Heb 4:12-13
Heb 4:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ọ̀rọ Ọlọrun yè, o si li agbara, o si mú jù idàkídà oloju meji lọ, o si ngúnni ani tìti de pipín ọkàn ati ẹmí niya, ati oríke ati ọrá inu egungun, on si ni olumọ̀ erò inu ati ète ọkàn. Kò si si ẹda kan ti kò farahan niwaju rẹ̀, ṣugbọn ohun gbogbo ni o wà nihoho ti a si ṣipaya fun oju rẹ̀ ẹniti awa ni iba lo.
Heb 4:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè, ó sì lágbára. Ó mú ju idà olójú meji lọ. Ó mú tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi lè gé ẹ̀mí kúrò lára ọkàn, ó sì lè rẹ́ mùdùnmúdùn kúrò lára àwọn oríkèé ara. Ó yára láti mọ ète ati èrò ọkàn eniyan. Kò sí ẹ̀dá kan tí ó lè fara pamọ́ níwájú rẹ̀. Gbogbo nǹkan ṣípayá kedere níwájú Ọlọrun, ẹni tí a óo jíyìn iṣẹ́ wa fún.
Heb 4:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ní agbára, ó sì mu ju idàkídà olójú méjì lọ, ó sì ń gún ni, àní títí dé pínpín ọkàn àti ẹ̀mí ní yà, àti ní oríkèé àti ọ̀rá inú egungun, òun sì ni olùmọ̀ èrò inú àti ète ọkàn. Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòhò tí a sì ṣípáyà fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn.