Eks 21

21
1NJẸ wọnyi ni idajọ ti iwọ o gbekalẹ niwaju wọn.
2Bi iwọ ba rà ọkunrin Heberu li ẹrú, ọdún mẹfa ni on o sìn: li ọdún keje yio si jade bi omnira lọfẹ.
3Bi o ba nikan wọle wá, on o si nikan jade lọ: bi o ba ti gbé iyawo, njẹ ki aya rẹ̀ ki o bá a jade lọ.
4Bi o ba ṣepe oluwa rẹ̀ li o fun u li aya, ti on si bi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin fun u; aya ati awọn ọmọ ni yio jẹ́ ti oluwa rẹ̀, on tikara rẹ̀ yio si nikan jade lọ.
5Bi ẹru na ba si wi ni gbangba pe, Emi fẹ́ oluwa mi, aya mi, ati awọn ọmọ mi; emi ki yio jade lọ idi omnira:
6Nigbana ni ki oluwa rẹ̀ ki o mú u lọ sọdọ awọn onidajọ; yio si mú u lọ si ẹnu-ọ̀na, tabi si opó ẹnu-ọ̀na; oluwa rẹ̀ yio si fi olù lú u li eti; on a si ma sìn i titi aiye.
7Bi ẹnikan ba si tà ọmọ rẹ̀ obinrin li ẹrú, on ki yio jade lọ bi awọn ẹrú ọkunrin ti ijade lọ.
8Bi on kò ba wù oluwa rẹ̀, ti o ti fẹ́ ẹ fun ara rẹ̀, njẹ ki o jẹ ki a rà a pada, on ki yio lagbara lati tà a fun ajeji enia, o sa ti tàn a jẹ.
9Bi o ba si fẹ́ ẹ fun ọmọkunrin rẹ̀, ki o ma ṣe si i bi a ti iṣe si ọmọbinrin ẹni.
10Bi o ba si fẹ́ obinrin miran; onjẹ rẹ̀, aṣọ rẹ̀, ati iṣe ọkọlaya rẹ̀, ki o máṣe yẹ̀.
11Bi on ki yio ba si ṣe ohun mẹtẹta yi fun u, njẹ ki on ki o jade kuro lọfẹ li aisan owo.
12Ẹniti o ba lù enia, tobẹ̃ ti o si ku, pipa li a o pa a.
13Bi o ba ṣepe enia kò ba dèna, ṣugbọn ti o ṣepe Ọlọrun li o fi lé e lọwọ, njẹ emi o yàn ibi fun ọ, nibiti on o gbé salọ si.
14Ṣugbọn bi enia ba ṣìka si aladugbo rẹ̀, lati fi ẹ̀tan pa a; ki iwọ ki o tilẹ mú u lati ibi pẹpẹ mi lọ, ki o le kú.
15Ẹniti o ba si lù baba, tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a.
16Ẹniti o ba si ji enia, ti o si tà a, tabi ti a ri i li ọwọ́ rẹ̀, pipa li a o pa a.
17Ẹniti o ba si bú baba tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a.
18Bi awọn ọkunrin ba si jùmọ̀ njà, ti ekini fi okuta lù ekeji, tabi ti o jìn i li ẹsẹ̀, ti on kò si kú ṣugbọn ti o da a bulẹ:
19Bi o ba si tun dide, ti o ntẹ̀ ọpá rìn kiri ni ita, nigbana li ẹniti o lù u yio to bọ́; kìki gbèse akokò ti o sọnù ni yio san, on o si ṣe ati mu u lara da ṣaṣa.
20Bi ẹnikan ba si fi ọpá lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin, ti o si kú si i li ọwọ́, a o gbẹsan rẹ̀ nitõtọ.
21Ṣugbọn bi o ba duro di ijọ́ kan, tabi meji, a ki yio gbẹsan rẹ̀: nitoripe owo rẹ̀ ni iṣe.
22Bi awọn ọkunrin ba njà, ti nwọn si pa obinrin aboyún lara, tobẹ̃ ti oyún rẹ̀ ṣẹ́, ṣugbọn ti ibi miran kò si pẹlu: a o mu ki o san nitõtọ, gẹgẹ bi ọkọ obinrin na yio ti dá lé e; on o si san a niwaju onidajọ.
23Bi ibi kan ba si pẹlu, njẹ ki iwọ ki o fi ẹmi dipò ẹmi.
24Fi oju dipò oju, ehín dipò ehín, ọwọ́ dipò ọwọ́, ẹsẹ̀ dipò ẹsẹ̀.
25Fi ijóna dipò ijóna, ọgbẹ́, dipò ọgbẹ́, ìna dipò ìna.
26Bi o ba ṣepe ẹnikan ba lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi ẹrú rẹ̀ obinrin li oju ti o si fọ́; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori oju rẹ̀.
27Bi o ba si ká ehín ẹrú rẹ̀ ọkunrin, tabi ehín ẹrú rẹ̀ obinrin; ki o si jọwọ rẹ̀ lọ li omnira nitori ehín rẹ̀.
28Bi akọmalu ba kàn ọkunrin tabi obinrin ti o si kú: sísọ ni ki a sọ akọmalu na li okuta pa bi o ti wù ki o ṣe, ki a má si ṣe jẹ ẹran rẹ̀; ṣugbọn ọrùn oni-akọmalu na yio mọ́.
29Ṣugbọn bi o ba ṣepe akọmalu na a ti ma fi iwo rẹ̀ kàn nigba atijọ, ti a si ti kìlọ fun oluwa rẹ̀, ti kò si sé e mọ, ṣugbọn ti o pa ọkunrin tabi obinrin, akọmalu na li a o sọ li okuta pa, oluwa rẹ̀ li a o si lù pa pẹlu.
30Bi o ba si ṣepe a bù iye owo kan fun u, njẹ iyekiye ti a bù fun u ni yio fi ṣe irapada ẹmi rẹ̀.
31Iba kàn ọmọkunrin, tabi iba kàn ọmọbinrin, gẹgẹ bi irú idajọ yi li a o ṣe si i.
32Bi akọmalu na ba kan ẹrukunrin tabi ẹrubirin; on o si san ọgbọ̀n ṣekeli fadakà fun oluwa rẹ̀, a o si sọ akọmalu na li okuta pa.
33Bi ẹnikan ba ṣi ihò silẹ, tabi bi ọkunrin kan ba si wà ihò silẹ, ti kò si bò o, ti akọmalu tabi kẹtẹkẹtẹ ba bọ́ sinu rẹ̀;
34Oni-ihò na yio si san; yio si fi owo fun oluwa wọn; okú ẹran a si jẹ́ tirẹ̀.
35Bi akọmalu ẹnikan ba si pa akọmalu ẹnikeji lara ti o si kú; ki nwọn ki o tà ãye akọmalu, ki nwọn ki o si pín owo rẹ̀; oku ni ki nwọn ki o si pín pẹlu.
36Tabi bi a ba si mọ̀ pe akọmalu na a ti ma kàn nigba atijọ ti oluwa rẹ̀ kò sé e mọ́; on o fi akọmalu san akọmalu nitõtọ; okú a si jẹ́ tirẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Eks 21: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