Eks 21:1-21
Eks 21:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ wọnyi ni idajọ ti iwọ o gbekalẹ niwaju wọn. Bi iwọ ba rà ọkunrin Heberu li ẹrú, ọdún mẹfa ni on o sìn: li ọdún keje yio si jade bi omnira lọfẹ. Bi o ba nikan wọle wá, on o si nikan jade lọ: bi o ba ti gbé iyawo, njẹ ki aya rẹ̀ ki o bá a jade lọ. Bi o ba ṣepe oluwa rẹ̀ li o fun u li aya, ti on si bi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin fun u; aya ati awọn ọmọ ni yio jẹ́ ti oluwa rẹ̀, on tikara rẹ̀ yio si nikan jade lọ. Bi ẹru na ba si wi ni gbangba pe, Emi fẹ́ oluwa mi, aya mi, ati awọn ọmọ mi; emi ki yio jade lọ idi omnira: Nigbana ni ki oluwa rẹ̀ ki o mú u lọ sọdọ awọn onidajọ; yio si mú u lọ si ẹnu-ọ̀na, tabi si opó ẹnu-ọ̀na; oluwa rẹ̀ yio si fi olù lú u li eti; on a si ma sìn i titi aiye. Bi ẹnikan ba si tà ọmọ rẹ̀ obinrin li ẹrú, on ki yio jade lọ bi awọn ẹrú ọkunrin ti ijade lọ. Bi on kò ba wù oluwa rẹ̀, ti o ti fẹ́ ẹ fun ara rẹ̀, njẹ ki o jẹ ki a rà a pada, on ki yio lagbara lati tà a fun ajeji enia, o sa ti tàn a jẹ. Bi o ba si fẹ́ ẹ fun ọmọkunrin rẹ̀, ki o ma ṣe si i bi a ti iṣe si ọmọbinrin ẹni. Bi o ba si fẹ́ obinrin miran; onjẹ rẹ̀, aṣọ rẹ̀, ati iṣe ọkọlaya rẹ̀, ki o máṣe yẹ̀. Bi on ki yio ba si ṣe ohun mẹtẹta yi fun u, njẹ ki on ki o jade kuro lọfẹ li aisan owo. Ẹniti o ba lù enia, tobẹ̃ ti o si ku, pipa li a o pa a. Bi o ba ṣepe enia kò ba dèna, ṣugbọn ti o ṣepe Ọlọrun li o fi lé e lọwọ, njẹ emi o yàn ibi fun ọ, nibiti on o gbé salọ si. Ṣugbọn bi enia ba ṣìka si aladugbo rẹ̀, lati fi ẹ̀tan pa a; ki iwọ ki o tilẹ mú u lati ibi pẹpẹ mi lọ, ki o le kú. Ẹniti o ba si lù baba, tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a. Ẹniti o ba si ji enia, ti o si tà a, tabi ti a ri i li ọwọ́ rẹ̀, pipa li a o pa a. Ẹniti o ba si bú baba tabi iya rẹ̀, pipa li a o pa a. Bi awọn ọkunrin ba si jùmọ̀ njà, ti ekini fi okuta lù ekeji, tabi ti o jìn i li ẹsẹ̀, ti on kò si kú ṣugbọn ti o da a bulẹ: Bi o ba si tun dide, ti o ntẹ̀ ọpá rìn kiri ni ita, nigbana li ẹniti o lù u yio to bọ́; kìki gbèse akokò ti o sọnù ni yio san, on o si ṣe ati mu u lara da ṣaṣa. Bi ẹnikan ba si fi ọpá lù ẹrú rẹ̀ ọkunrin tabi obinrin, ti o si kú si i li ọwọ́, a o gbẹsan rẹ̀ nitõtọ. Ṣugbọn bi o ba duro di ijọ́ kan, tabi meji, a ki yio gbẹsan rẹ̀: nitoripe owo rẹ̀ ni iṣe.
