ó fẹ́ kọ́ àgọ́: Nítorí ó wí pé, “Kíyèsí i, kí ìwọ kí ó ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ wọn, ti a fi hàn ọ́ ni orí òkè.” Ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ni ọlá jù, níwọ̀n bí o ti jẹ pé alárinà májẹ̀mú tí o dára jù ní i ṣe, èyí tí a fi ṣe òfin lórí ìlérí tí o sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣáájú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá ààyè fún èkejì.