Heb 1:13-14
Heb 1:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ewo ninu awọn angẹli li o sọ nipa rẹ̀ ri pe, Joko li ọwọ́ ọtún mi, titi emi o fi sọ awọn ọtá rẹ di apoti itisẹ rẹ? Ẹmí ti njiṣẹ ki gbogbo wọn iṣe, ti a nran lọ lati mã jọsin nitori awọn ti yio jogun igbala?
Pín
Kà Heb 1Heb 1:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Èwo ninu àwọn angẹli ni ó fi ìgbà kan sọ fún pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí n óo fi ṣe àwọn ọ̀tá rẹ ní àpótí ìtìsẹ̀ rẹ?” Ṣebí ẹ̀mí tí ó jẹ́ iranṣẹ ni gbogbo àwọn angẹli. A rán wọn láti ṣiṣẹ́ nítorí àwọn tí yóo jogún ìgbàlà.
Pín
Kà Heb 1Heb 1:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èwo nínú àwọn angẹli ní a gbọ́ pé Ọlọ́run fi ìgbà kan wí fún pé, “Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ”? Kì í ha á ṣe ẹ̀mí tí ń jíṣẹ́ ni àwọn angẹli í ṣe bí; tí a rán lọ síta láti máa ṣiṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?
Pín
Kà Heb 1