Gẹn 34:13-31

Gẹn 34:13-31 Yoruba Bible (YCE)

Ọgbọ́n ẹ̀tàn ni àwọn ọmọ Jakọbu fi dá Ṣekemu ati Hamori, baba rẹ̀ lóhùn, nítorí bíbà tí ó ba Dina, arabinrin wọn jẹ́. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ìtìjú gbáà ni ó jẹ́, pé kí a fi ọmọbinrin wa fún ẹni tí kò kọlà abẹ́, a kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá. Ohun kan ṣoṣo tí ó lè mú kí ọ̀rọ̀ náà ṣeéṣe ni pé kí ẹ̀yin náà dàbí wa, kí gbogbo ọkunrin yín kọlà abẹ́. Nígbà náà ni a óo tó máa fi ọmọ wa fun yín tí àwa náà yóo máa fẹ́ ọmọ yín, a óo máa gbé pọ̀ pẹlu yín, a óo sì di ọ̀kan. Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò gbà láti kọlà abẹ́, a óo mú ọmọbinrin wa, a óo sì máa lọ.” Ọ̀rọ̀ wọn dùn mọ́ Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀ ninu. Ọdọmọkunrin náà kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀, nítorí pé ó fẹ́ràn ọmọbinrin Jakọbu lọpọlọpọ. Ninu gbogbo ìdílé ọmọkunrin yìí, òun ni ó jẹ́ eniyan pataki jùlọ. Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀ bá lọ sí ẹnubodè ìlú, wọ́n sọ fún àwọn ọkunrin ìlú náà pé, “Ìbágbé àwọn eniyan wọnyi tuni lára pupọ, ẹ jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ wa, kí wọ́n máa tà, kí wọ́n máa rà, ilẹ̀ yìí tóbi tó, ó gbà wọ́n. Ẹ jẹ́ kí á máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn, kí àwọn náà sì máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wa. Ohun kan ṣoṣo ni wọ́n ní kí á ṣe kí á lè jọ máa gbé pọ̀, kí á sì di ọ̀kan, wọ́n ní olukuluku ọkunrin wa gbọdọ̀ kọlà abẹ́ gẹ́gẹ́ bíi tiwọn. Ṣebí gbogbo ẹran ọ̀sìn wọn, ati gbogbo ohun ìní wọn ni yóo di tiwa? Ẹ ṣá jẹ́ kí á gbà fún wọn, wọn yóo sì máa bá wa gbé.” Gbogbo àwọn ará ìlú náà gba ohun tí Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wí, gbogbo ọkunrin sì kọlà abẹ́. Ní ọjọ́ kẹta, nígbà tí ará kan wọ́n, meji ninu àwọn ọmọ Jakọbu, Simeoni ati Lefi, arakunrin Dina, mú idà wọn, wọ́n jálu àwọn ará ìlú náà lójijì, wọ́n sì pa gbogbo ọkunrin wọn. Wọ́n fi idà pa Hamori pẹlu, ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Wọ́n mú Dina jáde kúrò ní ilé Ṣekemu, wọ́n sì bá tiwọn lọ. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Jakọbu wá kó gbogbo ohun ìní àwọn ará ìlú náà nítorí pé wọ́n ba arabinrin wọn jẹ́. Wọ́n kó gbogbo aguntan wọn, gbogbo mààlúù wọn, gbogbo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, ati gbogbo ohun tí ó wà nílé ati èyí tí ó wà ninu pápá. Ati gbogbo dúkìá wọn, àwọn ọmọ wọn ati àwọn aya wọn, gbogbo wọn ni wọ́n kó lẹ́rú, wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà ninu ilé wọn pẹlu. Jakọbu sọ fún Simeoni ati Lefi pé, “Irú ìyọnu wo ni ẹ kó mi sí yìí? Ẹ sọ mí di ọ̀tá gbogbo àwọn tí ń gbé ilẹ̀ yìí, láàrin àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Perisi. Àwa nìyí, a kò pọ̀ jù báyìí lọ. Tí wọ́n bá kó ara wọn jọ sí mi, wọn óo run mí tilé-tilé.” Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “Àwa kò lè gbà kí ó ṣe arabinrin wa bí aṣẹ́wó.”

