ISIKIẸLI 36
36
Ibukun Ọlọrun Lórí Israẹli
1OLUWA ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, fi àsọtẹ́lẹ̀ bá àwọn òkè Israẹli wí. Sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA wí: 2Àwọn ọ̀tá ń yọ̀ yín, wọ́n ń sọ pé, àwọn òkè àtijọ́ ti di ogún àwọn.’
3“Nítorí náà, ó ní kí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé òun OLUWA Ọlọrun ní nítorí pé wọ́n ti sọ ẹ̀yin òkè Israẹli di ahoro, wọ́n sì ja yín gbà lọ́tùn-ún lósì, títí tí ẹ fi di ìkógun fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, àwọn eniyan sì ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní ìsọkúsọ, 4nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí èmi OLUWA wí, kí ẹ̀yin òkè ńláńlá ati ẹ̀yin òkè kéékèèké Israẹli, ẹ̀yin ipa odò ati ẹ̀yin àfonífojì, ẹ̀yin ibi tí ẹ ti di aṣálẹ̀ ati ẹ̀yin ìlú tí ẹ ti di ahoro, ẹ̀yin ìlú tí ẹ di ìjẹ ati yẹ̀yẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yi yín ká.
5“N óo fi ìtara sọ̀rọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù ati gbogbo Edomu, tí wọ́n fi tayọ̀tayọ̀ pẹlu ọkàn ìkórìíra sọ ilẹ̀ mi di ogún wọn, kí wọ́n lè gbà á, kí wọ́n sì pín in mọ́wọ́, nítorí wọ́n rò pé ilẹ̀ mi ti di tiwọn.
6“Nítorí náà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli. Wí fún àwọn òkè ńláńlá ati àwọn òkè kéékèèké, ati àwọn ipa odò ati àwọn àfonífojì, pé èmi OLUWA Ọlọrun ní ìtara ati ìgbónára ni mo fi ń sọ̀rọ̀ nítorí pé ẹ ti jìyà pupọ, ẹ sì ti di ẹni ẹ̀gàn lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. 7Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun, ń ṣe ìbúra pé, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín yóo di ẹni ẹ̀sín. 8Ṣugbọn ẹ̀yin òkè Israẹli, igi óo hù lórí yín, wọn óo sì so èso fún Israẹli, àwọn eniyan mi, nítorí pé wọn kò ní pẹ́ pada wálé. 9Nítorí pé mo wà fun yín, n óo ṣí ojú àánú wò yín, wọn óo dá oko sórí yín, wọn óo sì gbin nǹkan sinu rẹ̀. 10N óo sọ àwọn ọmọ Israẹli tí ń gbé orí yín di pupọ. Àwọn ìlú yóo rí ẹni máa gbé inú wọn, wọn óo sì tún gbogbo ibi tí ó ti wó kọ́. 11N óo sọ eniyan ati ẹran ọ̀sìn di pupọ lórí yín, wọn óo máa bímọlémọ, wọn ó sì di ọ̀kẹ́ àìmọye. N óo mú kí eniyan máa gbé orí yín bí ìgbà àtijọ́, nǹkan ó sì dára fun yín ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA. 12N óo jẹ́ kí àwọn eniyan mi, àní àwọn ọmọ Israẹli, máa rìn bọ̀ lórí yín. Àwọn ni wọn óo ni yín, ẹ óo sì di ogún wọn, ẹ kò ní pa wọ́n lọ́mọ mọ́.
13“Nítorí àwọn eniyan ń wí pé ò ń paniyan, ati pé ò ń run àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ. 14Nítorí náà, o kò ní pa eniyan mọ́, o kò sì ní pa àwọn eniyan rẹ lọ́mọ mọ́, Èmi OLUWA Ọlọrun ni ó sọ bẹ́ẹ̀. 15N kò ní jẹ́ kí o gbọ́ ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan kò ní dójútì ọ́ mọ́, n kò sì ní mú kí orílẹ̀-èdè rẹ kọsẹ̀ mọ́. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Ìgbé-Ayé Titun Israẹli
16OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, 17“Ìwọ ọmọ eniyan, nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń gbé ilẹ̀ wọn, wọ́n fi ìwà burúkú ba ilẹ̀ náà jẹ́. Lójú mi, ìwà wọn dàbí ìríra obinrin tí ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́. 18Mo bá bínú sí wọn gan-an nítorí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà ati oriṣa tí wọ́n fi bà á jẹ́. 19Mo fọ́n wọn ká sáàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, wọ́n sì tú káàkiri orí ilẹ̀ ayé. Ìwà ati ìṣe wọn ni mo fi dá wọn lẹ́jọ́. 20Nígbà tí wọ́n dé orílẹ̀-èdè tí mo fọ́n wọn ká sí, wọ́n bà mí lórúkọ jẹ́, nítorí àwọn eniyan ń sọ nípa wọn pé, ‘Eniyan OLUWA ni àwọn wọnyi, sibẹsibẹ wọ́n kúrò lórí ilẹ̀ OLUWA.’ 21Ṣugbọn mo ní ìtara fún orúkọ mímọ́ mi, tí àwọn ọmọ Israẹli sọ di nǹkan yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà.
