Gẹn 41:17-57

Gẹn 41:17-57 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Ní inú àlá mi, mo dúró ni etí bèbè odò Naili, sì kíyèsi i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀. Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógó, wọn kò sì lẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ tí n kò tí ì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Ejibiti. Àwọn màlúù tí ó rù tí kò sì lẹ́wà sì jẹ àwọn màlúù tí ó sanra tí ó kọ́ jáde nínú odò. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ́ wọ́n tan, kò sì ẹni tí ó le mọ̀ pé wọ́n jẹ ohunkóhun, nítorí wọn kò sanra sí i, wọn sì bùrẹ́wà síbẹ̀. Nígbà náà ni mo tají. “Ní ojú àlá mi, mo tún rí síírí ọkà méje tí ó yó ọmọ tí ó sì dára, wọ́n jáde láti ara igi ọkà kan. Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán. Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì. Mo sọ àlá yìí fún àwọn onídán mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le túmọ̀ rẹ̀ fún mi.” Nígbà náà ni Josẹfu wí fún Farao, “Ìtumọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Farao. Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, síírí ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni. Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni síírí ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ dànù tan: Wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú. “Bí mo ti wí fún Farao ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Farao. Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ̀ yanturu ń bọ̀ wà ní Ejibiti. Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú ń bọ̀, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé gbogbo ọ̀pọ̀ ní ilẹ̀ Ejibiti, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà, A kò ní rántí àsìkò ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu náà mọ́ nítorí pé ìyàn tí yóò tẹ̀lé e yóò pọ̀ púpọ̀. Ìdí tí Ọlọ́run fi fi àlá náà han fún Farao ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pé, Ọlọ́run ti pinnu pé yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ dandan, àti pé kò ni pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi ṣe é. “Ìmọ̀ràn mi ni wí pé, jẹ́ kí Farao wá ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ó sì fi ṣe alákòóso iṣẹ́ àgbẹ̀ ilẹ̀ Ejibiti. Kí Farao sì yan àwọn alábojútó láti máa gba ìdámárùn-ún ìkórè oko ilẹ̀ Ejibiti ní àsìkò ọdún méje ọ̀pọ̀. Kí wọn kó gbogbo oúnjẹ ilẹ̀ náà ni àwọn ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, kí wọn sì kó àwọn ọkà tí wọn jẹ ṣẹ́kù pamọ́ lábẹ́ àṣẹ Farao. Kí a kó wọn pamọ́ ni àwọn ìlú fún jíjẹ. Kí wọn kó oúnjẹ náà pamọ́ fún orílẹ̀-èdè yìí, kí a ba à le lò ó ni ọdún méje tí ìyàn yóò fi jà ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ìyàn náà má ba à pa orílẹ̀-èdè yìí run.” Èrò náà sì dára lójú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Farao sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ a le rí ẹnikẹ́ni bi ọkùnrin yìí, nínú ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé?” Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu, “Níwọ́n bí Ọlọ́run ti fi gbogbo èyí hàn ọ́, kò sí ẹni náà tí ó gbọ́n tí ó sì mọ̀ràn bí i tìrẹ ní ilẹ̀ Ejibiti yìí, ìwọ yóò ṣe àkóso ààfin mi gbogbo àwọn ènìyàn gbọdọ̀ tẹríba fún àṣẹ ẹ̀ rẹ. Ìtẹ́ mi nìkan ni èmi yóò fi jù ọ́ lọ.” Farao wí fún Josẹfu pé, “Mo fi ọ́ ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.” Farao sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Josẹfu ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn. Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́-ẹṣin bí igbákejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà.” Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Èmi ni Farao. Ṣùgbọ́n láìsí àṣẹ rẹ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun ní ilẹ̀ Ejibiti.” Farao sì sọ Josẹfu ní orúkọ yìí: Safenati-Panea èyí tí ó túmọ̀ sí, (ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà), Ó sì fun un ní Asenati ọmọ Potifẹra, alábojútó òrìṣà Oni, gẹ́gẹ́ bí aya. Josẹfu sì rin gbogbo ilẹ̀ Ejibiti já. Ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni Josẹfu nígbà tí ó wọ iṣẹ́ Farao ọba Ejibiti. Josẹfu sì jáde kúrò níwájú Farao, ó sì ṣe ìbẹ̀wò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ejibiti Ní ọdún méje ọ̀pọ̀, ilẹ̀ náà so èso lọ́pọ̀lọpọ̀. Josẹfu kó gbogbo oúnjẹ tí a pèsè ni ilẹ̀ Ejibiti ní ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, ó sì pa wọ́n mọ́ sí àwọn ìlú. Ní ìlú kọ̀ọ̀kan ni ó kó gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbìn ní àyíká ìlú wọn sí. Josẹfu pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà mọ́ bí iyanrìn Òkun; ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò ṣe àkọsílẹ̀ mọ́ nítorí, ó tayọ kíkà. Kí ó tó di pé ọdún ìyàn dé, Asenati ọmọ Potifẹra alábojútó Oni bí ọmọkùnrin méjì fún Josẹfu. Josẹfu sọ orúkọ àkọ́bí rẹ̀ ni Manase, ó sì wí pé, “Nítorí tí Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìdààmú mi àti gbogbo ilé baba mi.” Ó sì sọ orúkọ èkejì ní Efraimu, ó sì wí pé, “Nítorí pé Ọlọ́run fún mi ní ọmọ ní ilẹ̀ ìpọ́njú mi.” Ọdún méje ọ̀pọ̀ oúnjẹ sì wá sí òpin ní ilẹ̀ Ejibiti, Ọdún méje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀, bí Josẹfu ti wí gan an. Ìyàn sì mú ní gbogbo ilẹ̀ tókù, ṣùgbọ́n oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí àwọn ará Ejibiti bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ipá ìyàn náà, wọ́n kígbe sí Farao. Nígbà náà ni Farao wí fún wọn pé, “Ẹ lọ bá Josẹfu, ẹ ṣe ohun tí ó bá wí fún un yín.” Nígbà tí ìyàn sì ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà, Josẹfu ṣí inú àká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ìyàn náà mú gan an ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè sì ń wá sí Ejibiti láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Josẹfu, nítorí ìyàn náà pọ̀ gidigidi káàkiri gbogbo ayé.

Gẹn 41:17-57 Bibeli Mimọ (YBCV)

Farao si wi fun Josefu pe, Li oju-alá mi, kiyesi i, emi duro lori bèbe odò. Si kiyesi i, abo-malu meje ti o sanra, ti o si dara lati wò, jade lati inu odò na wa; nwọn si njẹ ni ẽsu-odò: Si kiyesi i, abo-malu meje miran ti o joro, ti o burujù ni wiwò, ti o si rù, jade soke lẹhin wọn, nwọn buru tobẹ̃ ti emi kò ri irú wọn rí ni ilẹ Egipti. Awọn abo-malu ti o rù, ti nwọn si buru ni wiwò, nwọn mú awọn abo-malu meje sisanra iṣaju wọnni jẹ: Nigbati nwọn si jẹ wọn tán, a kò le mọ̀ pe, nwọn ti jẹ wọn: nwọn si buru ni wiwò sibẹ̀ gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Bẹ̃ni mo jí. Mo si ri li oju-alá mi, si kiyesi i, ṣiri ọkà meje jade lara igi ọkà kan, o kún o si dara: Si kiyesi i, ṣiri ọkà meje rirẹ̀, ti o si fori, ati ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu, o rú jade lẹhin wọn: Awọn ṣiri ti o fori si mú awọn ṣiri rere meje nì jẹ; mo si rọ́ ọ fun awọn amoye; ṣugbọn kò sí ẹniti o le sọ ọ fun mi. Josefu si wi fun Farao pe, Ọkan li alá Farao: Ọlọrun ti fi ohun ti on mbọ̀wá iṣe hàn fun Farao. Awọn abo-malu daradara meje nì, ọdún meje ni: ati ṣiri daradara meje nì, ọdún meje ni: ọkan li alá na. Ati awọn abo-malu meje nì ti o rù ti o si buru ni wiwò ti nwọn jade soke lẹhin wọn, ọdún meje ni; ati ṣiri ọkà meje ti o fori nì, ti ẹfũfu ìla-õrùn rẹ̀ dànu nì, ọdún meje ìyan ni yio jasi. Eyi li ohun ti mo ti wi fun Farao pe, ohun ti Ọlọrun mbọ̀wá iṣe, o ti fihàn fun Farao. Kiyesi i, ọdún meje ọ̀pọ mbọ̀ já gbogbo ilẹ Egipti: Lẹhin wọn ọdún meje ìyan si mbọ̀; gbogbo ọ̀pọ nì li a o si gbagbe ni ilẹ Egipti; ìyan na yio si run ilẹ; A ki yio si mọ̀ ọ̀pọ na mọ́ ni ilẹ nitori ìyan na ti yio tẹle e, nitori yio mú gidigidi. Nitorina li alá na ṣe dìlu ni meji fun Farao; nitoripe lati ọdọ Ọlọrun li a ti fi idi ọ̀ran na mulẹ, Ọlọrun yio si mú u ṣẹ kánkan. Njẹ nisisiyi, ki Farao ki o wò amoye ati ọlọgbọ́n ọkunrin kan, ki o si fi i ṣe olori ilẹ Egipti. Ki Farao ki o ṣe eyi, ki o si yàn awọn alabojuto si ilẹ yi, ki nwọn ki o si gbà idamarun ni ilẹ Egipti li ọdún meje ọ̀pọ nì. Ki nwọn ki o si kó gbogbo onjẹ ọdún meje rere nì ti o dé, ki nwọn ki o si tò ọkà jọ si ọwọ́ Farao, ki nwọn ki o si pa onjẹ mọ́ ni ilu wọnni. Onjẹ na ni yio si ṣe isigbẹ fun ilẹ dè ọdún meje ìyan na, ti mbọ̀wá si ilẹ Egipti; ki ilẹ ki o má ba run nitori ìyan na. Ohun na si dara li oju Farao, ati li oju gbogbo awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀. Farao si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, A ha le ri ẹnikan bi irú eyi, ọkunrin ti Ẹmi Ọlọrun mbẹ ninu rẹ̀? Farao si wi fun Josefu pe, Niwọnbi Ọlọrun ti fi gbogbo nkan yi hàn ọ, kò sí ẹniti o ṣe amoye ati ọlọgbọ́n bi iwọ: Iwọ ni yio ṣe olori ile mi, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ li a o si ma ṣe akoso awọn enia mi: itẹ́ li emi o fi tobi jù ọ lọ: Farao si wi fun Josefu pe, Wò o, emi fi ọ jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti. Farao si bọ́ oruka ọwọ́ rẹ̀ kuro, o si fi bọ̀ Josefu li ọwọ́, o si wọ̀ ọ li aṣọ ọ̀gbọ daradara, o si fi ẹ̀wọn wurà si i li ọrùn; O si mu u gùn kẹkẹ́ keji ti o ní; nwọn si nké niwaju rẹ̀ pe, Kabiyesi: o si fi i jẹ́ olori gbogbo ilẹ Egipti. Farao si wi fun Josefu pe, Emi ni Farao, lẹhin rẹ ẹnikẹni kò gbọdọ gbé ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ soke ni gbogbo ilẹ Egipti. Farao si sọ orukọ Josefu ni Safnati-paanea; o si fi Asenati fun u li aya, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si jade lọ si ori ilẹ Egipti. Josefu si jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún nigbati o duro niwaju Farao ọba Egipti. Josefu si jade kuro niwaju Farao, o si là gbogbo ilẹ Egipti já. Li ọdún meje ọ̀pọ nì, ilẹ si so eso ni ikunwọ-ikunwọ. O si kó gbogbo onjẹ ọdún meje nì jọ, ti o wà ni ilẹ Egipti, o si fi onjẹ na ṣura ni ilu wọnni: onjẹ oko ilu ti o yi i ká, on li o kójọ sinu rẹ̀. Josefu si kó ọkà jọ bi iyanrin okun lọ̀pọlọpọ; titi o fi dẹkun ati mã ṣirò; nitori ti kò ní iye. A si bí ọmọkunrin meji fun Josefu, ki ọdún ìyan na ki o to dé, ti Asenati bí fun u, ọmọbinrin Potifera, alufa Oni. Josefu si sọ orukọ akọ́bi ni Manasse: wipe, Nitori ti Ọlọrun mu mi gbagbe gbogbo iṣẹ́ mi, ati gbogbo ile baba mi. Orukọ ekeji li o si sọ ni Efraimu: nitori Ọlọrun ti mu mi bisi i ni ilẹ ipọnju mi. Ọdún meje ọ̀pọ na ti o wà ni ilẹ Egipti si pari. Ọdún meje ìyan si bẹ̀rẹ si dé, gẹgẹ bi Josefu ti wi: ìyan na si mú ni ilẹ gbogbo; ṣugbọn ni gbogbo ilẹ Egipti li onjẹ gbé wà. Nigbati ìyan mú ni gbogbo ilẹ Egipti, awọn enia kigbe onjẹ tọ̀ Farao: Farao si wi fun gbogbo awọn ara Egipti pe, Ẹ ma tọ̀ Josefu lọ; ohunkohun ti o ba wi fun nyin ki ẹ ṣe. Ìyan na si wà lori ilẹ gbogbo: Josefu si ṣí gbogbo ile iṣura silẹ, o si ntà fun awọn ara Egipti; ìyan na si nmú si i ni ilẹ Egipti. Ilẹ gbogbo li o si wá si Egipti lati rà onjẹ lọdọ Josefu; nitori ti ìyan na mú gidigidi ni ilẹ gbogbo.