Gẹn 34:13-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn ọmọ Jakọbu sì fi ẹ̀tàn dá Ṣekemu àti Hamori baba rẹ̀ lóhùn, wọ́n sì wí pé, nítorí tí ó ti ba ògo Dina arábìnrin wọn jẹ́. Wọ́n wí fún wọn pé, “Àwa kò le ṣe nǹkan yìí láti fi arábìnrin wa fún aláìkọlà, nítorí àbùkù ni èyí yóò jẹ́ fún wa. Àwa yóò fi ara mọ́ ọn bí ẹ̀yin yóò bá gbà láti dàbí i tiwa, wí pé ẹ̀yin pẹ̀lú yóò kọ gbogbo ọkùnrin yín ní ilà. Nígbà náà ni àwa yóò le máa fún yín ní ọmọ wa, tí àwa náà yóò máa fẹ́ ẹ yín. A ó máa gbé láàrín yín, a ó sì di ara kan pẹ̀lú yín. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá kọ̀ láti kọlà, àwa yóò mú arábìnrin wa, á ó sì máa lọ.” Àbá náà sì dùn mọ́ Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Ọ̀dọ́mọkùnrin náà, ẹni tí ó jẹ́ ẹni iyì jùlọ ní ilé baba rẹ̀, kò jáfara láti ṣe ohun tí wọ́n wí. Nítorí tí ó fẹ́ràn ọmọbìnrin Jakọbu. Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀ sì wá sí ẹnu ibodè ìlú náà wọn sì bá àwọn ará ìlú náà sọ̀rọ̀. Wí pé, “Ìwà àwọn ọkùnrin wọ̀nyí dára, ẹ jẹ́ kí wọn máa gbé ní àárín wa, kí wọn sì máa ṣòwò, ilẹ̀ kúkú wà rẹpẹtẹ tó gba ààyè dáradára. A lè fẹ́ àwọn ọmọ wọ́n, ki wọn sì fẹ́ tiwa pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n kín ní kan ni a lè ṣe kí wọn tó gbà láti gbé pẹ̀lú wa, ìyẹn sì ni pé àwọn ọkùnrin wa yóò kọlà bí i tiwọn Ṣe bí àwọn ẹran wọn àti ẹrú wọn àti àwọn ohun ọ̀sìn wọn ni yóò di tiwa bí a bá lè gbà bẹ́ẹ̀, wọn yóò sì máa gbé ni àárín wa.” Gbogbo àwọn ọkùnrin tí ń jáde ní ẹnu-bodè ìlú náà sì gbọ́ ti Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀. Gbogbo ọkùnrin ìlú náà sì kọlà. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta, nígbà tí gbogbo wọn sì wà nínú ìrora. Àwọn ọmọ Jakọbu méjì, Simeoni àti Lefi tí ó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Dina, sì mú idà wọn pẹ̀lú ìgboyà, wọ́n sì pa gbogbo ọkùnrin ìlú náà. Wọ́n sì fi idà pa Hamori àti Ṣekemu ọmọ rẹ̀, wọ́n mú Dina kúrò ní ilé wọn, wọ́n sì jáde. Àwọn ọmọ Jakọbu sì wọlé àwọn tí a pa, wọ́n sì kó ẹrù ìlú tí a ti ba ògo arábìnrin wọn jẹ́. Wọ́n kó màlúù wọn àti agbo ẹran wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú ìlú àti ní oko. Gbogbo ọrọ̀ wọn, gbogbo obìnrin ìlú àti àwọn ọmọ wẹẹrẹ pátápátá ni wọ́n kó. Wọ́n sì kó gbogbo ohun tí ó wà nínú ilé wọn bí ìkógun. Nígbà náà ni Jakọbu wí fún Simeoni àti Lefi wí pé, “Ẹ̀yin ti kó ìyọnu bá mi nípa sísọ mí di olóòórùn láàrín ará Kenaani àti Peresi, tí ó ń gbé ilẹ̀ yìí. Àwa kò pọ̀, bí wọn bá wá parapọ̀ ṣígun sí wa, gbogbo wa pátápátá ni wọn yóò parun.” Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ó yẹ kí ó ṣe arábìnrin wa bí panṣágà?”

