Heb 4:9-11
Heb 4:9-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina isimi kan kù fun awọn enia Ọlọrun. Nitoripe ẹniti o ba bọ́ sinu isimi rẹ̀, on pẹlu simi kuro ninu iṣẹ tirẹ̀, gẹgẹ bi Ọlọrun ti simi kuro ni tirẹ̀. Nitorina ẹ jẹ ki a mura giri lati wọ̀ inu isimi na, ki ẹnikẹni ki o má ba ṣubu nipa apẹrẹ aigbagbọ́ kanna.
Heb 4:9-11 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ìsinmi ọjọ́ ìsinmi wà nílẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun. Nítorí ẹni tí ó bá wọ inú ìsinmi rẹ̀ ti sinmi ninu iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sinmi ninu tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á sa gbogbo ipá wa láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú ati àìgbọràn bíi ti àwọn tí à ń sọ̀rọ̀ wọn.
Heb 4:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
nítorí náà ìsinmi kan kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Nítorí pé ẹni tí ó ba bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀, òun pẹ̀lú sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti sinmi kúrò nínú iṣẹ́ tirẹ̀. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á múra gírí láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má ba à ṣubú nípa irú àìgbàgbọ́ kan náà.