Esek 36:25-27
Esek 36:25-27 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbana ni emi o fi omi mimọ́ wọ́n nyin, ẹnyin o si mọ́: emi o si wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin nyin ati kuro ninu gbogbo oriṣa nyin. Emi o fi ọkàn titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkàn okuta kuro lara nyin, emi o si fi ọkàn ẹran fun nyin. Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, emi o si mu ki ẹ ma rìn ninu aṣẹ mi, ẹnyin o pa idajọ mi mọ, ẹ o si ma ṣe wọn.
Esek 36:25-27 Yoruba Bible (YCE)
N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín. N óo fun yín ní ọkàn titun, n óo sì fi ẹ̀mí titun si yín ninu. N óo yọ ọkàn tí ó le bí òkúta kúrò, n óo sì fun yín ní ọkàn tí ó rọ̀ bí ẹran ara. N óo fi ẹ̀mí mi si yín ninu, n óo mú kí ẹ máa rìn ní ìlànà mi, kí ẹ sì máa fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́.
Esek 36:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára ẹ̀yin yóò sì mọ́; Èmi yóò sì fọ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà èérí yin gbogbo àti kúrò nínú gbogbo òrìṣà yin. Èmi yóò fún yín ni ọkàn tuntun, èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín; Èmi yóò sì mú ọkàn òkúta kúrò nínú yín, èmi yóò sì fi ọkàn ẹran fún yín. Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, èmi yóò sì mú ki ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ẹ sì fiyèsí àti pa òfin mi mọ́.