Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó, lójú àlá, bí mo ti dúró létí bèbè odò Naili, mo rí i tí àwọn mààlúù meje kan tí wọ́n sanra rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀, tí ara wọn sì ń dán, ti inú odò náà jáde wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko létí odò. Àwọn mààlúù meje mìíràn tún jáde láti inú odò náà, gbogbo wọn rù hangangan, wọ́n rí jàpàlà jàpàlà, n kò rí irú rẹ̀ rí ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Àwọn mààlúù tí wọ́n rù wọnyi gbé àwọn tí wọ́n sanra mì. Nígbà tí wọ́n gbé wọn mì tán, eniyan kò lè mọ̀ rárá pé wọ́n jẹ ohunkohun, nítorí pé wọ́n tún rù hangangan bákan náà ni. Mo bá tají. Mo tún lá àlá lẹẹkeji, mo rí ṣiiri ọkà meje lórí igi ọkà kan, wọ́n tóbi, wọ́n sì yọmọ. Mo tún rí i tí ṣiiri ọkà meje mìíràn yọ lẹ́yìn wọn, wọ́n tínínrín, wọn kò sì ní ọmọ ninu rárá, nítorí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ wọn lára. Àwọn ṣiiri ọkà tí kò níláárí wọnyi gbé àwọn tí wọ́n dára mì. Mo rọ́ àwọn àlá mi fún àwọn adáhunṣe, ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó lè túmọ̀ wọn fún mi.”
Josẹfu sọ fún Farao, ó ní, “Ọ̀kan náà ni àlá mejeeji, Ọlọrun fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi ni. Àwọn mààlúù rọ̀pọ̀tọ̀ rọ̀pọ̀tọ̀ meje nnì ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí wọ́n yọmọ dúró fún ọdún meje. Ọ̀kan náà ni àwọn àlá mejeeji. Àwọn mààlúù meje tí wọ́n rù, tí wọ́n sì rí jàpàlà jàpàlà tí wọ́n jáde lẹ́yìn àwọn ti àkọ́kọ́, ati àwọn ṣiiri ọkà meje tí kò yọmọ, tí afẹ́fẹ́ ìhà ìlà oòrùn ti pa ọlá mọ́ lára, àwọn náà dúró fún ìyàn ọdún meje. Bí ọ̀rọ̀ ti rí gan-an ni mo sọ fún kabiyesi yìí, Ọlọrun ti fi ohun tí ó fẹ́ ṣe han kabiyesi. Ọdún meje kan ń bọ̀ tí oúnjẹ yóo pọ̀ yanturu ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, ṣugbọn lẹ́yìn náà ìyàn yóo mú fún ọdún meje, ìyàn náà yóo pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọdún meje tí oúnjẹ pọ̀ yóo di ìgbàgbé ní ilẹ̀ Ijipti, ìyàn náà yóo run ilẹ̀ yìí. Ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀ pé oúnjẹ ti fi ìgbà kan pọ̀ rí, nítorí ìyàn ńlá tí yóo tẹ̀lé e yóo burú jáì. Ìdí tí àlá kabiyesi náà fi jẹ́ meji ni láti fihàn pé Ọlọrun ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, láìpẹ́, Ọlọrun yóo mú un ṣẹ.
“Bí ọ̀rọ̀ ti rí yìí, ó yẹ kí kabiyesi yan ọkunrin kan tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye, kí ó fi ṣe olórí ní ilẹ̀ Ijipti. Kí kabiyesi yan àwọn alabojuto ní ilẹ̀ náà kí wọ́n kó ìdámárùn-ún ìkórè ilẹ̀ Ijipti jọ láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ yóo fi wà. Kí wọ́n kó gbogbo oúnjẹ wọnyi jọ ninu ọdún tí oúnjẹ yóo pọ̀, kí wọ́n sì kó wọn pamọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá, pẹlu àṣẹ kabiyesi, kí wọ́n sì máa ṣọ́ ọ. Oúnjẹ yìí ni àwọn eniyan yóo máa jẹ láàrin ọdún meje tí ìyàn yóo mú ní ilẹ̀ Ijipti, kí ilẹ̀ náà má baà parun ní àkókò ìyàn náà.”
