ISIKIẸLI 20:1-9

ISIKIẸLI 20:1-9 YCE

Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ọdún keje tí a ti wà ní ìgbèkùn, àwọn àgbààgbà Israẹli kan wá láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA, wọ́n sì jókòó níwájú mi. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, “Ìwọ ọmọ eniyan sọ fún àwọn àgbààgbà Israẹli pé, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Ṣé ẹ wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi ni? Mo fi ara mi búra pé, n kò ní da yín lóhùn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ “Ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo ṣe ìdájọ́ wọn? Jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn nǹkan ìríra tí àwọn baba wọn ṣe. Kí o sì sọ fún wọn pé èmi OLUWA ní, ní ọjọ́ tí mo yan Israẹli, mo búra fún àwọn ọmọ Jakọbu, mo fi ara mi hàn fún wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo sì búra fún wọn pé èmi ni OLUWA Ọlọrun wọn. Ní ọjọ́ náà, mo búra fún wọn pé n óo yọ wọ́n kúrò ni ilẹ̀ Ijipti, n óo sì mú wọn dé ilẹ̀ tí mo ti wá sílẹ̀ fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, ilẹ̀ tí ó lógo jùlọ láàrin gbogbo ilẹ̀ ayé. Mo wí fún wọn pé kí olukuluku kọ àwọn nǹkan ẹ̀gbin tí ó gbójú lé sílẹ̀, kí ẹ má sì fi àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti, ba ara yín jẹ́; nítorí pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín. Ṣugbọn wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, wọn kò sì gbọ́ tèmi, ẹnìkankan ninu wọn kò mójú kúrò lára àwọn ère tí wọ́n ń bọ tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọ àwọn oriṣa Ijipti sílẹ̀. Mo kọ́ rò ó pé kí n bínú sí wọn, kí n sì tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn ní ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn mo tún ro ti orúkọ mi, nítorí n kò fẹ́ kí wọ́n ba orúkọ mi jẹ́ láàrin àwọn eniyan tí wọn ń gbé, lójú àwọn tí mo ti fi ara mi hàn wọ́n ní ilẹ̀ Ijipti, nígbà tí mo kó wọn jáde kúrò níbẹ̀.