Eks 35:1-35

Eks 35:1-35 Yoruba Bible (YCE)

Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ pé kí ẹ máa ṣe nìwọ̀nyí: Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn kí ẹ ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ fún OLUWA bí ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà, pípa ni kí ẹ pa á. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dáná ní gbogbo ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi.” Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA pa láṣẹ, ó ní, ‘Ẹ gba ọrẹ jọ fún OLUWA láàrin ara yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́, lè mú ọrẹ wá fún OLUWA. Àwọn ọrẹ náà ni: wúrà, fadaka ati idẹ, aṣọ aláwọ̀ aró, ti aláwọ̀ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ati irun ewúrẹ́; awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní àwọ̀ pupa ati awọ ewúrẹ́, igi akasia, òróró ìtànná, àwọn èròjà fún òróró ìyàsímímọ́ ati fún turari olóòórùn dídùn, òkúta onikisi ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà.’ “Kí gbogbo ọkunrin tí ó bá mọ iṣẹ́ ọwọ́ ninu yín jáde wá láti ṣe àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ wọnyi: àgọ́ àjọ, ati àwọn ìbòrí rẹ, àwọn ìkọ́ rẹ̀ ati àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn. Àpótí ẹ̀rí, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀, ìtẹ́ àánú rẹ̀, ati aṣọ títa rẹ̀. Tabili, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ pẹlu burẹdi ìfihàn orí rẹ̀. Ọ̀pá fìtílà fún iná títàn, ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ fìtílà rẹ̀ ati òróró fún iná títàn. Pẹpẹ turari, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati àwọn aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà. Pẹpẹ ẹbọ sísun tòun ti ojú ààrò onídẹ rẹ̀, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ ẹbọ, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn aṣọ títa ti àgbàlá ati àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. Àwọn èèkàn àgọ́, ati àwọn èèkàn àgbàlá pẹlu àwọn okùn wọn; àwọn aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa níbi mímọ́, ati àwọn ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa, ati ẹ̀wù iṣẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá túká lọ́dọ̀ Mose. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà wọ̀ lọ́kàn, tí ó sì jẹ lógún bẹ̀rẹ̀ sí pada wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọn ń mú ọrẹ wá fún kíkọ́ àgọ́ àjọ náà, ati gbogbo ohun tí wọn nílò fún àgọ́ náà, ati fún ẹ̀wù mímọ́ àwọn alufaa. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá, atọkunrin atobinrin, gbogbo àwọn tí ó tinú ọkàn wọn wá, wọ́n mú yẹtí wúrà wá, ati òrùka wúrà, ati ẹ̀gbà wúrà, ati oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn tí wọ́n fi wúrà ṣe; olukuluku wọn mú ẹ̀bùn wúrà wá fún OLUWA. Gbogbo àwọn tí wọ́n ní aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò, tabi aṣọ pupa, tabi aṣọ funfun, tabi irun ewúrẹ́, tabi awọ àgbò tí a ṣe ní pupa, tabi awọ ewúrẹ́, bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn wá. Gbogbo àwọn tí wọ́n lè fi fadaka ati idẹ tọrẹ fún OLUWA ni wọ́n mú wọn wá, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn tí wọ́n ní igi akasia, tí ó wúlò náà mú wọn wá pẹlu. Gbogbo àwọn obinrin tí wọ́n mọ òwú ran ni wọ́n ran òwú tí wọ́n sì kó o wá: àwọn òwú aláwọ̀ aró, elése àlùkò, aláwọ̀ pupa, ati funfun tí wọ́n fi ń hun aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. Gbogbo àwọn obinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún, tí wọ́n sì mọ irun ewúrẹ́ ran, ni wọ́n ran án wá. Àwọn àgbààgbà mú òkúta onikisi wá ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà, ati oríṣìíríṣìí èròjà ati òróró ìtànná, ati ti ìyàsímímọ́, ati fún turari olóòórùn dídùn. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọkunrin ati lobinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún ni wọ́n mú ọrẹ àtinúwá wá fún OLUWA, láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose. Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “OLUWA fúnra rẹ̀ ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda. Ọlọrun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ sinu rẹ̀, ó sì ti fún un ní ọgbọ́n, òye, ati ìmọ̀ ninu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà, láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà; láti gé oríṣìíríṣìí òkúta iyebíye ati láti tò wọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni igi gbígbẹ́ ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà ṣíṣe. Ọlọrun sì ti mí ìmísí rẹ̀ sí i ninu láti kọ́ ẹlòmíràn, àtòun ati Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani. Ọlọrun ti fún wọn ní ìmọ̀ oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí àwọn oníṣọ̀nà máa ń ṣe, ati ti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati ti àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ, ìbáà jẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò tabi aṣọ pupa tabi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ tabi oríṣìí aṣọ mìíràn, gbogbo iṣẹ́ ọnà ni wọn yóo máa ṣe; kò sì sí iṣẹ́ ọnà tí wọn kò lè ṣe.