Ìmọ̀ràn náà dára lójú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀. Ó bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ a lè rí irú ọkunrin yìí, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀?” Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé ìwọ ni Ọlọrun fi gbogbo nǹkan yìí hàn, kò sí ẹni tí ó gbọ́n, tí ó sì lóye bíi rẹ. Ìwọ ni yóo máa ṣe olórí ilé mi, gbogbo àṣẹ tí o bá sì pa ni àwọn eniyan mi yóo tẹ̀lé, kìkì pé mo jẹ́ ọba nìkan ni n óo fi jù ọ́ lọ.” Farao bá sọ fún Josẹfu pé, “Wò ó! Mo fi ọ́ ṣe alákòóso ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti.” Farao bá bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó fi bọ Josẹfu lọ́wọ́, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun olówó iyebíye, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. Farao ní kí Josẹfu gun ọkọ̀ ogun rẹ̀ keji gẹ́gẹ́ bí igbákejì ọba, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hó níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà!” Bẹ́ẹ̀ ni Farao ṣe fi Josẹfu ṣe olórí, ní ilẹ̀ Ijipti. Farao tún sọ fún un pé, “Èmi ni Farao, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkohun ní ilẹ̀ Ijipti láìjẹ́ pé o fọwọ́ sí i.” Lẹ́yìn náà ó sọ Josẹfu ní orúkọ Ijipti kan, orúkọ náà ni Safenati Panea, ó sì fi Asenati, ọmọ Pọtifera, fún un láti fi ṣe aya. Pọtifera yìí jẹ́ babalóòṣà oriṣa Oni, ní ìlú Heliopolisi. Josẹfu sì lọ káàkiri ilẹ̀ Ijipti.
Josẹfu jẹ́ ọmọ ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lábẹ́ Farao, ọba Ijipti. A máa lọ láti ààfin ọba Farao káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Láàrin ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà, ilẹ̀ so èso lọpọlọpọ. Josẹfu bẹ̀rẹ̀ sí kó oúnjẹ jọ fún ọdún meje tí oúnjẹ fi pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ Ijipti, ó ń pa wọ́n mọ́ sinu àwọn ìlú ńláńlá. Gbogbo oúnjẹ tí wọ́n bá rí kójọ ní agbègbè ìlú ńlá kọ̀ọ̀kan, Josẹfu a kó o pamọ́ sinu ìlú ńlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe kó ọkà jọ jantirẹrẹ bíi yanrìn etí òkun. Nígbà tó yá, òun gan-an kò mọ ìwọ̀n ọkà náà mọ́, nítorí pé ó ti pọ̀ kọjá wíwọ̀n.
Asenati, ọmọ Pọtifera, babalóòṣà Oni, bí ọkunrin meji fún Josẹfu kí ìyàn tó bẹ̀rẹ̀. Josẹfu sọ ọmọ rẹ̀ kinni ní Manase, ó ní, “Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìnira mi ati ilé baba mi.” Ó sọ ọmọ keji ní Efuraimu, ó ní, “Ọlọrun ti mú mi bí sí i ní ilẹ̀ tí mo ti rí ìpọ́njú.”
Nígbà tí ó yá, ọdún meje tí ọ̀pọ̀ oúnjẹ wà ní Ijipti dópin. Ọdún meje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti wí, ìyàn mú ní ilẹ̀ gbogbo, ṣugbọn oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí oúnjẹ kò sí mọ́ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, àwọn eniyan náà kígbe tọ Farao lọ fún oúnjẹ. Farao sọ fún gbogbo wọn pé, “Ẹ tọ Josẹfu lọ, ohunkohun tí ó bá wí fun yín ni kí ẹ ṣe.” Nígbà tí ìyàn náà tàn káàkiri gbogbo ilẹ̀, Josẹfu ṣí àwọn àká tí wọ́n kó oúnjẹ pamọ́ sí, ó ń ta oúnjẹ fún àwọn ará Ijipti, nítorí ìyàn náà mú gidigidi ní ilẹ̀ náà. Gbogbo ayé ni ó sì ń wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní Ijipti tí wọ́n wá ra oúnjẹ, nítorí pé ìyàn náà mú gidigidi ní gbogbo ayé.