Efe 6:7-9
Efe 6:7-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ mã fi inu rere sin bi si Oluwa, kì si iṣe si enia: Bi ẹnyin ti mọ pe ohun rere kohunrere ti olukuluku ba ṣe, on na ni yio si gbà pada lọdọ Oluwa, ibã ṣe ẹrú, tabi omnira. Ati ẹnyin oluwa, ẹ mã ṣe ohun kanna si wọn, ẹ mã din ibẹru nyin kù; bi ẹnyin ti mọ pe Oluwa ẹnyin tikaranyin si mbẹ li ọrun; kò si si ojuṣãju enia lọdọ rẹ̀.
Efe 6:7-9 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín pẹlu inú dídùn, bí ẹni pé fún Oluwa, kì í ṣe fún eniyan. Nítorí ẹ mọ̀ pé ohun rere tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá ṣe, olúwarẹ̀ ìbáà jẹ́ ẹrú tabi kí ó jẹ́ òmìnira, yóo rí èrè gbà lọ́dọ̀ Oluwa. Ẹ̀yin ọ̀gá, bákan náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Ẹ má máa dẹ́rù bà wọ́n. Ẹ ranti pé ati àwọn, ati ẹ̀yin, ẹ ní Oluwa kan lọ́run, tí kì í ṣe ojuṣaaju.
Efe 6:7-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ máa fi gbogbo ọkàn yin ṣe iṣẹ́ ìsìn bí sí Olúwa, kì í sí ṣe sí ènìyàn. Bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ohun rere tí olúkúlùkù bá ṣe òun náà ní yóò sí gbà padà lọ́dọ̀ Olúwa, ìbá à ṣe ẹrú, tàbí òmìnira. Àti ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa ṣe irú ìtọ́jú kan náà sí àwọn ẹrú yin, ẹ máa dín ìbẹ̀rù yín kù bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé Olúwa ẹ̀yin tìkára yín ń bẹ ní ọ̀run; kò sì ṣí ojúsàájú ènìyàn lọ́dọ̀ rẹ̀.