Gẹn 32:22-31

Gẹn 32:22-31 Yoruba Bible (YCE)

Ní òru ọjọ́ náà gan an, ó dìde ó kó àwọn aya rẹ̀ mejeeji, àwọn iranṣẹbinrin mejeeji ati àwọn ọmọ rẹ̀ mọkọọkanla, ó kọjá sí ìhà keji odò Jaboku. Ó kó àwọn ati ohun gbogbo tí ó ní kọjá sí ìhà keji odò. Ó wá ku Jakọbu nìkan, ọkunrin kan bá a wọ ìjàkadì títí di àfẹ̀mọ́jú ọjọ́ keji. Nígbà tí ọkunrin náà rí i pé òun kò lè dá Jakọbu, ó fi ọwọ́ kan kòtò itan rẹ̀, eegun itan Jakọbu bá yẹ̀ níbi tí ó ti ń bá a jìjàkadì. Nígbà náà ni ó wí pé, “Jẹ́ kí n lọ nítorí ilẹ̀ ti ń mọ́” Ṣugbọn Jakọbu kọ̀, ó ní, “N kò ní jẹ́ kí o lọ, àfi bí o bá súre fún mi.” Ọkunrin náà bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Jakọbu dáhùn pé, “Jakọbu ni.” Ọkunrin náà bá dáhùn pé, “A kò ní pè ọ́ ní Jakọbu mọ́, Israẹli ni a óo máa pè ọ́, nítorí pé o ti bá Ọlọrun ati eniyan wọ ìjàkadì, o sì ti ṣẹgun.” Jakọbu bá bẹ̀ ẹ́, ó ní, “Jọ̀wọ́, sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣugbọn ó dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí o fi ń bèèrè orúkọ mi?” Ó bá súre fún Jakọbu níbẹ̀. Nítorí náà ni Jakọbu fi sọ ibẹ̀ ní Penieli, ó ní, “Mo ti rí Ọlọrun lojukooju, sibẹ mo ṣì wà láàyè.” Oòrùn yọ kí ó tó kọjá Penueli, nítorí pé títiro ni ó ń tiro lọ nítorí itan rẹ̀.

Gẹn 32:22-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì dìde ní òru ọjọ́ náà, ó mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá, wọ́n sì kọjá ní ìwọdò Jabbok. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè odò, ó sì rán àwọn ohun ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú. Ó sì ku Jakọbu nìkan, ọkùnrin kan sì bá a ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì. Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.” Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.” Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.” Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.” Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀. Jakọbu sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Penieli pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.” Bí ó sì ti ń kọjá Penieli, oòrùn ràn bá a, ó sì ń tiro nítorí itan rẹ̀.