Eks 21:1-21 Yoruba Bible (YCE)
“Àwọn òfin tí o gbọdọ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli nìwọ̀nyí: Bí ẹnikẹ́ni bá ra Heberu kan lẹ́rú, ọdún mẹfa ni ẹrú náà óo fi sìn ín, ní ọdún keje, ó níláti dá a sílẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìgba ohunkohun lọ́wọ́ rẹ̀. Bí ó bá jẹ́ pé òun nìkan ni ó rà, òun nìkan ni òfin dá sílẹ̀, ṣugbọn bí ẹrú náà bá mú aya rẹ̀ lọ́wọ́ wá, bí ó bá ti ń dá a sílẹ̀, ó gbọdọ̀ dá aya rẹ̀ sílẹ̀ pẹlu. Bí olówó rẹ̀ bá fẹ́ aya fún un, tí aya náà sì bímọ fún un, lọkunrin ati lobinrin, olówó rẹ̀ ni ó ni aya ati àwọn ọmọ patapata, òun nìkan ni òfin dá sílẹ̀. Ṣugbọn bí ẹrú náà bá fúnra rẹ̀ wí ní gbangba pé òun fẹ́ràn olówó òun, ati aya òun, ati àwọn ọmọ òun, nítorí náà òun kò ní gba ìdásílẹ̀, kí òun má baà fi wọ́n sílẹ̀, olówó rẹ̀ yóo mú un wá siwaju Ọlọrun, ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ tabi òpó ìlẹ̀kùn, olówó rẹ̀ yóo fi òòlù lu ihò sí etí rẹ̀, ẹrú náà yóo sì di tirẹ̀ títí ayé. “Bí ẹnìkan bá ta ọmọ rẹ̀ obinrin lẹ́rú, ẹrubinrin yìí kò ní jáde bí ẹrukunrin. Bí ẹrubinrin yìí kò bá wù olówó rẹ̀ láti fi ṣe aya, ó níláti dá a pada fún baba rẹ̀, baba rẹ̀ yóo sì rà á pada. Olówó rẹ̀ kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á fún àjèjì nítorí pé òun ló kọ̀ tí kò ṣe ẹ̀tọ́ fún un. Bí ó bá fẹ́ ẹ sọ́nà fún ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ó gbọdọ̀ ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ gan-an. Bí ó bá fẹ́ aya mìíràn fún ara rẹ̀, kò gbọdọ̀ dín oúnjẹ ẹrubinrin yìí kù, tabi aṣọ rẹ̀ tabi àwọn ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aya. Bí olówó ẹrubinrin yìí bá kọ̀, tí kò ṣe àwọn nǹkan mẹtẹẹta náà fún ẹrubinrin rẹ̀, ẹrubinrin náà lẹ́tọ̀ọ́ láti jáde ní ilé rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́ láìsan ohunkohun. “Bí ẹnikẹ́ni bá lu eniyan pa, pípa ni a óo pa òun náà. Ṣugbọn bí olúwarẹ̀ kò bá mọ̀ọ́nmọ̀ pa á, tí ó jẹ́ pé ó ṣèèṣì ni, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè sálọ sí ibìkan tí n óo yàn fún yín. Ṣugbọn bí ẹnìkan bá mọ̀ọ́nmọ̀ bá ẹlòmíràn jà, tí ó sì fi ọgbọ́n àrékérekè pa á, bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá sálọ sí ibi pẹpẹ mi, fífà ni kí ẹ fà á kúrò níbi pẹpẹ náà kí ẹ sì pa á. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu baba tabi ìyá rẹ̀, pípa ni kí wọ́n pa òun náà. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jí eniyan gbé, kì báà jẹ́ pé ó ti tà á, tabi kí wọ́n ká a mọ́ ọn lọ́wọ́, pípa ni kí wọ́n pa á. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé baba tabi ìyá rẹ̀ ṣépè, pípa ni kí wọ́n pa á. “Bí eniyan meji bá ń jà, tí ọ̀kan bá fi òkúta tabi ẹ̀ṣẹ́ lu ekeji, tí ẹni tí wọ́n lù náà kò bá kú, ṣugbọn tí ó farapa, bí ẹni tí wọ́n lù tí ó farapa náà bá dìde, tí ó sì ń fi ọ̀pá rìn kiri, ẹni tí ó lù ú bọ́ lọ́wọ́ ikú, ṣugbọn dandan ni kí ó san owó fún àkókò tí ẹni tí ó lù náà lò ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, kí ó sì ṣe ètò ìtọ́jú rẹ̀ títí yóo fi sàn. “Bí ẹnìkan bá lu ẹrukunrin tabi ẹrubinrin rẹ̀ ní kùmọ̀, tí ẹrú náà bá kú mọ́ ọn lọ́wọ́, olúwarẹ̀ yóo jìyà. Ṣugbọn bí ẹrú náà bá gbé odidi ọjọ́ kan tabi meji kí ó tó kú, kí ẹnikẹ́ni má jẹ olówó ẹrú náà níyà, nítorí òun ni ó ni owó tí ó fi rà á.
Eks 21:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Wọ̀nyí ni àwọn òfin tí ìwọ yóò gbé sí iwájú wọn: “Bí ìwọ bá yá ọkùnrin Heberu ní ìwẹ̀fà, òun yóò sìn ọ́ fún ọdún Mẹ́fà. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, òun yóò lọ ni òmìnira láìsan ohunkóhun padà. Bí ó bá wá ní òun nìkan, òun nìkan náà ni yóò padà lọ ní òmìnira; ṣùgbọ́n tí ó bá mú ìyàwó wá, ó ní láti mú ìyàwó rẹ̀ padà lọ. Bí olówó rẹ̀ bá fún un ní aya, tí aya náà sì bímọ ọkùnrin àti obìnrin, aya àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ ti olówó rẹ̀, yóò sì lọ ní òmìnira ní òun nìkan. “Bí ẹrú náà bá sì wí ní gbangba pé, mo fẹ́ràn olúwa mi, ìyàwó mi àti àwọn mi, èmi kò sì fẹ́ ẹ́ gba òmìnira mọ́: Nígbà náà ni olúwa rẹ̀ yóò mu wá sí iwájú ìdájọ́. Òun yóò sì mú un lọ sí ẹnu-ọ̀nà tàbí lọ sí ibi ọ̀wọ̀n, yóò sì fi ìlu lu etí rẹ̀, òun yóò sì máa sin olówó rẹ̀ títí ayé. “Bí ọkùnrin kan bá ta ọmọbìnrin rẹ̀ bí ìwẹ̀fà, ọmọbìnrin yìí kò nígba òmìnira bí i ti ọmọkùnrin. Bí òun kò bá sì tẹ́ olówó rẹ̀ lọ́rùn, ẹni tí ó fẹ́ ẹ fún ara rẹ̀, yóò jẹ́ kí wọn ó rà á padà, òun kò ní ẹ̀tọ́ láti tà á bí ẹrú fún àjèjì, nítorí pé òun ni kò ṣe ojúṣe rẹ̀ pẹ̀lú ìwẹ̀fà náà. Bí ó bá fẹ́ ẹ fún ọmọkùnrin rẹ̀, kò ní máa lò ó bí ìwẹ̀fà mọ́, ṣùgbọ́n yóò máa ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ obìnrin. Bí ó bá fẹ́ obìnrin mìíràn, kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ nípa fífún un ní oúnjẹ àti aṣọ, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kùnà ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ sí aya. Bí ó bá kùnà láti ṣe àwọn nǹkan mẹ́ta wọ̀nyí fún un, òun yóò lọ ní òmìnira láìsan owó kankan padà. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lu arákùnrin rẹ̀ pa, pípa ni a ó pa á. Ṣùgbọ́n bí kò bá mọ̀ ọ́n mọ̀ pa á, tí ó bá jẹ́ (àmúwá) ìfẹ́ Ọlọ́run ni, òun yóò lọ sí ibi tí èmi yóò yàn fún un. Ṣùgbọ́n tí ó bá mú arákùnrin rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀tàn pa á. Ẹ mú un kúrò ní iwájú pẹpẹ mi kí ẹ sì pa á. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá pa baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá jí ènìyàn gbé, tí ó sì tà á tàbí tí ó fi pamọ́, pípa ni a ó pa á. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè fún baba tàbí ìyá rẹ̀, pípa ni a ó pa á. “Bí àwọn ọkùnrin méjì bá ń jà, ti ọ̀kan sọ òkúta tàbí fi ìkùùkuu lu ẹnìkejì rẹ̀, tí ó sì pa á lára, ti irú ìpalára bẹ́ẹ̀ mu kí ó wà lórí ìdùbúlẹ̀ àìsàn, Ẹni tó lu ẹnìkejì rẹ̀ kò ní ní ẹ̀bi, níwọ̀n ìgbà ti ẹni tí a lù bá ti lè dìde, tí ó sì lé è fi ọ̀pá ìtìlẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ rìn káàkiri. Ẹni náà ni láti san owó ti ó fi tọ́jú ara rẹ̀ padà fún un, lẹ́yìn ìgbà tí ara rẹ̀ bá ti yá tan pátápátá. “Bí ọkùnrin kan bá fi ọ̀pá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀, ti ẹrú náà sì kú lójú ẹsẹ̀, a ó fi ìyà jẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n a kò ní fi ìyà jẹ ẹ́, ti ẹrú náà bá yè, tí ó dìde lẹ́yìn ọjọ́ kan tàbí méjì, nítorí ẹrú náà jẹ́ dúkìá rẹ̀.