22“Nítorí náà, OLUWA ní kí n pe ẹ̀yin, ọmọ Israẹli, kí n sọ fun yín pé, òun OLUWA Ọlọrun ní, Kì í ṣe nítorí tiyín ni mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe, bíkòṣe nítorí orúkọ mímọ́ mi, tí ẹ̀ ń bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ sálọ. 23N óo fihàn bí orúkọ ńlá mi, tí ó ti bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè ti jẹ́ mímọ́ tó, àní orúkọ mi tí ẹ bàjẹ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ wà. Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun, nígbà tí mo bá ti ipasẹ̀ yín fi bí orúkọ mi ti jẹ́ mímọ́ tó hàn wọ́n. 24Nítorí pé n óo ko yín jáde láti inú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, n óo gba yín jọ láti gbogbo ilẹ̀ ayé, n óo sì mu yín pada sórí ilẹ̀ yín. 25N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín. 26N óo fun yín ní ọkàn titun, n óo sì fi ẹ̀mí titun si yín ninu. N óo yọ ọkàn tí ó le bí òkúta kúrò, n óo sì fun yín ní ọkàn tí ó rọ̀ bí ẹran ara. 27N óo fi ẹ̀mí mi si yín ninu, n óo mú kí ẹ máa rìn ní ìlànà mi, kí ẹ sì máa fi tọkàntọkàn pa òfin mi mọ́. 28Ẹ óo sì máa gbé orí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín. Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun yín. 29N óo gbà yín kúrò ninu gbogbo ìwà èérí yín. N óo mú ọkà pọ̀ ní ilé yín, n kò sì ní jẹ́ kí ìyàn mu yín mọ́. 30N óo jẹ́ kí èso igi ati èrè oko pọ̀, tóbẹ́ẹ̀ tí ìtìjú kò ní ba yín láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mọ́ nítorí ìyàn. 31Nígbà náà ni ẹ óo ranti ìrìnkurìn ati ìwà burúkú yín, ara yín óo sì su yín nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ati ìwà ìríra yín. 32Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájú pé kì í ṣe nítorí yín ni n óo fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ojú tì yín, kí ẹ sì dààmú nítorí ìwà yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Èmi OLUWA Ọlọrun, ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” #Isi 11:19-20
33OLUWA Ọlọrun ní, “Ní ọjọ́ tí mo bá wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ yín, n óo jẹ́ kí àwọn eniyan máa gbé inú àwọn ìlú yín, n óo sì mú kí wọ́n tún àwọn ibi tí ó wó lulẹ̀ kọ́. 34A óo dá oko sórí àwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti di igbó, dípò kí ó máa wà ní igbó lójú àwọn tí wọn ń kọjá lọ. 35Wọn yóo wí pé, ‘Ilẹ̀ yìí, tí ó ti jẹ́ igbó nígbà kan rí, ti dàbí ọgbà Edẹni, àwọn eniyan sì ti ń gbé àwọn ìlú tí wọ́n ti wó lulẹ̀, tí wọ́n ti di ahoro, tí wọ́n sì ti run tẹ́lẹ̀; a sì ti mọ odi wọn pada.’ 36Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká yín yóo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi OLUWA ni mo tún àwọn ibùgbé yín tí ó wó lulẹ̀ kọ́, tí mo sì tún gbin nǹkan ọ̀gbìn sí ilẹ̀ yín tí ó di igbó. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe.”
37OLUWA Ọlọrun ní, “Ohun kan tí n óo tún mú kí àwọn ọmọ Israẹli bèèrè lọ́wọ́ mi pé kí n ṣe fún àwọn ni pé kí n máa mú kí àwọn ọmọ wọn pọ̀ sí i bí ọ̀wọ́ aguntan. 38Kí wọn pọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran, àní bí ọ̀wọ́ ẹran ìrúbọ tíí pọ̀ ní Jerusalẹmu ní àkókò àjọ̀dún. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìlú tí a ti wó palẹ̀ yóo kún fún ọ̀pọ̀ eniyan. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ISIKIẸLI 36: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010