Esek 2:1-10

Esek 2:1-10 YBCV

O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, duro li ẹsẹ rẹ, emi o si ba ọ sọ̀rọ. Ẹmi si wọ inu mi, nigbati o ba mi sọ̀rọ o si gbe mi duro li ẹsẹ mi, mo si gbọ́ ẹniti o ba mi sọrọ. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, emi ran ọ si awọn ọmọ Israeli, si ọlọtẹ̀ orilẹ-ède, ti o ti ṣọtẹ si mi: awọn ati baba wọn ti ṣẹ̀ si mi titi di oni oloni. Nitori ọmọ alafojudi ati ọlọkàn lile ni nwọn, Emi rán ọ si wọn; iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi. Ati awọn, bi nwọn o gbọ́, tabi bi nwọn o kọ̀, (nitori ọlọtẹ̀ ile ni nwọn) sibẹ nwọn o mọ̀ pe woli kan ti wà larin wọn. Ati iwọ, ọmọ enia, máṣe bẹ̀ru wọn, bẹ̃ni ki o máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bi ẹgun ọgàn ati oṣuṣu tilẹ pẹlu rẹ, ti iwọ si gbe ãrin akẽkẽ: máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bẹ̃ni ki o máṣe foya wiwò wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọtẹ̀ ile. Iwọ o si sọ ọ̀rọ mi fun wọn, bi nwọn o gbọ́, tabi bi wọn o kọ̀: nitoriti nwọn jẹ ọlọtẹ̀. Ṣugbọn iwọ, ọmọ enia, gbọ́ ohun ti mo sọ fun ọ; Iwọ máṣe jẹ ọlọtẹ̀ bi ọlọtẹ̀ ile nì: ya ẹ̀nu rẹ, ki o si jẹ ohun ti mo fi fun ọ. Nigbati mo wò, si kiye si i, a ran ọwọ́ kan si mi; si kiye si i, iká-iwé kan wà ninu rẹ̀. O si tẹ́ ẹ siwaju mi, a si kọ ọ ninu ati lode: a si kọ ohùn-reré-ẹkun, ati ọ̀fọ, ati egbé.