Eks 35:1-35 Bibeli Mimọ (YBCV)

MOSE si pè apejọ gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, o si wi fun wọn pe, Wọnyi li ọ̀rọ ti OLUWA palaṣẹ pe, ki ẹnyin ki o ṣe wọn. Ijọ́ mẹfa ni ki a fi ṣe iṣẹ, ṣugbọn ijọ́ keje ni yio ṣe ọjọ́ mimọ́ fun nyin, ọjọ́ isimi ọ̀wọ si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹ ninu rẹ̀ li a o lupa nitõtọ. Ẹnyin kò gbọdọ da iná ni ile nyin gbogbo li ọjọ́ isimi. Mose si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, wipe, Ẹnyin mú ọrẹ wá lati inu ara nyin fun OLUWA: ẹnikẹni ti ọkàn rẹ̀ fẹ́, ki o mú u wá, li ọrẹ fun OLUWA; wurà, ati fadakà, ati idẹ; Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara, ati irun ewurẹ; Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu; Ati oróro fun fitila, ati olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn; Ati okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya. Gbogbo ọlọgbọ́n inú ninu nyin yio si wá, yio si wá ṣiṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ; Ibugbé na, ti on ti agọ́ rẹ̀, ati ibori rẹ̀, kọkọrọ rẹ̀, ati apáko rẹ̀, ọpá rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀; Apoti nì, ati ọpá rẹ̀, itẹ́-ãnu nì, ati aṣọ-ikele na; Tabili na, ati ọpá rẹ̀, ati ohun-èlo rẹ̀ gbogbo, ati àkara ifihàn nì; Ati ọpà-fitila na fun titanna, ati ohun-elo rẹ̀, ati fitila rẹ̀, pẹlu oróro fun titanna. Ati pẹpẹ turari, ati ọpá rẹ̀, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-sisorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na, ani atiwọle ẹnu agọ́ na; Ati pẹpẹ ẹbọsisun, ti on ti àwọn oju-àro idẹ rẹ̀, ati ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, agbada na ti on ti ẹsẹ rẹ̀; Aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agbalá na; Ekàn agọ́ na, ati ekàn agbalá na, ati okùn wọn; Aṣọ ìsin wọnni, lati sìn ni ibi mimọ́, aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa. Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si lọ kuro ni iwaju Mose. Nwọn si wá, olukuluku ẹniti ọkàn rẹ́ ru ninu rẹ̀, ati olukuluku ẹniti ọkàn rẹ̀ mu u fẹ́, nwọn si mú ọrẹ OLUWA wá fun iṣẹ agọ́ ajọ na, ati fun ìsin rẹ̀ gbogbo, ati fun aṣọ mimọ́ wọnni. Nwọn si wá, ati ọkunrin ati obinrin, iye awọn ti ọkàn wọn fẹ́, nwọn si mú jufù wá, ati oruka-eti, ati oruka-àmi, ati ilẹkẹ wurà, ati onirũru ohun ọṣọ́ wurà; ati olukuluku enia ti o nta ọrẹ, o ta ọrẹ wurà fun OLUWA. Ati olukuluku enia lọdọ ẹniti a ri aṣọ-alaró, ati elesè àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ daradara, ati irun ewurẹ, ati awọ àgbo pupa, ati awọ seali, mú wọn wá. Olukuluku ẹniti o ta ọrẹ fadakà ati idẹ, o mú ọrẹ OLUWA wá: ati olukuluku enia lati ọdọ ẹniti a ri igi ṣittimu fun iṣẹkiṣẹ ìsin na, mú u wá. Ati gbogbo awọn obinrin ti iṣe ọlọgbọ́n inu, nwọn fi ọwọ́ wọn ranwu, nwọn si mú eyiti nwọn ran wá, ti alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ati ti ọ̀gbọ daradara. Ati gbogbo awọn obinrin inu ẹniti o ru soke li ọgbọ́n nwọn ran irun ewurẹ. Ati awọn ijoye mú okuta oniki wá, ati okuta ti a o tò, fun ẹ̀wu-efodi nì, ati fun igbàiya nì; Ati olõrùn, ati oróro; fun fitila, ati fun oróro itasori, ati fun turari