Eks 21:33-36
Eks 21:33-36 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi ẹnikan ba ṣi ihò silẹ, tabi bi ọkunrin kan ba si wà ihò silẹ, ti kò si bò o, ti akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ba bọ́ sinu rẹ̀; Oni-ihò na yio si san; yio si fi owo fun oluwa wọn; okú ẹran a si jẹ́ tirẹ̀. Bi akọmalu ẹnikan ba si pa akọmalu ẹnikeji lara ti o si kú; ki nwọn ki o tà ãye akọmalu, ki nwọn ki o si pín owo rẹ̀; oku ni ki nwọn ki o si pín pẹlu. Tabi bi a ba si mọ̀ pe akọmalu na a ti ma kàn nigba atijọ ti oluwa rẹ̀ kò sé e mọ́; on o fi akọmalu san akọmalu nitõtọ; okú a si jẹ́ tirẹ̀.
Eks 21:33-36 Yoruba Bible (YCE)
“Bí ẹnìkan bá gbẹ́ kòtò sílẹ̀, tí kò bá bò ó, tabi tí ó gbẹ́ kòtò tí kò sì dí i, bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tabi mààlúù bá já sinu kòtò yìí, tí ó sì kú, ẹni tí ó gbẹ́ kòtò yìí gbọdọ̀ san owó mààlúù tabi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún ẹni tí ó ni ín, òkú ẹran yìí yóo sì di ti ẹni tí ó gbẹ́ kòtò. Bí mààlúù ẹnìkan bá pa ti ẹlòmíràn, àwọn mejeeji yóo ta mààlúù tí ó jẹ́ ààyè, wọn yóo pín owó rẹ̀, wọn yóo sì pín òkú mààlúù náà pẹlu. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé mààlúù yìí ti máa ń kàn tẹ́lẹ̀, tí ẹni tí ó ni ín kò sì mú un so, yóo fi mààlúù mìíràn rọ́pò èyí tí mààlúù rẹ̀ pa, òkú mààlúù yóo sì di tirẹ̀.
Eks 21:33-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Bí ọkùnrin kan bá ṣí kòtò sílẹ̀ láìbò tàbí kí ó gbẹ́ kòtò sílẹ̀ láìbò, tí màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá ṣe bẹ́ẹ̀ bọ́ sínú kòtò náà. Ẹni tí ó ni kòtò yóò san owó àdánù yìí fún ẹni tí ó ni ẹran. Òkú ẹran náà yóò sì di tirẹ̀. “Bí akọ màlúù ọkùnrin kan bá pa akọ màlúù ẹlòmíràn lára tí ó sì kú, wọn yóò ta akọ màlúù tó wà láààyè, wọn yóò sì pín owó èyí tiwọn tà àti ẹran èyí tí ó kú dọ́gbadọ́gba. Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo tí akọ màlúù náà máa ń kan òmíràn, tí olówó rẹ̀ kò sì mú un so, olówó rẹ̀ yóò san ẹran dípò ẹran. Ẹran tí ó kú yóò sì jẹ́ tirẹ̀.