Awọn ọmọ Jakobu si fi ẹ̀tan da Ṣekemu ati Hamori baba rẹ̀ lohùn, nwọn si wipe, nitori ti o bà Dina arabinrin wọn jẹ́:
Nwọn si wi fun wọn pe, Awa kò le ṣe nkan yi lati fi arabinrin wa fun ẹni alaikọlà, nitori ohun àbuku ni fun wa;
Kiki ninu eyi li awa le jẹ fun nyin: bi ẹnyin o ba wà bi awa, pe ki a kọ olukuluku ọkunrin nyin li ilà.
Nigbana li awa o fi awọn ọmọbinrin wa fun nyin, awa o si mú awọn ọmọbinrin nyin sọdọ wa; awa o si ma bá nyin gbé, awa o si di enia kanna.
Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbọ́ ti wa lati kọlà; njẹ awa o mú ọmọbinrin wa, awa o si ba ti wa lọ.
Ọ̀rọ wọn si dún mọ́ Hamori, ati Ṣekemu, ọmọ Hamori.
Ọdọmọkunrin na kò si pẹ́ titi lati ṣe nkan na, nitoriti o fẹ́ ọmọbinrin Jakobu; o si li ọlá jù gbogbo ara ile baba rẹ̀ lọ.
Ati Hamori ati Ṣekemu ọmọ rẹ̀ wá si ẹnubode ilu wọn, nwọn si bá awọn ara ilu wọn sọ̀rọ wipe,
Awọn ọkunrin wọnyi mbá wa gbé li alafia; nitorina ẹ jẹ ki nwọn ki o ma gbé ilẹ yi, ki nwọn ki o si ma ṣòwo nibẹ̀; kiyesi i, ilẹ sa gbàye tó niwaju wọn; ẹnyin jẹ ki a ma fẹ́ awọn ọmọbinrin wọn li aya, ki awa ki o si ma fi awọn ọmọbinrin wa fun wọn.
Kìki ninu eyi li awọn ọkunrin na o ṣe jẹ fun wa, lati ma bá wa gbé, lati di enia kan, bi gbogbo ọkunrin inu wa ba kọlà, gẹgẹ bi nwọn ti kọlà.
Tiwa kọ ẹran wọn, ati ẹrù wọn, ati gbogbo ohunọ̀sin wọn yio ha ṣe? ki a sa jẹ fun wọn nwọn o si ma ba wa joko,
Gbogbo awọn ti njade li ẹnubode ilu wọn si fetisi ti Hamori ati ti Ṣekemu ọmọ rẹ̀; a si kọ gbogbo awọn ọkunrin ni ilà, gbogbo ẹniti o nti ẹnubode wọn jade.
O si ṣe ni ọjọ́ kẹta, ti ọgbẹ wọn kan, ni awọn ọmọkunrin Jakobu meji si dide, Simeoni ati Lefi, awọn arakunrin Dina, olukuluku nwọn mú idà rẹ̀, nwọn si fi igboyà wọ̀ ilu na, nwọn si pa gbogbo awọn ọkunrin.
Nwọn si fi oju idà pa Hamori ati Ṣekemu, ọmọ rẹ̀, nwọn si mú Dina jade kuro ni ile Ṣekemu, nwọn si jade lọ.
Awọn ọmọ Jakobu si wọle awọn ti a pa, nwọn si kó ilu na lọ, nitori ti nwọn bà arabinrin wọn jẹ́.
Nwọn kó agutan wọn, ati akọmalu wọn, ati kẹtẹkẹtẹ wọn, ati ohun ti o wà ni ilu na, ati eyiti o wà li oko.
Ati ọrọ̀ wọn gbogbo, ati gbogbo ọmọ wọn wẹ́rẹ, ati aya wọn ni nwọn dì ni igbekun, nwọn si kó ohun gbogbo ti o wà ninu ile lọ.
Jakobu si wi fun Simeoni on Lefi pe, Ẹnyin mu wahalà bá mi niti ẹnyin mu mi di õrun ninu awọn onilẹ, ninu awọn ara Kenaani ati awọn enia Perissi: bi emi kò si ti pọ̀ ni iye, nwọn o kó ara wọn jọ si mi, nwọn o si pa mi: a o si pa mi run, emi ati ile mi.
Nwọn si wipe, Ki on ki o ha ṣe si arabinrin wa bi ẹnipe si panṣaga?