Eks 19:1-15
Eks 19:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI oṣù kẹta, ti awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti tán, li ọjọ́ na gan ni nwọn dé ijù Sinai. Nwọn sá ti ṣi kuro ni Refidimu, nwọn si wá si ijù Sinai, nwọn si dó si ijù na; nibẹ̀ ni Israeli si dó si niwaju oke na. Mose si goke tọ̀ Ọlọrun lọ, OLUWA si kọ si i lati oke na wá wipe, Bayi ni ki iwọ ki o sọ fun ile Jakobu, ki o si wi fun awọn ọmọ Israeli pe; Ẹnyin ti ri ohun ti mo ti ṣe si awọn ara Egipti, ati bi mo ti rù nyin li apa-ìyẹ́ idì, ti mo si mú nyin tọ̀ ara mi wá. Njẹ nisisiyi, bi ẹnyin ba fẹ́ gbà ohùn mi gbọ́ nitõtọ, ti ẹ o si pa majẹmu mi mọ́, nigbana li ẹnyin o jẹ́ iṣura fun mi jù gbogbo enia lọ: nitori gbogbo aiye ni ti emi. Ẹnyin o si ma jẹ́ ijọba alufa fun mi, ati orilẹ-ède mimọ́. Wọnyi li ọ̀rọ ti iwọ o sọ fun awọn ọmọ Israeli. Mose si wá o si ranṣẹ pè awọn àgba awọn enia, o si fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi lelẹ niwaju wọn ti OLUWA palaṣẹ fun u. Gbogbo awọn enia na si jùmọ dahùn, nwọn si wipe, Ohun gbogbo ti OLUWA wi li awa o ṣe. Mose si mú ọ̀rọ awọn enia pada tọ̀ OLUWA lọ. OLUWA si wi fun Mose pe, Wò o, emi tọ̀ ọ wá ninu awọsanma ṣíṣu, ki awọn enia ki o le ma gbọ́ nigbati mo ba mbá ọ sọ̀rọ, ki nwọn ki o si ma gbà ọ gbọ́ pẹlu lailai. Mose si sọ ọ̀rọ awọn enia na fun OLUWA. OLUWA si wi fun Mose pe, Tọ̀ awọn enia yi lọ, ki o si yà wọn simimọ́ li oni ati li ọla, ki nwọn ki o si fọ̀ asọ wọn. Ki nwọn ki o si mura dè ijọ́ kẹta: nitori ni ijọ́ kẹta OLUWA yio sọkalẹ sori oke Sinai li oju awọn enia gbogbo. Ki iwọ ki o si sagbàra fun awọn enia yiká, pe, Ẹ ma kiyesi ara nyin, ki ẹ máṣe gùn ori oke lọ, ki ẹ má si ṣe fọwọbà eti rẹ̀: ẹnikẹni ti o ba fọwọkàn oke na, pipa ni nitõtọ: Ọwọkọwọ́ kò gbọdọ kàn a, bikoṣepe ki a sọ ọ li okuta, tabi ki a gún u pa nitõtọ; iba ṣe ẹranko iba ṣe enia, ki yio là a: nigbati ipè ba dún, ki nwọn ki o gùn oke wá. Mose si sọkalẹ lati ori oke na wá sọdọ awọn enia, o si yà awọn enia si mimọ́, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn. O si wi fun awọn enia pe, Ẹ mura dè ijọ́ kẹta: ki ẹ máṣe sunmọ aya nyin.
