Oni 4:9-12
Oni 4:9-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹni meji san jù ẹnikan; nitori nwọn ni ère rere fun lãla wọn. Nitoripe bi nwọn ba ṣubu, ẹnikini yio gbe ọ̀gba rẹ̀ dide: ṣugbọn egbe ni fun ẹniti o ṣe on nikan nigbati o ba ṣubu; ti kò li ẹlomiran ti yio gbé e dide. Ati pẹlu, bi ẹni meji ba dubulẹ pọ̀, nigbana ni nwọn o mõru: ṣugbọn ẹnikan yio ha ti ṣe mõru? Bi ẹnikan ba kọlu ẹnikan, ẹni meji yio kò o loju; ati okùn onikọ mẹta kì iyá fàja.
Oni 4:9-12 Yoruba Bible (YCE)
Eniyan meji sàn ju ẹnìkan ṣoṣo lọ, nítorí wọn yóo lè jọ ṣiṣẹ́, èrè wọn yóo sì pọ̀. Bí ọ̀kan bá ṣubú, ekeji yóo gbé e dìde. Ṣugbọn ẹni tí ó dá wà gbé! Nítorí nígbà tí ó bá ṣubú kò ní sí ẹni tí yóo gbé e dìde. Bẹ́ẹ̀ sì tún ni, bí eniyan meji bá sùn pọ̀, wọn yóo fi ooru mú ara wọn ṣugbọn báwo ni ẹnìkan ṣe lè fi ooru mú ara rẹ̀? Ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo ni eniyan kan lè dojú ìjà kọ, nítorí pé eniyan meji lè gba ara wọn kalẹ̀. Okùn onípọn mẹta kò lè ṣe é já bọ̀rọ̀.
Oni 4:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹni méjì sàn ju ẹnìkan, nítorí wọ́n ní èrè rere fún làálàá wọn: Tí ọ̀kan bá ṣubú lulẹ̀, ọ̀rẹ́ rẹ̀ le è ràn án lọ́wọ́ kí ó fà á sókè, ṣùgbọ́n ìyọnu ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣubú tí kò sì ní ẹni tí ó le è ràn án lọ́wọ́! Àti pẹ̀lú pé, bí ẹni méjì bá sùn pọ̀, wọn yóò móoru. Ṣùgbọ́n báwo ni ẹnìkan ṣe le è dá nìkan móoru? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a le è kojú ogun ẹnìkan, àwọn méjì le è gbìjà ara wọn, ìkọ́ okùn mẹ́ta kì í dùn ún yára fà já.