Eks 19:9-25
Eks 19:9-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi tọ̀ ọ wá ninu awọsanma ṣíṣu, ki awọn enia ki o le ma gbọ́ nigbati mo ba mbá ọ sọ̀rọ, ki nwọn ki o si ma gbà ọ gbọ́ pẹlu lailai. Mose si sọ ọ̀rọ awọn enia na fun OLUWA. OLUWA si wi fun Mose pe, Tọ̀ awọn enia yi lọ, ki o si yà wọn simimọ́ li oni ati li ọla, ki nwọn ki o si fọ̀ asọ wọn. Ki nwọn ki o si mura dè ijọ́ kẹta: nitori ni ijọ́ kẹta OLUWA yio sọkalẹ sori oke Sinai li oju awọn enia gbogbo. Ki iwọ ki o si sagbàra fun awọn enia yiká, pe, Ẹ ma kiyesi ara nyin, ki ẹ máṣe gùn ori oke lọ, ki ẹ má si ṣe fọwọbà eti rẹ̀: ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn oke na, pipa ni nitõtọ: Ọwọkọwọ́ kò gbọdọ kàn a, bikoṣepe ki a sọ ọ li okuta, tabi ki a gún u pa nitõtọ; iba ṣe ẹranko iba ṣe enia, ki yio là a: nigbati ipè ba dún, ki nwọn ki o gùn oke wá. Mose si sọkalẹ lati ori oke na wá sọdọ awọn enia, o si yà awọn enia si mimọ́, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn. O si wi fun awọn enia pe, Ẹ mura dè ijọ́ kẹta: ki ẹ máṣe sunmọ aya nyin. O si ṣe, li owurọ̀ ijọ́ kẹta, ni ãrá ati mànamána wà, ati awọsanma ṣíṣu dùdu lori òke na, ati ohùn ipè na si ndún kikankikan; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti o wà ni ibudó warìri. Mose si mú awọn enia jade lati ibudó wá lati bá Ọlọrun pade; nwọn si duro ni ìha isalẹ oke na. Oke Sinai si jẹ́ kìki ẽfi, nitoriti OLUWA sọkalẹ sori rẹ̀ ninu iná: ẽfi na si goke bi ẽfi ileru, gbogbo oke na si mì tìtì. O si ṣe ti ohùn ipè si dún, ti o si mulẹ kijikiji, Mose sọ̀rọ, Ọlọrun si fi ãrá da a li ohùn. OLUWA si sọkalẹ wá si oke Sinai, lori oke na: OLUWA si pè Mose lori oke na; Mose si goke lọ. OLUWA si wi fun Mose pe, Sọkalẹ, kìlọ fun awọn enia, ki nwọn ki o má ba yà sọdọ OLUWA lati bẹ̀ ẹ wò, ki ọ̀pọ ki o má ba ṣegbe ninu wọn. Si jẹ ki awọn alufa pẹlu, ti o sunmọ OLUWA, ki o yà ara wọn si mimọ́, ki OLUWA ki o má ba kọlù wọn. Mose si wi fun OLUWA pe, Awọn enia ki yio le wá sori oke Sinai: nitoriti iwọ ti kìlọ fun wa pe, Sọ agbàra yi oke na ká, ki o si yà a si mimọ́. OLUWA si wi fun u pe, Lọ, sọkalẹ; ki iwọ ki o si goke wá, iwọ ati Aaroni pẹlu rẹ: ṣugbọn ki awọn alufa ati awọn enia ki o máṣe yà lati goke tọ̀ OLUWA wá, ki o má ba kọlù wọn. Bẹ̃ni Mose sọkalẹ tọ̀ awọn enia lọ, o si sọ̀rọ fun wọn.
Eks 19:9-25 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA sọ fún Mose pé, “Mò ń tọ̀ ọ́ bọ̀ ninu ìkùukùu tí yóo bo gbogbo ilẹ̀, kí àwọn eniyan náà lè gbọ́ nígbà tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì lè gbà ọ́ gbọ́ títí lae.” Mose sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA. OLUWA bá dá Mose lóhùn, ó ní, “Tọ àwọn eniyan náà lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ lónìí ati lọ́la. Sọ fún wọn pé kí wọ́n fọ aṣọ wọn, kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ ní ọjọ́ kẹta, nítorí pé ní ọjọ́ kẹta yìí ni èmi OLUWA óo sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, lójú gbogbo wọn. Pààlà yípo òkè náà fún wọn, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọ́n ṣọ́ra, kí wọ́n má ṣe gun òkè yìí, tabi fi ọwọ́ kan ẹsẹ̀ òkè náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè yìí, pípa ni n óo pa á. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kàn án, òkúta ni kí wọ́n sọ pa á tabi kí wọ́n ta á ní ọfà; kì báà ṣe ẹranko tabi eniyan, dandan ni kí ó kú. Nígbà tí fèrè bá dún, tí dídún rẹ̀ pẹ́, kí wọn wá sí ẹ̀bá òkè náà.” Mose bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ó tọ àwọn eniyan náà lọ, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ múrasílẹ̀ di ọ̀tunla, ẹ má ṣe súnmọ́ obinrin láti bá a lòpọ̀.” Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, ààrá bẹ̀rẹ̀ sí sán, bẹ́ẹ̀ ni mànàmáná ń kọ, ìkùukùu sì bo òkè náà mọ́lẹ̀, fèrè kan dún tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo eniyan tí wọ́n wà ninu àgọ́ wárìrì. Mose bá kó àwọn eniyan náà jáde láti pàdé Ọlọrun, wọ́n sì dúró ní ẹsẹ̀ òkè. Èéfín bo gbogbo òkè Sinai mọ́lẹ̀, nítorí pé ninu iná ni OLUWA ti sọ̀kalẹ̀ sórí rẹ̀, ọ̀wọ̀n èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ bí ọ̀wọ̀n èéfín iná ìléru ńlá, gbogbo òkè náà sì mì tìtì. Bí fèrè ti ń dún kíkankíkan tí dídún rẹ̀ sì ń gòkè sí i, bẹ́ẹ̀ ni Mose ń sọ̀rọ̀, Ọlọrun sì ń fi ààrá dá a lóhùn. OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, ó dúró ní ṣóńṣó òkè náà, ó pe Mose sọ́dọ̀, Mose sì gòkè tọ̀ ọ́ lọ. OLUWA sọ fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o sì kìlọ̀ fún àwọn eniyan náà, kí wọ́n má baà rọ́ wọ ibi tí OLUWA wà láti wò ó, kí ọpọlọpọ wọn má baà parun. Ati pé, kí àwọn alufaa tí yóo súnmọ́ ibi tí OLUWA wà, ya ara wọn sí mímọ́, kí n má baà jẹ wọ́n níyà.” Mose bá dá OLUWA lóhùn pé, “OLUWA, àwọn eniyan wọnyi kò lè gun òkè Sinai wá, nítorí pé ìwọ náà ni o pàṣẹ pé kí á pààlà yí òkè náà po, kí á sì yà á sí mímọ́.” OLUWA sì wí fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o mú Aaroni gòkè wá, ṣugbọn má ṣe jẹ́ kí àwọn alufaa ati àwọn eniyan náà rọ́ wá sórí òkè níbi tí mo wà, kí n má baà jẹ wọ́n níyà.” Mose bá sọ̀kalẹ̀ lọ bá àwọn eniyan náà, ó sì jíṣẹ́ fún wọn.
Eks 19:9-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA sọ fún Mose pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu ṣíṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mose sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún OLúWA. OLúWA sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn. Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹta, nítorí ni ọjọ́ náà ni OLúWA yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn. Kí ìwọ kí ó ṣe ààlà fún àwọn ènìyàn, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ kíyèsí ara yín, kí ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ má tilẹ̀ fi ọwọ́ ba etí rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà, ó dájú, pípa ni a ó pa á: A ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta á ní ọfà, ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án. Ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko, òun kì yóò wà láààyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.” Mose sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ múra sílẹ̀ di ọjọ́ kẹta; Ẹ má ṣe bá aya yín lòpọ̀.” Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, àrá àti mọ̀nàmọ́ná sì wà pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó ṣú dudu ní orí òkè, ìpè ńlá sì dún kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ó wà ni ibùdó wárìrì. Mose sì kó àwọn ènìyàn tí ó jáde láti ibùdó wá pàdé Ọlọ́run, wọ́n dúró nítòsí òkè. Èéfín sì bo òkè Sinai nítorí OLúWA sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ nínú iná. Èéfín náà sì ń ru sókè bí èéfín iná ìléru, gbogbo òkè náà sì mì tìtì. Ohùn ìpè sì ń rinlẹ̀ dòdò. Mose sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì fi àrá dá a lóhùn. OLúWA sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai, o sì pe Mose wá sí orí òkè náà. Mose sì gun orí òkè. OLúWA sọ fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀, kí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí wọn má ṣe fi tipátipá wá ọ̀nà láti wo OLúWA, bí wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn yóò ṣègbé. Kódà àwọn àlùfáà tí ó ń wá síwájú OLúWA gbọdọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́. OLúWA yóò kọlù wọ́n.” Mose wí fún OLúWA pé, “Àwọn ènìyàn kì yóò lè wá sí orí òkè Sinai, nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ti kìlọ̀ fún wa pé, ‘Ṣe ààlà yí òkè ká, kí o sì yà á sí mímọ́.’ ” OLúWA sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, mú Aaroni gòkè wá pẹ̀lú rẹ. Ṣùgbọ́n kí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn má ṣe fi tipátipá gòkè tọ OLúWA. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò kọlù wọ́n.” Mose sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ènìyàn lọ. Ó sì sọ ohun tí OLúWA wí fún wọn.