Esek 2:1-10

Esek 2:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, duro li ẹsẹ rẹ, emi o si ba ọ sọ̀rọ. Ẹmi si wọ inu mi, nigbati o ba mi sọ̀rọ o si gbe mi duro li ẹsẹ mi, mo si gbọ́ ẹniti o ba mi sọrọ. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, emi ran ọ si awọn ọmọ Israeli, si ọlọtẹ̀ orilẹ-ède, ti o ti ṣọtẹ si mi: awọn ati baba wọn ti ṣẹ̀ si mi titi di oni oloni. Nitori ọmọ alafojudi ati ọlọkàn lile ni nwọn, Emi rán ọ si wọn; iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi. Ati awọn, bi nwọn o gbọ́, tabi bi nwọn o kọ̀, (nitori ọlọtẹ̀ ile ni nwọn) sibẹ nwọn o mọ̀ pe woli kan ti wà larin wọn. Ati iwọ, ọmọ enia, máṣe bẹ̀ru wọn, bẹ̃ni ki o máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bi ẹgun ọgàn ati oṣuṣu tilẹ pẹlu rẹ, ti iwọ si gbe ãrin akẽkẽ: máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bẹ̃ni ki o máṣe foya wiwò wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọtẹ̀ ile. Iwọ o si sọ ọ̀rọ mi fun wọn, bi nwọn o gbọ́, tabi bi wọn o kọ̀: nitoriti nwọn jẹ ọlọtẹ̀. Ṣugbọn iwọ, ọmọ enia, gbọ́ ohun ti mo sọ fun ọ; Iwọ máṣe jẹ ọlọtẹ̀ bi ọlọtẹ̀ ile nì: ya ẹ̀nu rẹ, ki o si jẹ ohun ti mo fi fun ọ. Nigbati mo wò, si kiye si i, a ran ọwọ́ kan si mi; si kiye si i, iká-iwé kan wà ninu rẹ̀. O si tẹ́ ẹ siwaju mi, a si kọ ọ ninu ati lode: a si kọ ohùn-reré-ẹkun, ati ọ̀fọ, ati egbé.

Esek 2:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ. Èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀.” Bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀, ẹ̀mí sì wọ inú mi ó mú mi dúró lórí ẹsẹ̀ mi, mo sì ń gbọ́ tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó sọ pé, “Ọmọ ènìyàn, mo ń rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, sí ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi; àwọn àti baba ńlá wọn ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi títí di òní olónìí. Àwọn ènìyàn tí mo ń rán ọ sí jẹ́ aláìgbọ́ràn àti ọlọ́kàn líle. Sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí OLúWA Olódùmarè wí’ Bí wọn fetísílẹ̀ tàbí wọn kò fetísílẹ̀—nítorí pé ọlọ̀tẹ̀ ilé ni wọ́n—wọn yóò mọ̀ pé wòlíì kan wà láàrín wọn. Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn, má ṣe bẹ̀rù wọn tàbí ọ̀rọ̀ ẹnu wọn. Má ṣe bẹ̀rù, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òṣùṣú àti ẹ̀gún yí ọ ká, tí o sì ń gbé àárín àwọn àkéekèe. Má ṣe bẹ̀rù ohun tí wọ́n ń sọ tàbí bẹ̀rù wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọlọ̀tẹ̀ ìdílé ni wọ́n. Ìwọ gbọdọ̀ sọ ọ̀rọ̀ mi fún wọn, bí wọ́n gbọ́ bí wọn kọ̀ láti gbọ́ torí pé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. Ṣùgbọ́n ìwọ, ọmọ ènìyàn, gbọ́ ohun tí mo ń sọ fún ọ. Má ṣe ṣọ̀tẹ̀ bí i ti ìdílé ọlọ́tẹ̀; la ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí mo fún ọ.” Mo sì wò, mo sì rí ọwọ́ kan tí a nà sí mi. Ìwé kíká sì wà níbẹ̀, ó sì tú ìwé náà fún mi. Ní ojú àti ẹ̀yìn ìwé náà ni a kọ ìpohùnréré ẹkún, ọ̀fọ̀ àti ègún sí.

Esek 2:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Ó sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, dìde dúró, mo fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.” Bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀, ẹ̀mí OLUWA wọ inú mi, ó gbé mi nàró, mo sì gbọ́ bí ó ti ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó ní, “Ọmọ eniyan, mo rán ọ sí àwọn ọmọ Israẹli, orílẹ̀-èdè àwọn ọlọ̀tẹ̀, àwọn tí wọ́n ń ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Àwọn ati àwọn baba ńlá wọn ṣì tún ń bá mi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí. Aláfojúdi ati olóríkunkun ẹ̀dá ni wọ́n. Mò ń rán ọ sí wọn kí o lè sọ ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun wí fún wọn. Bí wọn bá fẹ́ kí wọn gbọ́, bí wọn sì fẹ́, kí wọn má gbọ́. (Nítorí pé ọlọ̀tẹ̀ kúkú ni wọ́n), ṣugbọn wọn yóo mọ̀ pé Wolii kan ti wà láàrin wọn. “Ṣugbọn ìwọ ọmọ eniyan, má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà ọ́, má sì bẹ̀rù ọ̀rọ̀ tí wọn ń sọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀gún ọ̀gàn ati ẹ̀wọ̀n agogo yí ọ ká, tí o sì jókòó láàrin àwọn àkeekèé, má ṣe bẹ̀rù ohunkohun tí wọn bá wí. Má jẹ́ kí ojú wọn dẹ́rù bà ọ́, nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ ni wọ́n. O óo sọ ohun tí mo bá wí fún wọn, wọn ìbáà gbọ́, wọn ìbáà má gbọ́; nítorí pé ìdílé ọlọ̀tẹ̀ kúkú ni wọ́n. “Ṣugbọn ìwọ, ọmọ eniyan, fetí sí ohun tí mò ń sọ fún ọ. Má dìtẹ̀ bí àwọn ọmọ ìdílé ọlọ̀tẹ̀ wọnyi. La ẹnu rẹ kí o sì jẹ ohun tí n óo fún ọ.” Nígbà tí mo wò, mo rí ọwọ́ tí ẹnìkan nà sí mi, ìwé kan tí a ká sì wà ninu rẹ̀. Ó tẹ́ ìwé náà siwaju mi; mo sì rí i pé wọ́n kọ nǹkan sí i ní àtojú àtẹ̀yìn. Ọ̀rọ̀ ẹkún, ati ọ̀rọ̀ ọ̀fọ̀, ati ègún ni wọ́n kọ sinu rẹ̀.