Eks 19:1-15 Yoruba Bible (YCE)
Ní oṣù kẹta tí àwọn eniyan Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ni wọ́n dé aṣálẹ̀ Sinai. Refidimu ni wọ́n ti gbéra wá sí aṣálẹ̀ Sinai. Nígbà tí wọ́n dé aṣálẹ̀ yìí, wọ́n pàgọ́ wọn siwaju òkè Sinai. Mose bá gòkè tọ Ọlọrun lọ. OLUWA pè é láti orí òkè náà, ó ní, “Ohun tí mo fẹ́ kí o sọ fún àwọn ọmọ Israẹli nìyí, ‘Ṣé ẹ rí ohun tí èmi OLUWA fi ojú àwọn ará Ijipti rí, ati bí mo ti fi ẹ̀yìn pọ̀n yín títí tí mo fi kó yín wá sí ọ̀dọ̀ mi níhìn-ín? Nítorí náà, bí ẹ bá gbọ́ tèmi, tí ẹ sì pa majẹmu mi mọ́ ẹ óo jẹ́ tèmi láàrin gbogbo eniyan, nítorí pé tèmi ni gbogbo ayé yìí patapata; ẹ óo di ìran alufaa ati orílẹ̀-èdè mímọ́ fún mi.’ Bẹ́ẹ̀ ni kí o sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.” Mose bá pada wá, ó pe àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, ó sì sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un fún wọn. Gbogbo àwọn eniyan náà bá pa ohùn pọ̀, wọ́n ní, “Gbogbo ohun tí OLUWA wí ni a óo ṣe.” Mose bá lọ sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA. OLUWA sọ fún Mose pé, “Mò ń tọ̀ ọ́ bọ̀ ninu ìkùukùu tí yóo bo gbogbo ilẹ̀, kí àwọn eniyan náà lè gbọ́ nígbà tí mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì lè gbà ọ́ gbọ́ títí lae.” Mose sọ ohun tí àwọn eniyan náà wí fún OLUWA. OLUWA bá dá Mose lóhùn, ó ní, “Tọ àwọn eniyan náà lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ lónìí ati lọ́la. Sọ fún wọn pé kí wọ́n fọ aṣọ wọn, kí wọ́n wà ní ìmúrasílẹ̀ ní ọjọ́ kẹta, nítorí pé ní ọjọ́ kẹta yìí ni èmi OLUWA óo sọ̀kalẹ̀ sórí òkè Sinai, lójú gbogbo wọn. Pààlà yípo òkè náà fún wọn, kí o sì kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọ́n ṣọ́ra, kí wọ́n má ṣe gun òkè yìí, tabi fi ọwọ́ kan ẹsẹ̀ òkè náà. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè yìí, pípa ni n óo pa á. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kàn án, òkúta ni kí wọ́n sọ pa á tabi kí wọ́n ta á ní ọfà; kì báà ṣe ẹranko tabi eniyan, dandan ni kí ó kú. Nígbà tí fèrè bá dún, tí dídún rẹ̀ pẹ́, kí wọn wá sí ẹ̀bá òkè náà.” Mose bá sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ó tọ àwọn eniyan náà lọ, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ múrasílẹ̀ di ọ̀tunla, ẹ má ṣe súnmọ́ obinrin láti bá a lòpọ̀.”
Eks 19:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní oṣù kẹta tí àwọn Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti, ni ọjọ́ náà gan an ni wọ́n dé aginjù Sinai. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n gbéra kúrò ní Refidimu, wọ́n wọ ijù Sinai, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀, níbẹ̀ ni Israẹli sì dó sí ní iwájú òkè ńlá. Mose sì gòkè tọ Ọlọ́run lọ. OLúWA sì ké pè é láti orí òkè náà wá pé, “Èyí ni ìwọ yóò sọ fún ilé Jakọbu àti ohun tí ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: ‘Ẹ̀yin ti rí ohun tí mo ti ṣe sí àwọn ará Ejibiti, àti bí mo ti gbé e yín ní apá ìyẹ́ idì. Nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá ṣe ìgbọ́ràn sí mi dé ojú ààmì, tí ẹ sì pa májẹ̀mú mi mọ́, nígbà náà ni ẹ̀yin ó jẹ́ ìṣúra fún mi ju gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ayé ni tèmi. Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ilẹ̀ ọba àwọn àlùfáà fún mi, orílẹ̀-èdè mímọ́.’ Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ti ìwọ yóò sọ fún àwọn ọmọ Israẹli.” Mose sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbàgbà láàrín àwọn ènìyàn jọ. Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti OLúWA pàṣẹ fún un láti sọ ní iwájú wọn. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò ṣe ohun gbogbo ti OLúWA wí.” Mose sì mú ìdáhùn wọn padà tọ OLúWA lọ. OLúWA sọ fún Mose pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu ṣíṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mose sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún OLúWA. OLúWA sì wí fún Mose pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn. Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹta, nítorí ni ọjọ́ náà ni OLúWA yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Sinai ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn. Kí ìwọ kí ó ṣe ààlà fún àwọn ènìyàn, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ kíyèsí ara yín, kí ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ má tilẹ̀ fi ọwọ́ ba etí rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà, ó dájú, pípa ni a ó pa á: A ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta á ní ọfà, ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án. Ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko, òun kì yóò wà láààyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.” Mose sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ múra sílẹ̀ di ọjọ́ kẹta; Ẹ má ṣe bá aya yín lòpọ̀.”