Gẹn 34:13-31 Bibeli Mimọ (YBCV)

Awọn ọmọ Jakobu si fi ẹ̀tan da Ṣekemu ati Hamori baba rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, nitori ti o bà Dina arabinrin wọn jẹ́: Nwọn si wi fun wọn pe, Awa kò le ṣe nkan yi lati fi arabinrin wa fun ẹni alaikọlà, nitori ohun àbuku ni fun wa; Kiki ninu eyi li awa le jẹ fun nyin: bi ẹnyin o ba wà bi awa, pe ki a kọ olukuluku ọkunrin nyin li ilà. Nigbana li awa o fi awọn ọmọbinrin wa fun nyin, awa o si mú awọn ọmọbinrin nyin sọdọ wa; awa o si ma bá nyin gbé, awa o si di enia kanna. Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti wa lati kọlà; njẹ awa o mú ọmọbinrin wa, awa o si ba ti wa lọ. Ọ̀rọ wọn si dún mọ́ Hamori, ati Ṣekemu, ọmọ Hamori. Ọdọmọkunrin na kò si pẹ́ titi lati ṣe nkan na, nitoriti o fẹ́ ọmọbinrin Jakobu; o si li ọlá jù gbogbo ara ile baba rẹ̀ lọ. Ati Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wá si ẹnubode ilu wọn, nwọn si bá awọn ara ilu wọn sọ̀rọ wipe, Awọn ọkunrin wọnyi mbá wa gbé li alafia; nitorina ẹ jẹ ki nwọn ki o ma gbé ilẹ yi, ki nwọn ki o si ma ṣòwo nibẹ̀; kiyesi i, ilẹ sa gbàye tó niwaju wọn; ẹnyin jẹ ki a ma fẹ́ awọn ọmọbinrin wọn li aya, ki awa ki o si ma fi awọn ọmọbinrin wa fun wọn. Kìki ninu eyi li awọn ọkunrin na o ṣe jẹ fun wa, lati ma bá wa gbé, lati di enia kan, bi gbogbo ọkunrin inu wa ba kọlà, gẹgẹ bi nwọn ti kọlà. Tiwa kọ ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ati gbogbo ohunọ̀sin wọn yio ha ṣe? ki a sa jẹ fun wọn nwọn o si ma ba wa joko, Gbogbo awọn ti njade li ẹnubode ilu wọn si fetisi ti Hamori ati ti Ṣekemu ọmọ rẹ̀; a si kọ gbogbo awọn ọkunrin ni ilà, gbogbo ẹniti o nti ẹnubode wọn jade. O si ṣe ni ọjọ́ kẹta, ti ọgbẹ wọn kan, ni awọn ọmọkunrin Jakobu meji si dide, Simeoni ati Lefi, awọn arakunrin Dina, olukuluku nwọn mú idà rẹ̀, nwọn si fi igboyà wọ̀ ilu na, nwọn si pa gbogbo awọn ọkunrin. Nwọn si fi oju idà pa Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀, nwọn si mú Dina jade kuro ni ile Ṣekemu, nwọn si jade lọ. Awọn ọmọ Jakobu si wọle awọn ti a pa, nwọn si kó ilu na lọ, nitori ti nwọn bà arabinrin wọn jẹ́. Nwọn kó agutan wọn, ati akọmalu wọn, ati kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ohun ti o wà ni ilu na, ati eyiti o wà li oko. Ati ọrọ̀ wọn gbogbo, ati gbogbo ọmọ wọn wẹ́rẹ, ati aya wọn ni nwọn dì ni igbekun, nwọn si kó ohun gbogbo ti o wà ninu ile lọ. Jakobu si wi fun Simeoni on Lefi pe, Ẹnyin mu wahalà bá mi niti ẹnyin mu mi di õrun ninu awọn onilẹ, ninu awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi: bi emi kò si ti pọ̀ ni iye, nwọn o kó ara wọn jọ si mi, nwọn o si pa mi: a o si pa mi run, emi ati ile mi. Nwọn si wipe, Ki on ki o ha ṣe si arabinrin wa bi ẹnipe si panṣaga?