Gẹn 41:17-57 Yoruba Bible (YCE)

Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó, lójú àlá, bí mo ti dúró létí bèbè odò Naili, mo rí i tí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọn sì ń dán, ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò. Àwọn mààlúù meje mìíràn tún jáde láti inú odò náà, gbogbo wọn rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, n kò rí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Àwọn mààlúù tí wọ́n rù wọnyi gbé àwọn tí wọ́n sanra mì. Nígbà tí wọ́n gbé wọn mì tán, eniyan kò lè mọ̀ rárá pé wọ́n jẹ ohunkohun, nítorí pé wọ́n tún rù hangangan bákan náà ni. Mo bá tají. Mo tún lá àlá lẹẹkeji, mo rí ṣiiri ọkà meje lórí igi ọkà kan, wọ́n tóbi, wọ́n sì yọmọ. Mo tún rí i tí ṣiiri ọkà meje mìíràn yọ lẹ́yìn wọn, wọ́n tínínrín, wọn kò sì ní ọmọ ninu rárá, nítorí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ wọn lára. Àwọn ṣiiri ọkà tí kò níláárí wọnyi gbé àwọn tí wọ́n dára mì. Mo rọ́ àwọn àlá mi fún àwọn adáhunṣe, ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó lè túmọ̀ wọn fún mi.” Josẹfu sọ fún Farao, ó ní, “Ọ̀kan náà ni àlá mejeeji, Ọlọrun fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi ni. Àwọn mààlúù rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ meje nnì ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí wọ́n yọmọ dúró fún ọdún meje. Ọ̀kan náà ni àwọn àlá mejeeji. Àwọn mààlúù meje tí wọ́n rù, tí wọ́n sì rí jàpàlà jàpàlà tí wọ́n jáde lẹ́yìn àwọn ti àkọ́kọ́, ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí kò yọmọ, tí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ lára, àwọn náà dúró fún ìyàn ọdún meje. Bí ọ̀rọ̀ ti rí gan-an ni mo sọ fún kabiyesi yìí, Ọlọrun ti fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi. Ọdún meje kan ń bọ̀ tí oúnjẹ yóo pọ̀ yanturu ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn lẹ́yìn náà ìyàn yóo mú fún ọdún meje, ìyàn náà yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọdún meje tí oúnjẹ pọ̀ yóo di ìgbàgbé ní ilẹ̀ Ijipti, ìyàn náà yóo run ilẹ̀ yìí. Ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀ pé oúnjẹ ti fi ìgbà kan pọ̀ rí, nítorí ìyàn ńlá tí yóo tẹ̀lé e yóo burú jáì. Ìdí tí àlá kabiyesi náà fi jẹ́ meji ni láti fihàn pé Ọlọrun ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, láìpẹ́, Ọlọrun yóo mú un ṣẹ. “Bí ọ̀rọ̀ ti rí yìí, ó yẹ kí kabiyesi yan ọkunrin kan tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye, kí ó fi ṣe olórí ní ilẹ̀ Ijipti. Kí kabiyesi yan àwọn alabojuto ní ilẹ̀ náà kí wọ́n kó ìdámárùn-ún ìkórè ilẹ̀ Ijipti jọ láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ yóo fi wà. Kí wọ́n kó gbogbo oúnjẹ wọnyi jọ ninu ọdún tí oúnjẹ yóo pọ̀, kí wọ́n sì kó wọn pamọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá, pẹlu àṣẹ kabiyesi, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ọ. Oúnjẹ yìí ni àwọn eniyan yóo máa jẹ láàrin ọdún meje tí ìyàn yóo mú ní ilẹ̀ Ijipti, kí ilẹ̀ náà má baà parun ní àkókò ìyàn náà.” Ìmọ̀ràn náà dára lójú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ó bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ a lè rí irú ọkunrin yìí, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀?” Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìwọ ni Ọlọrun fi gbogbo nǹkan yìí hàn, kò sí ẹni tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye bíi rẹ. Ìwọ ni yóo máa ṣe olórí ilé mi, gbogbo àṣẹ tí o bá sì pa ni àwọn eniyan mi yóo tẹ̀lé, kìkì pé mo jẹ́ ọba nìkan ni n óo fi jù ọ́ lọ.” Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó! Mo fi ọ́ ṣe alákòóso ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.” Farao bá bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó fi bọ Josẹfu lọ́wọ́, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun olówó iyebíye, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. Farao ní kí Josẹfu gun ọkọ̀ ogun rẹ̀ keji gẹ́gẹ́ bí igbákejì ọba, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hó níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà!” Bẹ́ẹ̀ ni Farao ṣe fi Josẹfu ṣe olórí, ní ilẹ̀ Ijipti. Farao tún sọ fún un pé, “Èmi ni Farao, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Ijipti láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i.” Lẹ́yìn náà ó sọ Josẹfu ní orúkọ Ijipti kan, orúkọ náà ni Safenati Panea, ó sì fi Asenati, ọmọ Pọtifera, fún un láti fi ṣe aya. Pọtifera yìí jẹ́ babalóòṣà oriṣa Oni, ní ìlú Heliopolisi. Josẹfu sì lọ káàkiri ilẹ̀ Ijipti. Josẹfu jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lábẹ́ Farao, ọba Ijipti. A máa lọ láti ààfin ọba Farao káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà, ilẹ̀ so èso lọpọlọpọ. Josẹfu bẹ̀rẹ̀ sí kó oúnjẹ jọ fún ọdún meje tí oúnjẹ fi pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ Ijipti, ó ń pa wọ́n mọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n bá rí kójọ ní agbègbè ìlú ńlá kọ̀ọ̀kan, Josẹfu a kó o pamọ́ sinu ìlú ńlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe kó ọkà jọ jantirẹrẹ bíi yanrìn etí òkun. Nígbà tó yá, òun gan-an kò mọ ìwọ̀n ọkà náà mọ́, nítorí pé ó ti pọ̀ kọjá wíwọ̀n. Asenati, ọmọ Pọtifera, babalóòṣà Oni, bí ọkunrin meji fún Josẹfu kí ìyàn tó bẹ̀rẹ̀. Josẹfu sọ ọmọ rẹ̀ kinni ní Manase, ó ní, “Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìnira mi ati ilé baba mi.” Ó sọ ọmọ keji ní Efuraimu, ó ní, “Ọlọrun ti mú mi bí sí i ní ilẹ̀ tí mo ti rí ìpọ́njú.” Nígbà tí ó yá, ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà ní Ijipti dópin. Ọdún meje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti wí, ìyàn mú ní ilẹ̀ gbogbo, ṣugbọn oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí oúnjẹ kò sí mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, àwọn eniyan náà kígbe tọ Farao lọ fún oúnjẹ. Farao sọ fún gbogbo wọn pé, “Ẹ tọ Josẹfu lọ, ohunkohun tí ó bá wí fun yín ni kí ẹ ṣe.” Nígbà tí ìyàn náà tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, Josẹfu ṣí àwọn àká tí wọ́n kó oúnjẹ pamọ́ sí, ó ń ta oúnjẹ fún àwọn ará Ijipti, nítorí ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ náà. Gbogbo ayé ni ó sì ń wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní Ijipti tí wọ́n wá ra oúnjẹ, nítorí pé ìyàn náà mú gidigidi ní gbogbo ayé.