Eks 6:10-13
Eks 6:10-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Mose pe, Wọle, sọ fun Farao ọba Egipti pe, ki o jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ kuro ni ilẹ rẹ̀. Mose si sọ niwaju OLUWA wipe, Kiyesi i, awọn ọmọ Israeli kò gbọ́ ti emi, Farao yio ha ti ṣe gbọ́ ti emi, emi ẹniti iṣe alaikọlà ète? OLUWA si bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ, o si fi aṣẹ fun wọn si awọn ọmọ Israeli, ati si Farao, ọba Egipti, lati mú awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ Egipti.
Eks 6:10-13 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, ọba ilẹ̀ Ijipti, kí o wí fún un pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.” Ṣugbọn Mose dá OLUWA lóhùn pé, “Àwọn eniyan Israẹli gan-an kò gbọ́ tèmi, báwo ni Farao yóo ṣe gbọ́, èmi akólòlò lásánlàsàn.” Ṣugbọn Ọlọrun bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ̀, ó wá pàṣẹ ohun tí wọn yóo sọ fún àwọn eniyan Israẹli ati fún Farao, ọba Ijipti, pé kí ó kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.
Eks 6:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose. “Lọ, sọ fún Farao ọba Ejibiti pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Israẹli lọ kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.” Ṣùgbọ́n Mose sọ fún OLúWA pé, “Nígbà ti àwọn ará Israẹli tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Farao yóò ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?” OLúWA bá ìran Mose àti Aaroni sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Israẹli àti Farao ọba Ejibiti, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.