Eks 7:1-6
Eks 7:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi fi ọ ṣe ọlọrun fun Farao: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma ṣe wolĩ rẹ. Iwọ o sọ gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ: Aaroni arakunrin rẹ ni yio si ma sọ fun Farao pe, ki o rán awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ rẹ̀. Emi o si mu Farao li àiya le, emi o si sọ iṣẹ-àmi mi ati iṣẹ-iyanu mi di pupọ̀ ni ilẹ Egipti. Ṣugbọn Farao ki yio gbọ́ ti nyin, emi o si fi ọwọ́ mi lé Egipti, emi o si fi idajọ nla mú awọn ogun mi, ani awọn ọmọ Israeli enia mi, jade kuro ni ilẹ Egipti. Awọn ara Egipti yio si mọ̀ pe, emi li OLUWA, nigbati mo ba nà ọwọ́ mi lé Egipti, ti mo si mú awọn ọmọ Israeli jade kuro lãrin wọn. Mose ati Aaroni si ṣe bẹ̃; bi OLUWA ti paṣẹ fun wọn; bẹ̃ni nwọn ṣe.
Eks 7:1-6 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá dá Mose lóhùn pé, “Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ọlọrun fún Farao, Aaroni, arakunrin rẹ ni yóo sì jẹ́ wolii rẹ. Gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ ni kí o sọ; Aaroni, arakunrin rẹ yóo sì sọ fún Farao pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀. Ṣugbọn n óo mú kí ọkàn Farao le, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo fi jẹ́ pé, bí ó ti wù kí iṣẹ́ ìyanu tí n óo ṣe ní ilẹ̀ Ijipti pọ̀ tó, kò ní gbọ́ tìrẹ. Nígbà náà ni n óo nawọ́ ìyà sí Ijipti, n óo sì kó àwọn ọmọ Israẹli, ìjọ eniyan mi, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ ìyanu ati ìdájọ́ ńlá. Àwọn ará Ijipti yóo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA, nígbà tí mo bá nawọ́ ìyà sí Ijipti tí mo sì kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò láàrin wọn.” Mose ati Aaroni bá ṣe bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún wọn.
Eks 7:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose pé, “Wò ó, Èmi ti ṣe ọ bí Ọlọ́run fún Farao, Aaroni arákùnrin rẹ ni yóò jẹ́ wòlíì (agbẹnusọ) rẹ. Ìwọ yóò sì sọ ohun gbogbo tí Èmi ti pàṣẹ fún ọ, Aaroni arákùnrin rẹ yóò sísọ fún Farao kí ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi yóò sé Farao lọ́kàn le. Bí Mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu ni Ejibiti, síbẹ̀ òun kì yóò fi etí sí ọ. Nígbà náà ni Èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé Ejibiti, pẹ̀lú agbára ìdájọ́ ńlá mi ni èmi yóò mú àwọn ènìyàn mi Israẹli jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́. Àwọn ará Ejibiti yóò sì mọ̀ pé Èmi ni OLúWA ní ìgbà tí mo bá na ọwọ́ mi jáde lé Ejibiti, tí mo sì mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò níbẹ̀.” Mose àti Aaroni sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti pàṣẹ fún wọn.