Hab 2:2-5
Hab 2:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Oluwa si da mi lohùn, o si wipe, Kọ iran na, ki o si hàn a lara wàlã, ki ẹniti nkà a, le ma sare. Nitori iran na jẹ ti igbà kan ti a yàn, yio ma yára si igbẹhìn, kì yio si ṣeke, bi o tilẹ̀ pẹ, duro dè e, nitori ni dide, yio de, kì yio pẹ. Kiyesi i, ọkàn rẹ̀ ti o gbega, kò duro ṣinṣin ninu rẹ̀: ṣugbọn olododo yio wà nipa ìgbagbọ́ rẹ̀. Bẹ̃ni pẹlu, nitoriti ọti-waini li ẹtàn, agberaga enia li on, kì isi simi, ẹniti o sọ ifẹ rẹ̀ di gbigbõrò bi ipò-okú, o si dabi ikú, a kò si lè tẹ́ ẹ lọrun, ṣugbọn o kó gbogbo orilẹ-ède jọ si ọdọ, o si gbá gbogbo enia jọ si ọdọ rẹ̀
Hab 2:2-5 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA dá mi lóhùn, ó ní: “Kọ ìran yìí sílẹ̀; kọ ọ́ sórí tabili kí ó hàn ketekete, kí ó lè rọrùn fún ẹni tí ń sáré lọ láti kà á. Kọ ọ́ sílẹ̀, nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni; ọjọ́ náà kò ní pẹ́ dé, ohun tí o rí kì í ṣe irọ́, dájúdájú yóo ṣẹ. Bí ó bá dàbí ẹni pé ó ń pẹ́, ìwọ ṣá dúró kí o máa retí rẹ̀, dájúdájú, yóo ṣẹ, láìpẹ́. Wò ó! Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò ṣe déédéé ninu OLUWA yóo ṣègbé; ṣugbọn olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.” Ọrọ̀ a máa tan eniyan jẹ; onigbeeraga kò sì ní wà láàyè pẹ́. Ojúkòkòrò rẹ̀ dàbí isà òkú; nǹkan kì í sì í tó o, àfi bí ikú. Ó gbá gbogbo orílẹ̀-èdè jọ fún ara rẹ̀, ó sì sọ gbogbo eniyan di ti ara rẹ̀.
Hab 2:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA dáhùn pé: “Kọ ìṣípayá náà sílẹ̀ kí o sì fi hàn ketekete lórí wàláà kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré. Nítorí ìṣípayá náà jẹ́ tí ìgbà kan tí a múra sílẹ̀ dè; yóò máa yára sí ìgbẹ̀yìn kí yóò sìsọ èké. Bí o tilẹ̀ lọ́ra, dúró dè é; nítorí, dájúdájú, yóò dé, kí yóò sí pẹ́.” “Kíyèsi, ọkàn rẹ tí ó gbéga; Ìfẹ́ rẹ̀ kò dúró ṣinṣin nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n olódodo yóò wa nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lú, nítorí tí ọtí wáìnì ni ẹ̀tàn, agbéraga ènìyàn òun, kò sì ní sinmi ẹni tí ó sọ ìwọra rẹ di gbígbòòrò bí isà òkú, ó sì dàbí ikú, a kò sì le tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ sí ọ̀dọ̀ ó sì gba gbogbo ènìyàn jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.