Eks 35:1-9
Eks 35:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
MOSE si pè apejọ gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, o si wi fun wọn pe, Wọnyi li ọ̀rọ ti OLUWA palaṣẹ pe, ki ẹnyin ki o ṣe wọn. Ijọ́ mẹfa ni ki a fi ṣe iṣẹ, ṣugbọn ijọ́ keje ni yio ṣe ọjọ́ mimọ́ fun nyin, ọjọ́ isimi ọ̀wọ si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹ ninu rẹ̀ li a o lupa nitõtọ. Ẹnyin kò gbọdọ da iná ni ile nyin gbogbo li ọjọ́ isimi. Mose si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, wipe, Ẹnyin mú ọrẹ wá lati inu ara nyin fun OLUWA: ẹnikẹni ti ọkàn rẹ̀ fẹ́, ki o mú u wá, li ọrẹ fun OLUWA; wurà, ati fadakà, ati idẹ; Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara, ati irun ewurẹ; Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu; Ati oróro fun fitila, ati olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn; Ati okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya.
Eks 35:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ pé kí ẹ máa ṣe nìwọ̀nyí: Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn kí ẹ ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ fún OLUWA bí ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà, pípa ni kí ẹ pa á. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dáná ní gbogbo ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi.” Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA pa láṣẹ, ó ní, ‘Ẹ gba ọrẹ jọ fún OLUWA láàrin ara yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́, lè mú ọrẹ wá fún OLUWA. Àwọn ọrẹ náà ni: wúrà, fadaka ati idẹ, aṣọ aláwọ̀ aró, ti aláwọ̀ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ati irun ewúrẹ́; awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní àwọ̀ pupa ati awọ ewúrẹ́, igi akasia, òróró ìtànná, àwọn èròjà fún òróró ìyàsímímọ́ ati fún turari olóòórùn dídùn, òkúta onikisi ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà.’
Eks 35:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mose pe gbogbo ìjọ Israẹli ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ohun ti OLúWA ti pàṣẹ fún un yín láti ṣe: Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí OLúWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa. Ẹ má ṣe dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi.” Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA pàṣẹ: Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún OLúWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún OLúWA ní ti: “wúrà, fàdákà àti idẹ; aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára; àti irun ewúrẹ́; awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù; odò igi kasia; òróró olifi fún títan iná; olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn; òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà.