Hab 2:18-20
Hab 2:18-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Erè kini ere fínfin nì, ti oniṣọna rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ; ere didà, ati olùkọ eké, ti ẹniti nṣe iṣẹ rẹ̀ fi gbẹkẹ̀le e, lati ma ṣe ere ti o yadi? Egbe ni fun ẹniti o wi fun igi pe, Ji; fun okuta ti o yadi pe, Dide, on o kọ́ ni! Kiyesi i, wurà ati fàdakà li a fi bò o yika, kò si si ẽmi kan ninu rẹ̀. Ṣugbọn Oluwa mbẹ ninu tempili rẹ̀ mimọ́; jẹ ki gbogbo aiye pa rọ́rọ niwaju rẹ̀.
Hab 2:18-20 Yoruba Bible (YCE)
Èrè kí ni ó wà ninu ère? Ère irin lásánlàsàn, tí eniyan ṣe, tí ń kọ́ni ní irọ́ pípa. Nítorí ẹni tí ó ṣe wọ́n gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ère tí ó gbẹ́ tán tí kò lè sọ̀rọ̀! Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún ohun tí a fi igi gbẹ́, pé kí ó dìde; ẹ̀yin tí ẹ̀ ń sọ fún òkúta tí kò lè sọ̀rọ̀, pé kí ó gbéra nílẹ̀. Ǹjẹ́ eléyìí lè rí ìran kankan? Wò ó! Wúrà ati fadaka ni wọ́n yọ́ lé e, kò sì ní èémí ninu rárá. Ṣugbọn OLUWA ń bẹ ninu tẹmpili mímọ́ rẹ̀, kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ̀.
Hab 2:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ, ère dídá ti ń kọ ni èké? Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnrarẹ̀ dá; ó sì mọ ère tí kò le fọhùn. Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘di alààyè?’ Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde’ Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà? Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yíká; kò sì sí èémí kan nínú rẹ.” Ṣùgbọ́n OLúWA wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; Ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.