Gẹnẹsisi 32:22-31

Gẹnẹsisi 32:22-31 YCB

Ó sì dìde ní òru ọjọ́ náà, ó mú àwọn aya rẹ̀ méjèèjì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ méjèèjì, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mọ́kọ̀ọ̀kànlá, wọ́n sì kọjá ní ìwọdò Jabbok. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè odò, ó sì rán àwọn ohun ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú. Ó sì ku Jakọbu nìkan, ọkùnrin kan sì bá a ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì. Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.” Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.” Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.” Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.” Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀. Jakọbu sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Penieli pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.” Bí ó sì ti ń kọjá Penieli, oòrùn ràn bá a, ó sì ń tiro nítorí itan rẹ̀.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Gẹnẹsisi 32:22-31