ẸKISODU 24:3-8

ẸKISODU 24:3-8 YCE

Mose bá tọ àwọn eniyan náà lọ, ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA sọ fún un fún wọn, ati gbogbo ìlànà tí ó là sílẹ̀, gbogbo àwọn eniyan náà sì fi ẹnu kò, wọ́n dáhùn pé, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” Mose bá kọ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀. Nígbà tí ó di òwúrọ̀ kutukutu, ó dìde, ó tẹ́ pẹpẹ kan sí ìsàlẹ̀ òkè náà, ó ri ọ̀wọ̀n mejila mọ́lẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan. Ó sì rán àwọn kan ninu àwọn ọdọmọkunrin Israẹli, pé kí wọ́n lọ fi mààlúù rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia sí OLUWA. Mose gba ìdajì ninu ẹ̀jẹ̀ ẹran náà sinu àwo ńlá, ó sì da ìdajì yòókù sí ara pẹpẹ náà. Ó mú ìwé majẹmu náà, ó kà á sí etígbọ̀ọ́ gbogbo àwọn eniyan, wọ́n sì dáhùn pé, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe, a óo sì gbọ́ràn.” Ni Mose bá gba ẹ̀jẹ̀ ẹran yòókù tí ó wà ninu àwo, ó wọ́n ọn sí àwọn eniyan náà lára, ó ní, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí OLUWA bá yín dá, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí mo sọ.”