Hab 2

2
Ìdáhùn OLUWA sí Habakuku
1LORI ibuṣọ́ mi li emi o duro, emi o si gbe ara mi kà ori alore, emi o si ṣọ lati ri ohun ti yio sọ fun mi, ati èsi ti emi o fọ́, nigbati a ba mba mi wi.
2Oluwa si da mi lohùn, o si wipe, Kọ iran na, ki o si hàn a lara wàlã, ki ẹniti nkà a, le ma sare.
3Nitori iran na jẹ ti igbà kan ti a yàn, yio ma yára si igbẹhìn, kì yio si ṣeke, bi o tilẹ̀ pẹ, duro dè e, nitori ni dide, yio de, kì yio pẹ.
4Kiyesi i, ọkàn rẹ̀ ti o gbega, kò duro ṣinṣin ninu rẹ̀: ṣugbọn olododo yio wà nipa ìgbagbọ́ rẹ̀.
Ìjìyà Àwọn Alaiṣododo
5Bẹ̃ni pẹlu, nitoriti ọti-waini li ẹtàn, agberaga enia li on, kì isi simi, ẹniti o sọ ifẹ rẹ̀ di gbigbõrò bi ipò-okú, o si dabi ikú, a kò si lè tẹ́ ẹ lọrun, ṣugbọn o kó gbogbo orilẹ-ède jọ si ọdọ, o si gbá gbogbo enia jọ si ọdọ rẹ̀:
6Gbogbo awọn wọnyi kì yio ma pa owe si i, ti nwọn o si ma kọ orin owe si i, wipe, Egbe ni fun ẹniti nmu ohun ti kì iṣe tirẹ̀ pọ̀ si i! yio ti pẹ to? ati fun ẹniti ndi ẹrẹ̀ ilọnilọwọgbà ru ara rẹ̀.
7Awọn ti o yọ ọ lẹnu, kì yio ha dide lojiji? awọn ti o wahalà rẹ kì yio ha ji? iwọ kì yio ha si di ikogun fun wọn?
8Nitori iwọ ti kó orilẹ-ède pupọ̀, gbogbo iyokù awọn enia na ni yio kó ọ; nitori ẹjẹ̀ enia, ati ìwa-ipá ilẹ na, ti ilu na, ati ti gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.
9Egbe ni fun ẹniti njẹ erè ijẹkujẹ si ile rẹ̀, ki o lè ba gbe itẹ́ rẹ̀ ka ibi giga, ki a lè ba gbà a silẹ kuro lọwọ ibi!
10Iwọ ti gbìmọ itìju si ile rẹ, nipa kike enia pupọ̀ kuro, o si ti ṣẹ̀ si ọkàn rẹ.
11Nitoriti okuta yio kigbe lati inu ogiri wá, ati igi-idábu lati inu òpo wá yio si da a lohùn.
12Egbe ni fun ẹniti o fi ẹjẹ̀ kọ ilu, ti o si fi aiṣedede tẹ̀ ilu nla do.
13Kiyesi i, ti Oluwa awọn ọmọ-ogun kọ́ pe, ki awọn enia na ma ṣe lãla fun iná, ati ki awọn enia na si ma ṣe ara wọn li ãrẹ̀ fun asan?
14Nitoriti aiye yio kún fun ìmọ ogo Oluwa, bi omi ti bò okun.
15Egbe ni fun ẹniti o fi ohun mimu fun aladugbo rẹ̀, ti o si fi ọti-lile rẹ fun u, ti o si jẹ ki o mu amupara pẹlu, ki iwọ ba le wò ihòho wọn!
16Itìju bò ọ nipò ogo, iwọ mu pẹlu, ki abẹ́ rẹ le hàn, ago ọwọ́ ọtun Oluwa ni a o yipadà si ọ, ati itọ́ itìju sára ogo rẹ.
17Nitori ti ìwa-ipá ti Lebanoni yio bò ọ, ati ikogun awọn ẹranko, ti o bà wọn li ẹ̀ru, nitori ẹjẹ̀ enia, ati ìwa ipá ilẹ na, ti ilu na, ati ti gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.
18Erè kini ere fínfin nì, ti oniṣọna rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ; ere didà, ati olùkọ eké, ti ẹniti nṣe iṣẹ rẹ̀ fi gbẹkẹ̀le e, lati ma ṣe ere ti o yadi?
19Egbe ni fun ẹniti o wi fun igi pe, Ji; fun okuta ti o yadi pe, Dide, on o kọ́ ni! Kiyesi i, wurà ati fàdakà li a fi bò o yika, kò si si ẽmi kan ninu rẹ̀.
20Ṣugbọn Oluwa mbẹ ninu tempili rẹ̀ mimọ́; jẹ ki gbogbo aiye pa rọ́rọ niwaju rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Hab 2: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa