EFESU 6

6
Ọmọ ati Òbí
1Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ ti àwọn òbí yín nítorí pé bẹ́ẹ̀ ni ó dára.#Kol 3:20 2“Bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ.” Èyí níí ṣe òfin kinni pẹlu ìlérí, pé#Eks 20:12; Diut 5:16 3“Kí ó lè dára fún ọ, ati kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ náà.”
4Ẹ̀yin òbí, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú. Títọ́ ni kí ẹ máa tọ́ wọn ninu ẹ̀kọ́ ati ìlànà ti onigbagbọ.#Kol 3:21
Ẹrú ati Ọ̀gá
5Ẹ̀yin ẹrú, ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí wọ́n jẹ́ oluwa yín nípa ti ara, pẹlu ọ̀wọ̀ ati ìbẹ̀rù, pẹlu ọkàn kan gẹ́gẹ́ bí ẹni pé Kristi ni ẹ̀ ń ṣe é fún.#Kol 3:22-25 6Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń ṣọ́ yín nìkan ni ẹ óo máa ṣiṣẹ́ bí ìgbà tí ẹ fẹ́ gba ìyìn eniyan. Ṣugbọn bí ẹrú Kristi, ẹ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọrun láti ọkàn wá. 7Ẹ máa ṣe iṣẹ́ yín pẹlu inú dídùn, bí ẹni pé fún Oluwa, kì í ṣe fún eniyan. 8Nítorí ẹ mọ̀ pé ohun rere tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín bá ṣe, olúwarẹ̀ ìbáà jẹ́ ẹrú tabi kí ó jẹ́ òmìnira, yóo rí èrè gbà lọ́dọ̀ Oluwa.
9Ẹ̀yin ọ̀gá, bákan náà ni kí ẹ máa ṣe sí àwọn ẹrú yín. Ẹ má máa dẹ́rù bà wọ́n. Ẹ ranti pé ati àwọn, ati ẹ̀yin, ẹ ní Oluwa kan lọ́run, tí kì í ṣe ojuṣaaju.#a Kol 4:1, b Diut 10:17; Kol 3:25
Ìjàkadì pẹlu Ibi
10Ní ìparí, ẹ jẹ́ alágbára ninu Oluwa, kí ẹ fi agbára rẹ̀ ṣe okun yín. 11Ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dúró láti dojú kọ èṣù pẹlu ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀. 12Nítorí kì í ṣe eniyan ni à ń bá jagun, bíkòṣe àwọn ẹ̀mí burúkú ojú ọ̀run, àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára òkùnkùn ayé yìí. 13Nítorí èyí, ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dìde dúró láti jà nígbà tí ọjọ́ ibi bá dé. Nígbà tí ìjà bá sì dópin, kí ẹ lè wà ní ìdúró.
14Nítorí náà, ẹ dúró gbọningbọnin. Ẹ fi òtítọ́ ṣe ọ̀já ìgbànú yín. Ẹ fi òdodo bo àyà yín bí apata. 15Ẹ jẹ́ kí ìmúrasílẹ̀ láti waasu ìyìn rere alaafia jẹ́ bàtà ẹsẹ̀ yín. 16Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, ẹ fi igbagbọ ṣe ààbò yín. Nípa rẹ̀ ni ẹ óo lè fi pa iná gbogbo ọfà amúbíiná tí èṣù ń ta. 17Ẹ fi ìgbàlà ṣe fìlà onírin tí ẹ óo máa dé, kí ẹ sì mú idà Ẹ̀mí Mímọ́, tíí ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọrun. 18Ẹ máa gbadura nígbà gbogbo, kí ẹ máa fi gbogbo ẹ̀bẹ̀ yín siwaju Ọlọrun nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí náà, ẹ máa gbadura láì sùn, láì wo, fún gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun. 19Ẹ máa gbadura fún èmi gan-an alára, pé kí n lè mọ ohun tí ó yẹ kí n sọ nígbà tí n óo bá sọ̀rọ̀. Ati pé kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ tí àwọn eniyan yóo fi mọ àṣírí ìyìn rere 20tí mo jẹ́ ikọ̀ fún, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè mí. Ẹ gbadura pé kí n lè fi ìgboyà sọ̀rọ̀ bí ó ti yẹ.
Gbolohun Ìparí
21Kí ẹ lè mọ bí nǹkan ti ń lọ sí lọ́dọ̀ mi, ati ohun tí mò ń ṣe, Tukikọsi yóo sọ gbogbo rẹ̀ fun yín. Àyànfẹ́ arakunrin ni, ati iranṣẹ tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ninu iṣẹ́ Oluwa. 22Ìdí tí mo fi rán an si yín ni pé kí ẹ lè mọ bí gbogbo nǹkan ti ń lọ sí lọ́dọ̀ wa, kí ọkàn yín lè balẹ̀.
23Kí alaafia ati ìfẹ́ pẹlu igbagbọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba ati Oluwa Jesu Kristi, kí ó wà pẹlu àwọn onigbagbọ. 24Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn Oluwa wa, Jesu Kristi pẹlu ìfẹ́ tí kò lópin.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

EFESU 6: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa