Eks 6

6
Ọlọrun Pe Mose
1NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Nigbayi ni iwọ o ri ohun ti emi o ṣe si Farao: nitori ọwọ́ agbara li on o ṣe jọwọ wọn lọwọ lọ, ati pẹlu ọwọ́ agbara li on o fi tì wọn jade kuro ni ilẹ rẹ̀.
2Ọlọrun si sọ fun Mose, o si wi fun u pe, Emi ni JEHOFA:
3Emi si farahàn Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, li orukọ Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn orukọ mi JEHOFA, ni nwọn kò fi mọ̀ mi.
4Emi si ti bá wọn da majẹmu mi pẹlu, lati fun wọn ni ilẹ Kenaani, ilẹ atipo wọn, nibiti nwọn gbé ṣe atipo.
5Emi si ti gbọ́ irora awọn ọmọ Israeli pẹlu, ti awọn ara Egipti nmu sìn; emi si ti ranti majẹmu mi.
6Nitorina wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi li OLUWA, emi o si mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti, emi o si yọ nyin kuro li oko-ẹrú wọn, emi o si fi apa ninà ati idajọ nla da nyin ni ìde:
7Emi o si gbà nyin ṣe enia fun ara mi, emi o si jẹ́ Ọlọrun fun nyin: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti.
8Emi o si mú nyin lọ sinu ilẹ na, ti mo ti bura lati fi fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu; emi o si fi i fun nyin ni iní: Emi li OLUWA.
9Mose si sọ bẹ̃ fun awọn ọmọ Israeli: ṣugbọn nwọn kò gbà ti Mose gbọ́ fun ibinujẹ ọkàn, ati fun ìsin lile.
10OLUWA si sọ fun Mose pe,
11Wọle, sọ fun Farao ọba Egipti pe, ki o jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ kuro ni ilẹ rẹ̀.
12Mose si sọ niwaju OLUWA wipe, Kiyesi i, awọn ọmọ Israeli kò gbọ́ ti emi, Farao yio ha ti ṣe gbọ́ ti emi, emi ẹniti iṣe alaikọlà ète?
13OLUWA si bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ, o si fi aṣẹ fun wọn si awọn ọmọ Israeli, ati si Farao, ọba Egipti, lati mú awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ Egipti.
Àkọsílẹ̀ Ìran Mose ati Ti Aaroni
14Wọnyi li olori ile baba wọn: awọn ọmọ Reubeni akọ́bi Israeli; Hanoku, ati Pallu, Hesroni, ati Karmi: wọnyi ni idile Reubeni.
15Ati awọn ọmọ Simeoni; Jemueli, ati Jamini, ati Ohadi, ati Jakini, ati Sohari, ati Ṣaulu ọmọ obinrin ara Kénaani; wọnyi ni idile Simeoni.
16Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Lefi ni iran wọn; Gerṣoni, ati Kohati, ati Merari: ọdún aiye Lefi si jẹ́ mẹtadilogoje.
17Awọn ọmọ Gerṣoni; Libni, ati Ṣimei, ni idile wọn.
18Ati awọn ọmọ Kohati; Amramu ati Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli ọdún aiye Kohati si jẹ́ ãdoje o le mẹta.
19Ati awọn ọmọ Merari; Mahali, ati Muṣi. Wọnyi ni idile Lefi ni iran wọn.
20Amramu si fẹ́ Jokebedi arabinrin baba rẹ̀ li aya, on li o si bi Aaroni ati Mose fun u: ọdún aiye Amramu si jẹ́ mẹtadilogoje.
21Ati awọn ọmọ Ishari; Kora, ati Nefegi, ati Sikri.
22Ati awọn ọmọ Ussieli; Miṣaeli, ati Elsafani, ati Sitri.
23Aaroni si fẹ́ Eliṣeba, ọmọbinrin Aminadabu, arabinrin Naṣoni, li aya; on si bí Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari fun u.
24Ati awọn ọmọ Kora; Assiri, ati Elkana, ati Abiasafu; wọnyi ni idile awọn ọmọ Kora.
25Eleasari ọmọ Aaroni si fẹ́ ọkan ninu awọn ọmọbinrin Putieli li aya; on si bi Finehasi fun u: wọnyi li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi ni idile wọn.
26Wọnyi ni Aaroni on Mose na, ẹniti OLUWA sọ fun pe, Ẹ mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn.
27Awọn wọnyi li o bá Farao ọba Egipti sọ̀rọ lati mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni Egipti: wọnyi ni Mose ati Aaroni na.
Àṣẹ Tí OLUWA Pa fún Mose ati Aaroni
28O si ṣe li ọjọ́ ti OLUWA bá Mose sọ̀rọ ni ilẹ Egipti,
29Ni OLUWA sọ fun Mose wipe, Emi li OLUWA: sọ gbogbo eyiti mo wi fun ọ fun Farao ọba Egipti.
30Mose si wi niwaju OLUWA pe, Kiyesi i, alaikọlà ète li emi, Farao yio ha ti ṣe fetisi ti emi?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Eks 6: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa