Esek 11:19-20
Esek 11:19-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi o si fun wọn li ọkàn kan, emi o si fi ẹmi titun sinu nyin; emi o si mu ọkàn okuta kuro lara wọn, emi o si fun wọn li ọkàn ẹran: Ki wọn le rìn ninu aṣẹ mi, ki wọn si le pa ilana mi mọ, ki nwọn si ṣe wọn: nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.
Esek 11:19-20 Yoruba Bible (YCE)
Ó ní, mo sọ pé, n óo fún wọn ní ọkàn kan, n óo fi ẹ̀mí titun sí wọn ninu. N óo yọ ọkàn òkúta kúrò láyà wọn, n óo sì fún wọn ní ọkàn ẹran; kí wọ́n lè máa rìn ninu ìlànà mi, kí wọ́n sì lè máa pa òfin mi mọ́. Wọn óo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn.
Esek 11:19-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi yóò fún wọn ní ọ̀kankan; èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú wọn; Èmi yóò mú ọkàn òkúta kúrò lára wọn, èmi yóò sì fún wọn ní ọkàn tó rọ̀ bí ara ẹran. Kí wọn le tẹ̀lé àṣẹ mi, kí wọn sì le pa òfin mi mọ́. Wọ́n yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi náà yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.