Eks 24:3-8
Eks 24:3-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mose si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ OLUWA, ati gbogbo idajọ fun awọn enia: gbogbo enia si fi ohùn kan dahùn wipe, Gbogbo ọ̀rọ ti OLUWA wi li awa o ṣe. Mose si kọwe gbogbo ọ̀rọ OLUWA, o si dide ni kùtukutu owurọ̀, o si tẹ́ pẹpẹ kan nisalẹ òke na, o mọ ọwọ̀n mejila, gẹgẹ bi ẹ̀ya Israeli mejila. O si rán awọn ọdọmọkunrin ninu awọn ọmọ Israeli, nwọn si ru ẹbọ sisun, nwọn si fi akọmalu ru ẹbọ alafia si OLUWA. Mose si mú àbọ ẹ̀jẹ na o si fi i sinu awokòto; ati àbọ ẹ̀jẹ na o fi wọ́n ara pẹpẹ na. O si mú iwé majẹmu nì, o si kà a li eti awọn enia: nwọn si wipe, Gbogbo eyiti OLUWA wi li awa o ṣe, awa o si gbọràn. Mose si mú ẹ̀jẹ na, o si wọ́n ọ sara awọn enia, o si wipe, Kiyesi ẹ̀jẹ majẹmu, ti OLUWA bá nyin dá nipasẹ ọ̀rọ gbogbo wọnyi.
Eks 24:3-8 Yoruba Bible (YCE)
Mose bá tọ àwọn eniyan náà lọ, ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA sọ fún un fún wọn, ati gbogbo ìlànà tí ó là sílẹ̀, gbogbo àwọn eniyan náà sì fi ẹnu kò, wọ́n dáhùn pé, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” Mose bá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, ó dìde, ó tẹ́ pẹpẹ kan sí ìsàlẹ̀ òkè náà, ó ri ọ̀wọ̀n mejila mọ́lẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan. Ó sì rán àwọn kan ninu àwọn ọdọmọkunrin Israẹli, pé kí wọ́n lọ fi mààlúù rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Mose gba ìdajì ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran náà sinu àwo ńlá, ó sì da ìdajì yòókù sí ara pẹpẹ náà. Ó mú ìwé majẹmu náà, ó kà á sí etígbọ̀ọ́ gbogbo àwọn eniyan, wọ́n sì dáhùn pé, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe, a óo sì gbọ́ràn.” Ni Mose bá gba ẹ̀jẹ̀ ẹran yòókù tí ó wà ninu àwo, ó wọ́n ọn sí àwọn eniyan náà lára, ó ní, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí OLUWA bá yín dá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí mo sọ.”
Eks 24:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà ti Mose lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin OLúWA, wọ́n wí ní ohùn kan pé, “Gbogbo ohun ti OLúWA wí ni àwa yóò ṣe.” Nígbà náà ni Mose kọ gbogbo ohun tí OLúWA sọ sílẹ̀. Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà. Ó ṣe ọ̀wọ́n òkúta méjìlá. Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá. Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Israẹli, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si OLúWA. Mose bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ. Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí OLúWA wí: Àwa yóò sì gbọ́rọ̀.” Nígbà náà ni Mose gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”