Eks 6:1-30

Eks 6:1-30 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Nigbayi ni iwọ o ri ohun ti emi o ṣe si Farao: nitori ọwọ́ agbara li on o ṣe jọwọ wọn lọwọ lọ, ati pẹlu ọwọ́ agbara li on o fi tì wọn jade kuro ni ilẹ rẹ̀. Ọlọrun si sọ fun Mose, o si wi fun u pe, Emi ni JEHOFA: Emi si farahàn Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, li orukọ Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn orukọ mi JEHOFA, ni nwọn kò fi mọ̀ mi. Emi si ti bá wọn da majẹmu mi pẹlu, lati fun wọn ni ilẹ Kenaani, ilẹ atipo wọn, nibiti nwọn gbé ṣe atipo. Emi si ti gbọ́ irora awọn ọmọ Israeli pẹlu, ti awọn ara Egipti nmu sìn; emi si ti ranti majẹmu mi. Nitorina wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi li OLUWA, emi o si mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti, emi o si yọ nyin kuro li oko-ẹrú wọn, emi o si fi apa ninà ati idajọ nla da nyin ni ìde: Emi o si gbà nyin ṣe enia fun ara mi, emi o si jẹ́ Ọlọrun fun nyin: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti. Emi o si mú nyin lọ sinu ilẹ na, ti mo ti bura lati fi fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu; emi o si fi i fun nyin ni iní: Emi li OLUWA. Mose si sọ bẹ̃ fun awọn ọmọ Israeli: ṣugbọn nwọn kò gbà ti Mose gbọ́ fun ibinujẹ ọkàn, ati fun ìsin lile. OLUWA si sọ fun Mose pe, Wọle, sọ fun Farao ọba Egipti pe, ki o jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ kuro ni ilẹ rẹ̀. Mose si sọ niwaju OLUWA wipe, Kiyesi i, awọn ọmọ Israeli kò gbọ́ ti emi, Farao yio ha ti ṣe gbọ́ ti emi, emi ẹniti iṣe alaikọlà ète? OLUWA si bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ, o si fi aṣẹ fun wọn si awọn ọmọ Israeli, ati si Farao, ọba Egipti, lati mú awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ Egipti. Wọnyi li olori ile baba wọn: awọn ọmọ Reubeni akọ́bi Israeli; Hanoku, ati Pallu, Hesroni, ati Karmi: wọnyi ni idile Reubeni. Ati awọn ọmọ Simeoni; Jemueli, ati Jamini, ati Ohadi, ati Jakini, ati Sohari, ati Ṣaulu ọmọ obinrin ara Kénaani; wọnyi ni idile Simeoni. Wọnyi si li orukọ awọn ọmọ Lefi ni iran wọn; Gerṣoni, ati Kohati, ati Merari: ọdún aiye Lefi si jẹ́ mẹtadilogoje. Awọn ọmọ Gerṣoni; Libni, ati Ṣimei, ni idile wọn. Ati awọn ọmọ Kohati; Amramu ati Ishari, ati Hebroni, ati Ussieli ọdún aiye Kohati si jẹ́ ãdoje o le mẹta. Ati awọn ọmọ Merari; Mahali, ati Muṣi. Wọnyi ni idile Lefi ni iran wọn. Amramu si fẹ́ Jokebedi arabinrin baba rẹ̀ li aya, on li o si bi Aaroni ati Mose fun u: ọdún aiye Amramu si jẹ́ mẹtadilogoje. Ati awọn ọmọ Ishari; Kora, ati Nefegi, ati Sikri. Ati awọn ọmọ Ussieli; Miṣaeli, ati Elsafani, ati Sitri. Aaroni si fẹ́ Eliṣeba, ọmọbinrin Aminadabu, arabinrin Naṣoni, li aya; on si bí Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari fun u. Ati awọn ọmọ Kora; Assiri, ati Elkana, ati Abiasafu; wọnyi ni idile awọn ọmọ Kora. Eleasari ọmọ Aaroni si fẹ́ ọkan ninu awọn ọmọbinrin Putieli li aya; on si bi Finehasi fun u: wọnyi li olori awọn baba awọn ọmọ Lefi ni idile wọn. Wọnyi ni Aaroni on Mose na, ẹniti OLUWA sọ fun pe, Ẹ mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn wọnyi li o bá Farao ọba Egipti sọ̀rọ lati mú awọn ọmọ Israeli jade kuro ni Egipti: wọnyi ni Mose ati Aaroni na. O si ṣe li ọjọ́ ti OLUWA bá Mose sọ̀rọ ni ilẹ Egipti, Ni OLUWA sọ fun Mose wipe, Emi li OLUWA: sọ gbogbo eyiti mo wi fun ọ fun Farao ọba Egipti. Mose si wi niwaju OLUWA pe, Kiyesi i, alaikọlà ète li emi, Farao yio ha ti ṣe fetisi ti emi?

Eks 6:1-30 Yoruba Bible (YCE)

Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “O óo rí ohun tí n óo ṣe sí ọba Farao; ó fẹ́, ó kọ̀, yóo jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, fúnra rẹ̀ ni yóo sì fi ipá tì wọ́n jáde.” Ọlọrun tún sọ fún Mose pé, “Èmi ni OLUWA. Mo fara han Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn n kò farahàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA tíí ṣe orúkọ mi gan-an. Mo tún bá wọn dá majẹmu pé n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún wọn, ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò. Mo gbọ́ ìkérora àwọn ọmọ Israẹli tí àwọn ará Ijipti dì ní ìgbèkùn, mo sì ranti majẹmu mi. Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èmi ni OLUWA, n óo yọ yín jáde kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín, n óo yọ yín kúrò ninu ìgbèkùn wọn, ipá ni n óo sì fi rà yín pada pẹlu ìdájọ́ ńlá. N óo mu yín gẹ́gẹ́ bí eniyan mi, n óo jẹ́ Ọlọrun yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó fà yín yọ kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín. N óo sì ko yín wá sí ilẹ̀ tí mo búra láti fún Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; n óo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní, Èmi ni OLUWA.’ ” Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn eniyan Israẹli, ṣugbọn wọn kò fetí sí ohun tí ó ń sọ, nítorí pé ìyà burúkú tí wọn ń jẹ ní oko ẹrú ti jẹ́ kí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, ọba ilẹ̀ Ijipti, kí o wí fún un pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.” Ṣugbọn Mose dá OLUWA lóhùn pé, “Àwọn eniyan Israẹli gan-an kò gbọ́ tèmi, báwo ni Farao yóo ṣe gbọ́, èmi akólòlò lásánlàsàn.” Ṣugbọn Ọlọrun bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ̀, ó wá pàṣẹ ohun tí wọn yóo sọ fún àwọn eniyan Israẹli ati fún Farao, ọba Ijipti, pé kí ó kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Èyí ni àkọsílẹ̀ àwọn olórí olórí ninu ìdílé wọn: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu bí ọmọkunrin mẹrin: Hanoku, Palu, Hesironi ati Karimi; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Reubẹni. Simeoni bí ọmọkunrin mẹfa: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari ati Ṣaulu, tí obinrin ará Kenaani kan bí fún un; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Simeoni. Lefi bí ọmọ mẹta: Geriṣoni, Kohati ati Merari; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi. Ọdún mẹtadinlogoje (137) ni Lefi gbé láyé. Geriṣoni bí ọmọ meji: Libini ati Ṣimei, wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé wọn. Kohati bí ọmọ mẹrin: Amramu, Iṣari, Heburoni ati Usieli. Ọdún mẹtalelaadoje (133) ni Kohati gbé láyé. Merari bí ọmọkunrin meji: Mahili ati Muṣi. Àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi nìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí arọmọdọmọ wọn. Amramu fẹ́ Jokebedi, arabinrin baba rẹ̀. Jokebedi sì bí Aaroni ati Mose fún un. Ọdún mẹtadinlogoje (137) ni Amramu gbé láyé. Iṣari bí ọmọkunrin mẹta: Kora, Nefegi ati Sikiri. Usieli bí ọmọkunrin mẹta: Miṣaeli, Elisafani ati Sitiri. Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbinrin Aminadabu tíí ṣe arabinrin Naṣoni. Àwọn ọmọ tí ó bí fún un nìwọ̀nyí: Nadabu, Abihu, Eleasari, ati Itamari. Kora bí ọmọkunrin mẹta: Asiri, Elikana ati Abiasafu; àwọn ni ìdílé Kora. Eleasari ọmọ Aaroni fẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọmọbinrin Putieli; ó sì bí Finehasi fún un; àwọn ni olórí àwọn ìdílé ẹ̀yà Lefi. Aaroni ati Mose ni OLUWA pè, tí ó sì wí fún pé kí wọ́n kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwọn ni wọ́n sọ fún ọba Ijipti pé kí ó dá àwọn eniyan Israẹli sílẹ̀. Ní ọjọ́ tí OLUWA bá Mose sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ Ijipti, OLUWA sọ fún un pé, “Èmi ni OLUWA, sọ gbogbo ohun tí mo rán ọ fún Farao, ọba Ijipti.” Ṣugbọn Mose dáhùn pé, “OLUWA, akólòlò ni mí; báwo ni ọba Farao yóo ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ mi?”

Eks 6:1-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ní OLúWA sọ fún Mose pé, “Ní ìsin yìí, ìwọ yóò rí ohun tí èmi yóò ṣe sí Farao pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi ni yóò fi jẹ́ kí wọn lọ; pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi, òun yóò lé wọn jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.” Ọlọ́run sì tún sọ fún Mose pé, “Èmi ni OLúWA. Mo fi ara hàn Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu bí Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai) ṣùgbọ́n nípa orúkọ mi OLúWA, Èmi kò fi ara Mi hàn wọ́n. Èmí sì tún fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì. Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli àwọn tí àwọn ará Ejibiti mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mú Mi. “Sọ fún àwọn ará ilé Israẹli: ‘Èmi ni OLúWA, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúrò ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá. Èmi yóò mú un yín bí ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Abrahamu. Isaaki àti Jakọbu. Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, Èmi ni OLúWA.’ ” Mose sì sọ èyí fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n wọn kò fi etí sílẹ̀ sí Mose nítorí ọkàn wọn tó rẹ̀wẹ̀sì àti nítorí ìgbèkùn búburú bí ohun tí ó ti kọ́ sọ kó wọn sí ní oko ẹrú wọn. Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose. “Lọ, sọ fún Farao ọba Ejibiti pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Israẹli lọ kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.” Ṣùgbọ́n Mose sọ fún OLúWA pé, “Nígbà ti àwọn ará Israẹli tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Farao yóò ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?” OLúWA bá ìran Mose àti Aaroni sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Israẹli àti Farao ọba Ejibiti, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti. Wọ̀nyí ni olórí ìran wọn: Àwọn ọmọ Reubeni àkọ́bí Israẹli ni: Hanoku, Pallu, Hesroni àti Karmi. Àwọn wọ̀nyí ni ìdílé Reubeni. Àwọn ọmọ Simeoni ní: Jemueli, Jamini, Ohadi, Jakini, Sohari àti Saulu ọmọ obìnrin Kenaani. Àwọn wọ̀nyí ni ìran Simeoni. Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn: Gerṣoni, Kohati àti Merari. Lefi lo ẹ̀tàndínlógóje (137) ọdún láyé. Àwọn ọmọ Gerṣoni ni ìran wọn ni: Libni àti Ṣimei. Àwọn ọmọ Kohati ni: Amramu, Isari, Hebroni àti Usieli. Kohati lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé. Àwọn ọmọ Merari ni: Mahili àti Muṣi. Ìwọ̀nyí ni ìran Lefi gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn. Amramu sì fẹ́ Jokebedi arábìnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jokebedi sì bí Aaroni àti Mose fún un. Amramu lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé. Àwọn ọmọ Isari ni: Kora, Nefegi àti Sikri. Àwọn ọmọ Usieli ni: Miṣaeli, Elsafani àti Sitiri. Aaroni fẹ́ Eliṣeba ọmọbìnrin Amminadabu tí í ṣe arábìnrin Nahiṣoni, ó sì bí Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari. Àwọn ọmọ Kora ni: Asiri, Elkana àti Abiasafu. Ìwọ̀nyí ni ìran Kora. Eleasari ọmọ Aaroni fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Putieli ní ìyàwó, ó sì bí Finehasi fún un. Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn Lefi ni ìdílé ìdílé. Aaroni àti Mose yìí kan náà ni OLúWA sọ fún pé, “Ẹ kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí.” Àwọn ni ó bá Farao ọba Ejibiti sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni Ejibiti, àní Mose àti Aaroni yìí kan náà ni. Nígbà tí OLúWA bá Mose sọ̀rọ̀ ni Ejibiti, OLúWA sì sọ fún Mose pé, “Èmi ni OLúWA. Sọ ohun gbogbo ti mo ti sọ fún ọ fún Farao ọba Ejibiti.” Ṣùgbọ́n Mose sì wí ní iwájú OLúWA pé, “Níwọ́n ìgbà ti mo jẹ́ akólòlò, ọ̀nà dà ti Farao yóò ṣe fi etí sí mi?”