didùn. Awọn ọmọ Israeli ta ọrẹ atinuwa fun OLUWA; olukuluku ọkunrin ati obinrin, ẹniti ọkàn wọn mu wọn fẹ́ lati mú u wá fun onirũru iṣẹ, ti OLUWA palaṣẹ ni ṣiṣe lati ọwọ́ Mose wá, Mose si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Wò o, OLUWA ti pè Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah, li orukọ. O si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, li oyé, ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà; Ati lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ, Ati li okuta gbigbẹ́ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà. O si fi sinu ọkàn rẹ̀ lati ma kọni, ati on, ati Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani. O si fi ọgbọ́n inu kún wọn, lati ṣe onirũru iṣẹ, ti alagbẹdẹ, ati ti ọnà, ati ti agunnà, li aṣọ-alaró, ati li elesè-àluko, li ododó, ati li ọ̀gbọ daradara, ati ti ahunṣọ, ati ti awọn ẹniti nṣe iṣẹkiṣẹ ati ti awọn ẹniti nhumọ̀ iṣẹ-ọnà.

Eks 35:1-35 Yoruba Bible (YCE)

Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó wí fún wọn pé, “Àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ pé kí ẹ máa ṣe nìwọ̀nyí: Ọjọ́ mẹfa ni kí ẹ máa fi ṣiṣẹ́, ṣugbọn kí ẹ ya ọjọ́ keje sọ́tọ̀ fún OLUWA bí ọjọ́ ìsinmi tí ó lọ́wọ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà, pípa ni kí ẹ pa á. Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ dáná ní gbogbo ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi.” Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA pa láṣẹ, ó ní, ‘Ẹ gba ọrẹ jọ fún OLUWA láàrin ara yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́, lè mú ọrẹ wá fún OLUWA. Àwọn ọrẹ náà ni: wúrà, fadaka ati idẹ, aṣọ aláwọ̀ aró, ti aláwọ̀ elése àlùkò, ati aṣọ pupa, aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ati irun ewúrẹ́; awọ àgbò tí wọ́n ṣe ní àwọ̀ pupa ati awọ ewúrẹ́, igi akasia, òróró ìtànná, àwọn èròjà fún òróró ìyàsímímọ́ ati fún turari olóòórùn dídùn, òkúta onikisi ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà.’ “Kí gbogbo ọkunrin tí ó bá mọ iṣẹ́ ọwọ́ ninu yín jáde wá láti ṣe àwọn nǹkan tí OLUWA pa láṣẹ wọnyi: àgọ́ àjọ, ati àwọn ìbòrí rẹ, àwọn ìkọ́ rẹ̀ ati àwọn àkànpọ̀ igi rẹ̀, àwọn ọ̀pá rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn. Àpótí ẹ̀rí, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀, ìtẹ́ àánú rẹ̀, ati aṣọ títa rẹ̀. Tabili, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati gbogbo àwọn ohun èlò rẹ̀ pẹlu burẹdi ìfihàn orí rẹ̀. Ọ̀pá fìtílà fún iná títàn, ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ fìtílà rẹ̀ ati òróró fún iná títàn. Pẹpẹ turari, ati àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati òróró ìyàsímímọ́, ati turari olóòórùn dídùn, ati àwọn aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà. Pẹpẹ ẹbọ sísun tòun ti ojú ààrò onídẹ rẹ̀, pẹlu àwọn ọ̀pá rẹ̀ ati àwọn ohun èlò tí ó jẹ mọ́ ti pẹpẹ ẹbọ, agbada omi ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọn aṣọ títa ti àgbàlá ati àwọn òpó rẹ̀ ati ìtẹ́lẹ̀ àwọn òpó ati aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. Àwọn èèkàn àgọ́, ati àwọn èèkàn àgbàlá pẹlu àwọn okùn wọn; àwọn aṣọ tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí fún ṣíṣe iṣẹ́ alufaa níbi mímọ́, ati àwọn ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa, ati ẹ̀wù iṣẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, tí wọn yóo máa fi ṣe iṣẹ́ alufaa.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá túká lọ́dọ̀ Mose. Lẹ́yìn náà gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà wọ̀ lọ́kàn, tí ó sì jẹ lógún bẹ̀rẹ̀ sí pada wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, wọn ń mú ọrẹ wá fún kíkọ́ àgọ́ àjọ náà, ati gbogbo ohun tí wọn nílò fún àgọ́ náà, ati fún ẹ̀wù mímọ́ àwọn alufaa. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá, atọkunrin atobinrin, gbogbo àwọn tí ó tinú ọkàn wọn wá, wọ́n mú yẹtí wúrà wá, ati òrùka wúrà, ati ẹ̀gbà wúrà, ati oríṣìíríṣìí ohun èlò mìíràn tí wọ́n fi wúrà ṣe; olukuluku wọn mú ẹ̀bùn wúrà wá fún OLUWA. Gbogbo àwọn tí wọ́n ní aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò, tabi aṣọ pupa, tabi aṣọ funfun, tabi irun ewúrẹ́, tabi awọ àgbò tí a ṣe ní pupa, tabi awọ ewúrẹ́, bẹ̀rẹ̀ sí kó wọn wá. Gbogbo àwọn tí wọ́n lè fi fadaka ati idẹ tọrẹ fún OLUWA ni wọ́n mú wọn wá, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn tí wọ́n ní igi akasia, tí ó wúlò náà mú wọn wá pẹlu. Gbogbo àwọn obinrin tí wọ́n mọ òwú ran ni wọ́n ran òwú tí wọ́n sì kó o wá: àwọn òwú aláwọ̀ aró, elése àlùkò, aláwọ̀ pupa, ati funfun tí wọ́n fi ń hun aṣọ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́. Gbogbo àwọn obinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún, tí wọ́n sì mọ irun ewúrẹ́ ran, ni wọ́n ran án wá. Àwọn àgbààgbà mú òkúta onikisi wá ati òkúta tí wọn yóo tò sí ara efodu ati sí ara aṣọ ìgbàyà, ati oríṣìíríṣìí èròjà ati òróró ìtànná, ati ti ìyàsímímọ́, ati fún turari olóòórùn dídùn. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọkunrin ati lobinrin tí ọ̀rọ̀ náà jẹ lógún ni wọ́n mú ọrẹ àtinúwá wá fún OLUWA, láti fi ṣe iṣẹ́ tí OLUWA pa láṣẹ fún Mose. Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “OLUWA fúnra rẹ̀ ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ ọmọ Huri, láti inú ẹ̀yà Juda. Ọlọrun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ sinu rẹ̀, ó sì ti fún un ní ọgbọ́n, òye, ati ìmọ̀ ninu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà, láti fi wúrà ati fadaka ati idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà; láti gé oríṣìíríṣìí òkúta iyebíye ati láti tò wọ́n, bẹ́ẹ̀ náà ni igi gbígbẹ́ ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà ṣíṣe. Ọlọrun sì ti mí ìmísí rẹ̀ sí i ninu láti kọ́ ẹlòmíràn, àtòun ati Oholiabu ọmọ Ahisamaki láti inú ẹ̀yà Dani. Ọlọrun ti fún wọn ní ìmọ̀ oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí àwọn oníṣọ̀nà máa ń ṣe, ati ti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ati ti àwọn tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ọnà sí ara aṣọ, ìbáà jẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró, tabi ti elése àlùkò tabi aṣọ pupa tabi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ tabi oríṣìí aṣọ mìíràn, gbogbo iṣẹ́ ọnà ni wọn yóo máa ṣe; kò sì sí iṣẹ́ ọnà tí wọn kò lè ṣe.

Eks 35:1-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Mose pe gbogbo ìjọ Israẹli ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ohun ti OLúWA ti pàṣẹ fún un yín láti ṣe: Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí OLúWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa. Ẹ má ṣe dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi.” Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA pàṣẹ: Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún OLúWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún OLúWA ní ti: “wúrà, fàdákà àti idẹ; aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára; àti irun ewúrẹ́; awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù; odò igi kasia; òróró olifi fún títan iná; olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn; òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà. “Gbogbo ẹni tí ó ní ọgbọ́n láàrín yín, kí ó wa, kí ó sì wá ṣe gbogbo ohun tí OLúWA ti pàṣẹ: “àgọ́ náà pẹ̀lú àgọ́ rẹ àti ìbòrí rẹ̀, kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ọ̀wọ́n rẹ̀ àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀; Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ìbò àánú àti aṣọ títa náà tí ó ṣíji bò ó; Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà; Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná; Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn; aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu-ọ̀nà sí àgọ́ náà; Pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú ojú ààrò idẹ rẹ̀, òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; agbada idẹ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀; aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú, ọ̀wọ́n àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà; Èèkàn àgọ́ náà fún àgọ́ náà àti fún àgbàlá àti okùn wọn; aṣọ híhun láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́ aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n sìn bí àlùfáà.” Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì kúrò níwájú Mose, Olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún OLúWA, fún iṣẹ́ àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún aṣọ mímọ́ náà. Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ̀ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀ṣọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún OLúWA. Olúkúlùkù ẹni tí ó ni aṣọ aláró elése àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a rì ní pupa tàbí awọ màlúù odò, kí ó mú wọn wá. Àwọn tí ó mú ọrẹ fàdákà tàbí idẹ wá, mú ọrẹ wá fún OLúWA, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní igi ṣittimu fún ipa kankan nínú iṣẹ́ mú un wá. Gbogbo àwọn obìnrin tí ó ní ọgbọ́n ríran owú pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, kí ó mú èyí ti ó ti ran wá ti aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó tàbí ti ọ̀gbọ̀ dáradára. Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́ Àwọn olórí mú òkúta óníkìsì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù efodu àti ìgbàyà. Wọ́n sì tún mú olóòórùn àti òróró olifi wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn. Gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún OLúWA fún gbogbo iṣẹ́ tí OLúWA ti pàṣẹ fún wọn láti ṣe nípasẹ̀ Mose. Nígbà náà ni Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Wò ó, OLúWA ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, Ó sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún un, pẹ̀lú ọgbọ́n, òye, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà Láti máa ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ, láti gbẹ́ òkúta àti láti tò ó, láti fún igi àti láti ṣiṣẹ́ ni gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. Ó sì fún òun àti Oholiabu ọmọ Ahisamaki ti ẹ̀yà Dani, ni agbára láti kọ́ àwọn tókù. Ó sì fi ọgbọ́n kún wọn láti ṣe gbogbo onírúurú iṣẹ́, ti oníṣọ̀nà, ti ayàwòrán, ti aránsọ, ti aláṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ní ọ̀gbọ̀ dáradára àti ti ahunṣọ, gbogbo èyí tí ọ̀gá oníṣẹ́-ọnà àti ayàwòrán ń ṣe.