Efe 6:10-14
Efe 6:10-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Lakotan, ará mi, ẹ jẹ alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipá rẹ̀. Ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, ki ẹnyin ki o le kọ oju ija si arekereke Eṣu. Nitoripe kì iṣe ẹ̀jẹ ati ẹran-ara li awa mba jijakadi, ṣugbọn awọn ijoye, awọn ọlọla, awọn alaṣẹ ibi òkunkun aiye yi, ati awọn ẹmí buburu ni oju ọrun. Nitorina ẹ gbe gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀ ki ẹnyin ki o le duro tiri si ọjọ ibi, nigbati ẹnyin bá si ti ṣe ohun gbogbo tan, ki ẹ si duro. Ẹ duro nitorina lẹhin ti ẹ ti fi àmure otitọ di ẹgbẹ nyin, ti ẹ si ti di ìgbaiya ododo nì mọra
Efe 6:10-14 Yoruba Bible (YCE)
Ní ìparí, ẹ jẹ́ alágbára ninu Oluwa, kí ẹ fi agbára rẹ̀ ṣe okun yín. Ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dúró láti dojú kọ èṣù pẹlu ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀. Nítorí kì í ṣe eniyan ni à ń bá jagun, bíkòṣe àwọn ẹ̀mí burúkú ojú ọ̀run, àwọn aláṣẹ ati àwọn alágbára òkùnkùn ayé yìí. Nítorí èyí, ẹ gbé gbogbo ihamọra Ọlọrun wọ̀, kí ẹ lè dìde dúró láti jà nígbà tí ọjọ́ ibi bá dé. Nígbà tí ìjà bá sì dópin, kí ẹ lè wà ní ìdúró. Nítorí náà, ẹ dúró gbọningbọnin. Ẹ fi òtítọ́ ṣe ọ̀já ìgbànú yín. Ẹ fi òdodo bo àyà yín bí apata.
Efe 6:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró. Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra.