Heb 1:5-6
Heb 1:5-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ewo ninu awọn angẹli li o wi fun rí pe, Iwọ li Ọmọ mi, loni ni mo bí ọ? Ati pẹlu, Emi yio jẹ Baba fun u, on yio si jẹ Ọmọ fun mi? Ati pẹlu, nigbati o mu akọbi ni wá si aiye, o wipe, Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun u.
Heb 1:5-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn angẹli tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; lónìí ni mo bí ọ”? Àti pẹ̀lú pé; “Èmi yóò jẹ́ baba fún un, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi”? Àti pẹ̀lú, nígbà tí Ọlọ́run rán àkọ́bí rẹ̀ wá si ayé wa yìí. Ó pàṣẹ pé, “Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọ́run foríbalẹ̀ fún un.”
Heb 1:5-6 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé, “Ìwọ ni ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ?” Tabi tí ó sọ fún pé, “Èmi yóo jẹ́ baba fún un, òun náà yóo sì jẹ́ ọmọ fún mi?” Ṣugbọn nígbà tí ó mú àkọ́bí rẹ̀ wọ inú ayé, ohun tí ó sọ ni pé, “Kí gbogbo àwọn angẹli Ọlọrun foríbalẹ̀ fún un.”