Esek 20:1-9

Esek 20:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe ni ọdun keje ni oṣu karun, ni ọjọ kẹwa oṣu, ti awọn kan ninu awọn àgba Israeli wá ibere lọwọ Oluwa, nwọn si joko niwaju mi. Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá, wipe, Ọmọ enia, sọ fun awọn àgba Israeli, si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi: Lati bere lọwọ mi ni ẹ ṣe wá? Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, lọwọ mi kọ́ ẹnyin o bere. Iwọ o ha dá wọn lẹjọ bi, ọmọ enia, iwọ o ha da wọn lẹjọ? jẹ ki wọn mọ̀ ohun-irira baba wọn. Si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ni ọjọ na nigbati mo yàn Israeli, ti mo si gbe ọwọ́ mi soke si iru-ọmọ ile Jakobu, ti mo si sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn ni ilẹ Egipti, nigbati mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, wipe, Emi ni Oluwa Ọlọrun nyin: Ni ọjọ ti mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti si ilẹ ti mo ti wò silẹ fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ. Mo si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ninu nyin gbe irira oju rẹ̀ junù, ẹ má si ṣe fi oriṣa Egipti sọ ara nyin di aimọ́: emi ni Oluwa Ọlọrun nyin. Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si mi, nwọn kò si fẹ fi eti si mi: olukuluku wọn kò gbe ohun-irira oju wọn junù, bẹ̃ni nwọn kò kọ oriṣa Egipti silẹ: nigbana ni mo wipe, emi o da irúnu mi si wọn lori, lati pari ibinu mi si wọn lãrin ilẹ Egipti. Ṣugbọn mo ṣiṣẹ nitori orukọ mi; ki o má bà bajẹ niwaju awọn keferi, lãrin ẹniti nwọn wà, loju ẹniti mo sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn, ni mimu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti.

Esek 20:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ọdún keje tí a ti wà ní ìgbèkùn, àwọn àgbààgbà Israẹli kan wá láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n sì jókòó níwájú mi. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan sọ fún àwọn àgbààgbà Israẹli pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ṣé ẹ wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi ni? Mo fi ara mi búra pé, n kò ní da yín lóhùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ “Ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan ìríra tí àwọn baba wọn ṣe. Kí o sì sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní, ní ọjọ́ tí mo yan Israẹli, mo búra fún àwọn ọmọ Jakọbu, mo fi ara mi hàn fún wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo sì búra fún wọn pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn. Ní ọjọ́ náà, mo búra fún wọn pé n óo yọ wọ́n kúrò ni ilẹ̀ Ijipti, n óo sì mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jùlọ láàrin gbogbo ilẹ̀ ayé. Mo wí fún wọn pé kí olukuluku kọ àwọn nǹkan ẹ̀gbin tí ó gbójú lé sílẹ̀, kí ẹ má sì fi àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti, ba ara yín jẹ́; nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, wọn kò sì gbọ́ tèmi, ẹnìkankan ninu wọn kò mójú kúrò lára àwọn ère tí wọ́n ń bọ tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ àwọn oriṣa Ijipti sílẹ̀. Mo kọ́ rò ó pé kí n bínú sí wọn, kí n sì tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn ní ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ láàrin àwọn eniyan tí wọn ń gbé, lójú àwọn tí mo ti fi ara mi hàn wọ́n ní ilẹ̀ Ijipti, nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò níbẹ̀.

Esek 20:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kẹwàá, oṣù karùn-ún ọdún keje, ní díẹ̀ nínú àwọn àgbàgbà Israẹli wá wádìí lọ́wọ́ OLúWA, wọn jókòó níwájú mi. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, sọ fún àwọn àgbàgbà Israẹli, kì ó sì wí fún wọn pé, ‘Báyìí ní OLúWA Olódùmarè wí: Ṣe ki ẹ lè wádìí lọ́dọ̀ mi ni ẹ ṣe wá? Bí mo ti wà láààyè, ní OLúWA Olódùmarè wí, Èmi kì yóò gbà kí ẹ wádìí lọ́dọ̀ mi.’ “Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí? Ìwọ fẹ́ dájọ́ wọn bí ọmọ ènìyàn? Nítorí náà fi gbogbo ìwà ìríra baba wọn kò wọ́n lójú, kí ó sì sọ fún wọn pé: ‘Báyìí ní OLúWA Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo yàn Israẹli, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ìbúra sí àwọn ọmọ ilé Jakọbu, mo sì fi ara mi hàn wọn ní Ejibiti, mo gbé ọwọ́ mi sókè nínú ẹ̀jẹ́ wí pé, “Èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín.” Ní ọjọ́ náà mo lọ búra fún wọn pé, èmi yóò mú wọn jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti lọ sí ilẹ̀ ti mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, ilẹ̀ tí ó lẹ́wà jùlọ láàrín àwọn ilẹ̀ yòókù. Mo sì wí fún wọn pé, “Kí olúkúlùkù nínú yín gbé ìríra ojú rẹ̀ kúrò, kí ẹ sì má bá sọ ara yín di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn òrìṣà Ejibiti, èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín.” “ ‘Ṣùgbọ́n wọn ṣọ̀tẹ̀ sí mi wọn kò sì gbọ́rọ̀, wọn kò gbé àwòrán ìríra tí wọ́n dojúkọ kúrò níwájú wọn bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si kọ̀ àwọn òrìṣà Ejibiti sílẹ̀, torí náà mo sọ pé èmi yóò tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí, èmi yóò sì jẹ́ kí ìbínú mi sẹ̀ lórí wọn ní ilẹ̀ Ejibiti. Ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mi, mo ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí orúkọ mi bàjẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń gbé láàrín wọn, lójú àwọn ẹni tí mo ti fi ara hàn fún ara Israẹli nípa mímú wọn jáde ní ilẹ̀ Ejibiti.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa