Eks 6:1-13
Eks 6:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
NIGBANA li OLUWA wi fun Mose pe, Nigbayi ni iwọ o ri ohun ti emi o ṣe si Farao: nitori ọwọ́ agbara li on o ṣe jọwọ wọn lọwọ lọ, ati pẹlu ọwọ́ agbara li on o fi tì wọn jade kuro ni ilẹ rẹ̀. Ọlọrun si sọ fun Mose, o si wi fun u pe, Emi ni JEHOFA: Emi si farahàn Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu, li orukọ Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn orukọ mi JEHOFA, ni nwọn kò fi mọ̀ mi. Emi si ti bá wọn da majẹmu mi pẹlu, lati fun wọn ni ilẹ Kenaani, ilẹ atipo wọn, nibiti nwọn gbé ṣe atipo. Emi si ti gbọ́ irora awọn ọmọ Israeli pẹlu, ti awọn ara Egipti nmu sìn; emi si ti ranti majẹmu mi. Nitorina wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi li OLUWA, emi o si mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti, emi o si yọ nyin kuro li oko-ẹrú wọn, emi o si fi apa ninà ati idajọ nla da nyin ni ìde: Emi o si gbà nyin ṣe enia fun ara mi, emi o si jẹ́ Ọlọrun fun nyin: ẹnyin o si mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade kuro labẹ ẹrù awọn ara Egipti. Emi o si mú nyin lọ sinu ilẹ na, ti mo ti bura lati fi fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu; emi o si fi i fun nyin ni iní: Emi li OLUWA. Mose si sọ bẹ̃ fun awọn ọmọ Israeli: ṣugbọn nwọn kò gbà ti Mose gbọ́ fun ibinujẹ ọkàn, ati fun ìsin lile. OLUWA si sọ fun Mose pe, Wọle, sọ fun Farao ọba Egipti pe, ki o jẹ ki awọn ọmọ Israeli ki o lọ kuro ni ilẹ rẹ̀. Mose si sọ niwaju OLUWA wipe, Kiyesi i, awọn ọmọ Israeli kò gbọ́ ti emi, Farao yio ha ti ṣe gbọ́ ti emi, emi ẹniti iṣe alaikọlà ète? OLUWA si bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ, o si fi aṣẹ fun wọn si awọn ọmọ Israeli, ati si Farao, ọba Egipti, lati mú awọn ọmọ Israeli jade ni ilẹ Egipti.

Eks 6:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn OLUWA sọ fún Mose pé, “O óo rí ohun tí n óo ṣe sí ọba Farao; ó fẹ́, ó kọ̀, yóo jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, fúnra rẹ̀ ni yóo sì fi ipá tì wọ́n jáde.” Ọlọrun tún sọ fún Mose pé, “Èmi ni OLUWA. Mo fara han Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun Olodumare, ṣugbọn n kò farahàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí OLUWA tíí ṣe orúkọ mi gan-an. Mo tún bá wọn dá majẹmu pé n óo fi ilẹ̀ Kenaani fún wọn, ilẹ̀ tí wọ́n ti jẹ́ àlejò. Mo gbọ́ ìkérora àwọn ọmọ Israẹli tí àwọn ará Ijipti dì ní ìgbèkùn, mo sì ranti majẹmu mi. Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Èmi ni OLUWA, n óo yọ yín jáde kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín, n óo yọ yín kúrò ninu ìgbèkùn wọn, ipá ni n óo sì fi rà yín pada pẹlu ìdájọ́ ńlá. N óo mu yín gẹ́gẹ́ bí eniyan mi, n óo jẹ́ Ọlọrun yín; ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó fà yín yọ kúrò lábẹ́ ẹrù wúwo tí àwọn ará Ijipti dì rù yín. N óo sì ko yín wá sí ilẹ̀ tí mo búra láti fún Abrahamu, ati Isaaki ati Jakọbu; n óo fún yín gẹ́gẹ́ bí ìní, Èmi ni OLUWA.’ ” Mose sọ ọ̀rọ̀ wọnyi fún àwọn eniyan Israẹli, ṣugbọn wọn kò fetí sí ohun tí ó ń sọ, nítorí pé ìyà burúkú tí wọn ń jẹ ní oko ẹrú ti jẹ́ kí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì. OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Wọlé lọ sí ọ̀dọ̀ Farao, ọba ilẹ̀ Ijipti, kí o wí fún un pé kí ó jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.” Ṣugbọn Mose dá OLUWA lóhùn pé, “Àwọn eniyan Israẹli gan-an kò gbọ́ tèmi, báwo ni Farao yóo ṣe gbọ́, èmi akólòlò lásánlàsàn.” Ṣugbọn Ọlọrun bá Mose ati Aaroni sọ̀rọ̀, ó wá pàṣẹ ohun tí wọn yóo sọ fún àwọn eniyan Israẹli ati fún Farao, ọba Ijipti, pé kí ó kó àwọn eniyan Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.
Eks 6:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ní OLúWA sọ fún Mose pé, “Ní ìsin yìí, ìwọ yóò rí ohun tí èmi yóò ṣe sí Farao pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi ni yóò fi jẹ́ kí wọn lọ; pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi, òun yóò lé wọn jáde kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.” Ọlọ́run sì tún sọ fún Mose pé, “Èmi ni OLúWA. Mo fi ara hàn Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu bí Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai) ṣùgbọ́n nípa orúkọ mi OLúWA, Èmi kò fi ara Mi hàn wọ́n. Èmí sì tún fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì. Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli àwọn tí àwọn ará Ejibiti mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mú Mi. “Sọ fún àwọn ará ilé Israẹli: ‘Èmi ni OLúWA, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúrò ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá. Èmi yóò mú un yín bí ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni OLúWA Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde kúrò nínú àjàgà àwọn ará Ejibiti. Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Abrahamu. Isaaki àti Jakọbu. Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, Èmi ni OLúWA.’ ” Mose sì sọ èyí fún àwọn ará Israẹli, ṣùgbọ́n wọn kò fi etí sílẹ̀ sí Mose nítorí ọkàn wọn tó rẹ̀wẹ̀sì àti nítorí ìgbèkùn búburú bí ohun tí ó ti kọ́ sọ kó wọn sí ní oko ẹrú wọn. Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Mose. “Lọ, sọ fún Farao ọba Ejibiti pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Israẹli lọ kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.” Ṣùgbọ́n Mose sọ fún OLúWA pé, “Nígbà ti àwọn ará Israẹli tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Farao yóò ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?” OLúWA bá ìran Mose àti Aaroni sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Israẹli àti Farao ọba Ejibiti, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti.