ẸKISODU 19
19
Àwọn Ọmọ Israẹli ní Òkè Sinai
1Ní oṣù kẹta tí àwọn eniyan Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ Sinai. 2Refidimu ni wọ́n ti gbéra wá sí aṣálẹ̀ Sinai. Nígbà tí wọ́n dé aṣálẹ̀ yìí, wọ́n pàgọ́ wọn siwaju òkè Sinai. 3Mose bá gòkè tọ Ọlọrun lọ.
OLUWA pè é láti orí òkè náà, ó ní, “Ohun tí mo fẹ́ kí o sọ fún àwọn ọmọ Israẹli nìyí, 4‘Ṣé ẹ rí ohun tí èmi OLUWA fi ojú àwọn ará Ijipti rí, ati bí mo ti fi ẹ̀yìn pọ̀n yín títí tí mo fi kó yín wá sí ọ̀dọ̀ mi níhìn-ín? 5Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì pa majẹmu mi mọ́ ẹ óo jẹ́ tèmi láàrin gbogbo eniyan, nítorí pé tèmi ni gbogbo ayé yìí patapata;#Diut 4:20; 7:6; 14:2; 26:18; Tit 2:14 6ẹ óo di ìran alufaa ati orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.’ Bẹ́ẹ̀ ni kí o sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.”#1 Pet 2:9 #Ifi 1:6; 5:10 7Mose bá pada wá, ó pe àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un fún wọn. 8Gbogbo àwọn eniyan náà bá pa ohùn pọ̀, wọ́n ní, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” Mose bá lọ sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA.
9OLUWA sọ fún Mose pé, “Mò ń tọ̀ ọ́ bọ̀ ninu ìkùukùu tí yóo bo gbogbo ilẹ̀, kí àwọn eniyan náà lè gbọ́ nígbà tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì lè gbà ọ́ gbọ́ títí lae.”
Mose sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA. 10OLUWA bá dá Mose lóhùn, ó ní, “Tọ àwọn eniyan náà lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ lónìí ati lọ́la. Sọ fún wọn pé kí wọ́n fọ aṣọ wọn, kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ ní ọjọ́ kẹta, 11nítorí pé ní ọjọ́ kẹta yìí ni èmi OLUWA óo sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, lójú gbogbo wọn. 12Pààlà yípo òkè náà fún wọn, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọ́n ṣọ́ra, kí wọ́n má ṣe gun òkè yìí, tabi fi ọwọ́ kan ẹsẹ̀ òkè náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè yìí, pípa ni n óo pa á. 13Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kàn án, òkúta ni kí wọ́n sọ pa á tabi kí wọ́n ta á ní ọfà; kì báà ṣe ẹranko tabi eniyan, dandan ni kí ó kú. Nígbà tí fèrè bá dún, tí dídún rẹ̀ pẹ́, kí wọn wá sí ẹ̀bá òkè náà.”#Heb 12:18-20
14Mose bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ó tọ àwọn eniyan náà lọ, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. 15Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ múrasílẹ̀ di ọ̀tunla, ẹ má ṣe súnmọ́ obinrin láti bá a lòpọ̀.”
16Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹta, ààrá bẹ̀rẹ̀ sí sán, bẹ́ẹ̀ ni mànàmáná ń kọ, ìkùukùu sì bo òkè náà mọ́lẹ̀, fèrè kan dún tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo eniyan tí wọ́n wà ninu àgọ́ wárìrì.#Ifi 4:5 17Mose bá kó àwọn eniyan náà jáde láti pàdé Ọlọrun, wọ́n sì dúró ní ẹsẹ̀ òkè. 18Èéfín bo gbogbo òkè Sinai mọ́lẹ̀, nítorí pé ninu iná ni OLUWA ti sọ̀kalẹ̀ sórí rẹ̀, ọ̀wọ̀n èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ bí ọ̀wọ̀n èéfín iná ìléru ńlá, gbogbo òkè náà sì mì tìtì.#Diut 4:11-12. 19Bí fèrè ti ń dún kíkankíkan tí dídún rẹ̀ sì ń gòkè sí i, bẹ́ẹ̀ ni Mose ń sọ̀rọ̀, Ọlọrun sì ń fi ààrá dá a lóhùn. 20OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, ó dúró ní ṣóńṣó òkè náà, ó pe Mose sọ́dọ̀, Mose sì gòkè tọ̀ ọ́ lọ. 21OLUWA sọ fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o sì kìlọ̀ fún àwọn eniyan náà, kí wọ́n má baà rọ́ wọ ibi tí OLUWA wà láti wò ó, kí ọpọlọpọ wọn má baà parun. 22Ati pé, kí àwọn alufaa tí yóo súnmọ́ ibi tí OLUWA wà, ya ara wọn sí mímọ́, kí n má baà jẹ wọ́n níyà.”
23Mose bá dá OLUWA lóhùn pé, “OLUWA, àwọn eniyan wọnyi kò lè gun òkè Sinai wá, nítorí pé ìwọ náà ni o pàṣẹ pé kí á pààlà yí òkè náà po, kí á sì yà á sí mímọ́.”
24OLUWA sì wí fún un pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, kí o mú Aaroni gòkè wá, ṣugbọn má ṣe jẹ́ kí àwọn alufaa ati àwọn eniyan náà rọ́ wá sórí òkè níbi tí mo wà, kí n má baà jẹ wọ́n níyà.” 25Mose bá sọ̀kalẹ̀ lọ bá àwọn eniyan náà, ó sì jíṣẹ́ fún wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ẸKISODU 19: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010